Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìwé Àkọsílẹ̀ ẹ Ti Ọ̀run

    Àgbáyé nílò àwọn ajíhìnrere,àwọn ajíhìnrere nínú ilé tí a yà sí mímọ́, kò sì sí ẹnìkan tí a ó kọ̀ sínú àwọn ìwé ìrántí i ti ọ̀run bí onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀mí ajíhìnrere.- Review and Herald, Aug. 23, 1892.IIO 87.1

    Tí àwọn ọmọ ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kò bá mú iṣẹ́ yìí ní ọ̀kúnkúndùn, wọ́n fihàn pé wọn kò ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Orúkọ ọ wọn ni a kọ bí àwọn ìránṣẹ́ ṣúẹ́súẹ́. Testimonies, vol.5, pp.462, 463.IIO 87.2

    Nínú àwọn olùfọkànsìn ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan àwọn kan wà tí wọn kò le è ṣàì náání ipa Ọlọ́run, síbẹ̀, wọ́n takété, wọn kọ̀ láti ṣe ìgbìyànjú kankan fún ìrànlọ́wọ́. Kì bá sàn fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti rántí ìwé ìrántí tí a pamọ́ l'ókè, - Ìwé yìí tí kò sí ìgbàgbé, tí kò sí àṣìṣe, àti pé nínú èyí ni wọn yóò ti dá wọn lẹ́jọ́. Níbẹ̀ gbogbo ànfààní tí a kò fiyèsí láti ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run ni a kọ sílẹ̀, àti níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ẹ ti ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ni áò mú wá sí ìrántí ayérayé. - Prophets and Kings, p.639.IIO 87.3

    Ní òwúrọ̀ ọ ti ọjọ́ kẹtàlélógún osù kẹwàá, ọdún, 1897, ní n ǹkan bí agogo méjì, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé mi, mo sì rí ìran nínú àwọn ìdájọ́ tí ó ń bọ̀…. ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbèrún mẹ́wàá ni wọ́n péjọ síwájú ìtẹ́ ń lá kan, lórí èyí tí ẹnìkan jòkó tí ìfarahàn rẹ̀ sì lọ́lá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ni ó wà níwájú u RẸ̀, àti ní orí ohun tí a fi bo ọ̀kọ̀ọ̀kan an wọn ni a fi wúrà kọ àwọn ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀, tí ó dàbí iná tí ń jó, “ìwé ìṣirò ti ọ̀run.” Ọ̀kan nínú àwọn ìwé yìí ni ó ní àwọn orúkọ àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn gba òtítọ́ gbọ́, ni wọ́n ṣí i sílẹ̀. Lọ́gan mo sọ ìran ti ọ̀kẹ́ àìmoye nípa ti orí ìtẹ́ nù, àti pé àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ti òtítọ́ ni ó gba àkíyèsí ì mi…. IIO 87.4

    Ìwé mìíràn ni a sì tún ṣí sílẹ̀, níbi tí a ti kọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ó jẹ́wọ́ òtítọ́ náà. Lábẹ́ àkòrí gbo-gbo-gbò ẹ̀ṣẹ̀ ìmọ-tara-ẹni-nìkan ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó kù wà…. A forúkọ ẹ̀ka kan sílẹ̀ bí i àwọn tó ń gbilẹ̀. Bí adájọ́ tí ojú u rẹ́ rínú róde, ṣe wò wọ́n àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti àìkàsí i wọn farahàn ní kedere. Pẹ̀lú ètè tó gbẹ tó sì ń gbọ̀n rìrì, wọ́n gbà pé àwọn ti dalẹ̀ sí ohun mímọ́ tí a fi sábẹ́ ìṣàkóso o wọn. Wọ́n ti gbọ́ àwọn ìkìlọ̀ àti àwọn ànfààní ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ tàbi kí wọn ṣe àtúnṣe. Wọ́n wá rí i báyìí wí pé wọ́n ti ṣe àìnáání àánú Ọlọ́run lọ́pọ̀lọpọ̀. Ní tòótọ́, wọn kò ní irú àwọn ìjẹ́wọ́ bẹ́ẹ̀ láti ṣe bí wọ́n ti kún fún ẹ̀gbin àti ìdíbàjẹ́; ṣùgbọ́n,bí igi ọ̀pọ̀tọ́, a fi wọ́n ré nítorí pé wọn kò so èso, nítorí pé wọn kò lo àwọn ẹ̀bùn tí a fi jíǹkí i wọn. Àwọn ẹ̀ka yìí gbé ara wọn ga jù lọ, ń ṣiṣẹ́ fún ìfẹ́ ẹ ti ara wọn nìkan. Wọn kò ní ọrọ̀ sí ipa ti Ọlọ́run, bí wọn kò ti ka ẹ̀tọ́ Ọlọ́run lórí i wọn kún. Bí wọ́n tilẹ̀ ń jẹ́wọ́ bí ìránṣẹ́ ẹ ti Krístì, wọn kò jèrè ọkan kankan fún Un. Kìbá jẹ́ pé orí akitiyan wọn nìkan ni iṣẹ́ Ọlọ́run dúró lé lórí, ìfàsẹ́hìn ì bá bá a, nítorí pé ki i ṣe ohun ìní i wọn nikan ni wọn ko fi sílẹ̀, ṣùgbọn ara wọn pẹ̀lú....Wọ́n gba àwọn mìíran láàyè láti ṣe iṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà Oluwa a wọn, kí wọn sì gbé ẹrù tí ó wúwo jùlọ nígbà tí wọ́n ń fi ìmọ̀ tara wọn nìkan sin ìfẹ́ ọkàn an wọn tí ó wà fún ìgbà díẹ̀...IIO 87.5

    Adájọ́ wípé “Gbogbo yín ni a yóò dá láre nípa ìgbàgbọ́, a yóò sì dá wọn lẹ́jọ́ nípa iṣẹ́ ẹ wọn.” Bí àìbìkítà a wọn ṣe le farahàn ṣàn-án ṣàn-án nígbà náà àti bí ètò Ọlọ́run ṣe l'ọ́gbọ́n tó nínú fífún olúkúlùkù ènìyàn ní iṣẹ́ láti ṣe láti gbé iṣẹ́ Olúwa ga àti láti gba àwọn ènìyàn là. Olúkúlùkù ni ó ní láti fi ìgbàgbọ tí ó wà láàyè hàn nínú ìdílé e rẹ̀ àti ní àdsúgbò o rẹ̀, nípa fífi àánú hàn sí àwọn aláìní, kí ó bá àwọn tí a pọ́n lójú kẹ́dùn, kí ó sì gba iṣẹ́ ajíhìnrere, àti nípa títi iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́hìn pẹ̀lú àwọn ohun ìní i rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí i Meroz, ègún Ọlọ́run wà lórí i wọn fún ọhun tí wọn kò tí ì ṣe. Wọ́n nífẹ̀ ẹ sí iṣẹ́ tí ó lè mú èrè púpọ̀ wá nínú ayé yìí; àti pé iwáju orúkọ ọ wọn ṣófo ìbànújẹ́ nínú ìwé ìṣirò tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn iṣẹ́ rere.- Testimonies,vol.4, pp.384-386.IIO 88.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents