Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìpè Sí Ọlọ́danni

    Iṣẹ́ tí ó yàtọ̀ pátá pátá ni a ti yan àtẹ̀lé e Krístì kọọkan. - Southern Watchman, Aug.2, 1904.IIO 9.3

    Olọ́run fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà a rẹ̀. Ìwọ ni ó ní latí ṣiṣẹ́ tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ tọkàn tọkàn.-Bible Echo, June 10, 1901.IIO 9.4

    Tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bá jẹ́ ajíhìnrere tó múná dóko ni, iṣe ìránṣẹ́ ti àsìkò yìí yóò ti tàn káà kiri èdè, ẹ̀ya àti ènìyan.-Testimonies, vol.6, p438.IIO 9.5

    Gbogbo àtẹ̀lé e Krístì tòótọ́ ni a ti bí sí ìjọba Olọ́run gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere. Eni tí ó bà si ti mu nínú omi ìyè ti di orísun ìyè.ẹni tí ó ń gbà ti wa dí afun ni.Oore-ọ̀fẹ́ Krístì nínu ọkàn an wa sì wá dàbí i orísun nínu aṣálẹ̀, tí ó wà láti tu ọkàn ènìyàn lára, tí ó sì ń fẹ́ kí ọkàn tí ó fẹ́ ṣègbé yára láti mu nínú omi ìyè náà. Desire of Ages, p 195.IIO 9.6

    Olọ́run ń fẹ́ iṣẹ́ ìsìn in wa ni ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ti fi ìmọ̀ òtítọ́ ti àsìko yii fún.IIO 9.7

    Olọ́run ń fẹ́ iṣẹ́ ìsìn in wa l’ẹ́nì kọ̀ọkan tí ó ti fi ìmọ̀ òtítọ́ ó rẹ̀ lé l’ọ́wọ́ ní àsìkò yìí. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè jíhìnrere ní ilẹ̀ àjèji, ṣùgbọ́n gbogbo wa ni a lè jẹ́ ajíhìnrere ní ilé e wa, ní àdúgbò o wa àti nínú ìdílé e wa.-Testimonies, vol.9,p30IIO 9.8

    Ọlọ́run dúró ní ìwọ̀n ẹsẹ bàta díẹ̀ sí orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ọ̀run nígbàtí ó gbe iṣẹ́ rẹ̀ lé àwọn àtẹ̀le e rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ajíhìnrere tí o gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. O sọ fún won pé “E lọ sí gbogbo ayé ki ẹ sì wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo ẹ̀dá” O sì fi agbára rẹ̀ fún wọn —Southern Watchman, Sept.20, 1904.IIO 9.9

    Láti gba ẹ̀mí là gbọdọ̀ je iṣẹ́ tí ẹni tí ó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Krístì ní láti ṣe.A sì jẹ́ ajigbèsè fún aráyé fún oore-ọfẹ́ tí Olọ́run fún wa, fún ìmọ́lẹ̀ tí ó tàn sí ọ̀ná a wa àti ṣíṣe àwarí agbára òtitọ́ ọ rẹ̀-Testimonies, vol 4, p53.IIO 10.1

    Níbi gbogbo, ó ṣe é ṣe kí a ṣe pàsípàroọ̀ iṣẹ́ tí à ń ṣe fún ìgbani níyànjú ti ara wa. Ìmọ́ ènìyàn lè tẹ̀ẹ̀ sí kí á mú kí ìjọ àti ilé ìwé dàgbá sókè síi, kí a sì wá parapọ̀ bí ẹgbẹ́ láti ṣàkóso, láti kọ ilé ìjọsìn àgbàyanu àti awọn ilé-ìwé.Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó ń fi ilé-ìwé sílẹ́ tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ àánú,wọ́ǹ sì yọ ara wọn kúrò láti darapọ̀ mọ́ ayé, tí ìfẹ́ ọkàn an wọn sì di tútù: wọ́n wá di ẹni tí ǹkan kò yá lórí láti ṣe, ìfẹ́ Ọlórun àti ti ènìyàn sì ti kú ní ọkàn an wọn.iṣẹ́ tí kò ṣeé fi fún ẹlòmíràn láti ṣe ni Ọlórun ti gbé lé àwọn àtẹ̀lé e rẹ́ lọ́wọ́ bíi iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn aláìsàn àti àwoọn aláìní, fífi iṣẹ́ ìhìnrere fún àwọn tí ó ti sọnù kìí ṣe iṣẹ́ tí a lè fi sílẹ̀ fún àwọn ìgbìmọ̀ tàbí àwọn ti ń dá ilé iṣẹ́ àánú sílẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìgbìyànjú u wa, ìfira ẹni rúbo ni ohun tí iṣẹ́ ìhìnrere nílò.-Ministry of Healing, p.147.IIO 10.2

    Ẹnikẹ́ni tí ó bà si ti gba ìmọ́lẹ́ mímọ́ yìí gbọdọ̀ tàn an sí ọ̀nà àwọn tí kò mọ ìmọ́lẹ̀ ìyè yìí.-Desire of Ages, p.152.IIO 10.3

    Ati fi iṣẹ́ yìí fún ẹnì kọọkan, kò sì sí ẹni tí ó lè jẹ́ olúrópò fún ẹnìkejì, ẹnì kọọkan ni ó ní iṣẹ́ Pàtàkì tí kò ṣe e fojú fò, bí ìmúṣe rẹ ṣe kan àwọn ọkàn bẹ́ẹ̀ ni ìfojú rénà rẹ̀ jẹ́ ègbé fún àwọn tí Krístì kú fún. Review and Herald, Dec.12, 1893.IIO 10.4

    A gbọdọ̀ jẹ́ alábásisépọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,ọ̀lẹ ènìyàn kò lè jẹ́ ọmọ lẹ́yìn in rẹ́. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìjo gbọdọ̀ ní ìmọ̀lára pé ìgbé ayé àti ìdàgbà sókè ìjọ le è ní ìfarapa pẹ̀lú ìwà àti ìṣesí i wọn.-Review and Herald, Feb.15, 1887.IIO 10.5

    Gbogbo ọkàn tí Jésù ti gbàlà ni ó pè láti ṣiṣẹ́ ní orúko rẹ̀ fún ìgbàlà àwọn tí ó ti sọnù. Iṣẹ́ ti di ìkọ̀sílẹ̀ ní Ísírélí; ṣé àwa àtèlé e Krístí lónìí náà kò fi iṣẹ́ yìí sílẹ̀? Christ Object Lessons, p.191.IIO 10.6

    Ohun kan wà tí a ní láti sṣe, gbogbo oọkàn tí ó gbàgbó nínú òtítoọ́ gboọdoọ̀ dúró ní ipò o woọn láti soọ pé “Èmi nìyí; rán mi Isa. 6:8. Testimonies, vol.6, p 49.IIO 10.7

    Ànfààní tí a fún onígbàgbọọ́ kọ̀ọ̀kan kìí ṣe láti máa wò, ṣùgbọ́n kí a jí gììrì sí bíbọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.-Christ Object Lessons, p.69.IIO 11.1

    Ẹni tí ó bá sì ti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run láti ìsinsìnyí lọ gbọdọ̀ rí ara rẹ̀ bí ohun tí ó so ẹ̀wọ̀n tí a sọ̀ kalẹ̀ láti gba aráyé là, ẹni tí ó bá ti wà nínú u Krístì nípa ètò àánú u rẹ̀ yóò lọ pẹ̀lú u rẹ̀ láti wá àti láti gba ọkàn tó ńsọnù là.-Ministry of Healing, p.105.IIO 11.2

    Gbogbo o wa ni a ní láti wá ń ǹ kan ṣe. Kí ẹnikẹ́ni máṣe rò pé kò sí ibi tí wọ́n ti lè ṣiṣẹ́ fún Kristi. Olùgbàlà ṣe ìfarajọ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ènìyàn.- The Ministry Of Healing, p. 104. IIO 11.3

    Gbogbo àwọn tí wọ́n ti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run nínú májẹ̀mú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ wà ní abẹ́ èdìdì tí yóò mú wọn wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú u rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìjèrè ọkàn.-Testimonies, vol.7, p. 19.IIO 11.4

    Fífẹ̀ ni oko nàà,ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ni ìṣelọ́sọ̀ ọ́ rẹ̀ to béẹ̀ tí ọkàn kọ̀ọ̀kan tí a yà sí mímọ́ yóò rí ààyè láti ṣe iṣẹ́ ìsìn gẹ́gẹ́ bí ohun èlò tí ó ní agbára àtọ̀run wá.- Testimonies, vol.9, p.47.IIO 11.5

    Ohun èló ni àwa ènìyàn jẹ́ níwájú Ọlọ́run nítorí pé ó ti yàn wá láti ṣe àṣeparí ìdí àánú àti oore-òfé e rẹ́.Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nì a sì ní ipá láti ṣà, fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tí a ti fún ní òsùwòn ìmọ́lẹ́, èyí tí a dá fún ìwúlò àsìkò o rẹ̀ láti lè jẹ́ kí a ṣiṣẹ́ tí ó fún wa láti ṣe.-The Great Controversy, p.343.IIO 11.6

    Ọlọ́run ti ń dúró fún ìgbà pípẹ́ fún ẹ̀mí ìsìn in rẹ́ láti gba àkóso ìjọ ọ rẹ̀ tóbẹ́ ẹ̀ tí oní kálùkù yóò fi ṣiṣẹ́ fún un gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀.-Tha Acts of the Apotles, p.111.IIO 11.7

    Lákọ́kọ́, ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, lẹ́yìn náà ni ó rán àwọn àádoọ́rin ọkàn láti polongo ìjọba Ọlọ́run, Ó ń kọ́ wọn ní iṣẹ́ e wọn láti lè jẹ́ kí wọn fi lọ ẹlòmíràn nípa ohun tí ó ti fì hàn wọ́n. Nínú iṣẹ́ e rẹ̀,Ó ń kọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ní iṣẹ́ tí wọn yòó ṣe tí wọn yóò fi tàn kálẹ̀ sí gbogbo ayé, bí iye wọn bá ti ń pọ̀ sii.-The Act of the Apostles,p.32.IIO 11.8

    Iṣẹ́ yìí kò wà fún àwọn àlùfáà tí a gbọ́wọ́ lé lórí nìkan bíkòse fún gbogbo ẹni tí ó bá ti gba Jésù ní Olúwa ni a pè láti ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ẹlomíràn.-The Acts of the Apostles, p.110.IIO 12.1

    A kò lè gbé ìjọ léwọ́n nípa oun tí ó jẹ́, tàbí nípa orúkọ tí ó wà nínú ìwé ìgbìmọ̀ ìjọ, ṣùgbọ́n a lè ṣe ìgbéléwọ̀n rẹ̀ nípa ìfaradà, nípa ìṣòdodo rẹ̀, bí o ṣe ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ náà, àti ìfojúsónà, ìgbìyànjú ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò mú kí a lè parí iṣẹ́ naa ju ìwàásù àti ohun tí à ń sọ nípa àgbékalẹ̀ ìjọ tí kò ṣe é yí padà.-Review and Herald, Sept 6, 1881. IIO 12.2

    Ní gbogbo ibi tí a bá ti fi ìjọ lọ́lẹ̀, gbogbo ọmọ ìjọ ni ó gbọdọ̀ kó’pa ribi ribi nínú iṣẹ́ ìhìnrere. Wọ́n gbọdọ̀ ṣe àbẹ̀wò sí gbogbo ìdílé tí ó yi wọn ká kí wọn sì mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí í ṣe ti ẹ̀mí.-Testimonies, vol.6, p.296.IIO 12.3

    Kìí ṣe gbogbo ọmọ ìjọ ni a pè láti jẹ́ òṣìṣẹ ní ilẹ̀ àjèjì, ṣùgbọ́n gbogbo wa la ní ipa Pàtàkì láti kó nínú títan ìmọ́leẹ́ ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ fún aráyé.Iṣẹ́ ìránṣẹ̀ Krístí kò ní àbùlà.IIO 12.4

    Ní ọjọ́ Olúwa, kò ní sí àwáwí fún pé a pa ẹnu wa mọ́ fún ìwà ìmọ ti ara wa nìkan tí a hù.Iṣẹ́ wà fún gbogbo ọkàn àti fún gbogbo ẹni tí ó ṣetán. Onírúurú iṣẹ́ ni a ti pèsè sílẹ̀ fún orísirísi ọkàn, àti orísirísi agbára. Historical Sketches, pp 290,291.IIO 12.5

    Olúwa ti gbé iṣẹ́ òtítọ́ yìí lé wa lọ́wọ́, gbígbé Krístì nínú ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ gẹ́gẹ́ bí kànga omi tí ó ń sun loọ sí ìyè ayérayé.IIO 12.6

    A máa jẹ̀bi tí a kò bá sa ipá a wa tàbí gbìyànjú láti fi omi ìyè yìí lọ ẹlòmíràn—Historical Sketches, page 291.IIO 12.7

    Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́, a kó tíì kó ìdákan nínú ogún tí ó yẹ kí a kó nípa jíjèrè ọkàn fún Krístì.Ìkìlọ̀ gbọdọ̀ lọ sí gbogbo ayé, àti pé gbogbo onígbàgbọ́ tòótọ́ ni yòó jẹ́ olùdarí àti àpẹẹrẹ fún ẹlòmíràn nínú ìṣòdodo, ìgbé àgbélébùú, bí a ṣe já fáfá tó nínú iṣẹ́ náà, nínú à i fi irọ́ bo òtítọ́ mọ́lọ, nínú ìfira ẹni rúbọ àti iṣẹ́ wa láti polongo iṣẹ́ Ọlọ́run:- Review & Herald, Aug, 23, 1881.IIO 12.8

    Níwọ̀n ìgbàtí o ti fun wa ni ànfààní, ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ti gba ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ rẹ̀ ni ó wà ní abẹ́ ànfààní kan náà tí ó fún àwọn wòlíì Ísrélì tí ọ̀rọ̀ náà tọ̀ lọ pé `iwọ ọmọ ènìyàn mo ti fi ó ṣe alóre sí ilé l´srélì, nítorí náà ìwọ ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹnu ù mi, kí o sì fi ìkìlọ̀ mi fún wọn”—Testimonies, Vol.9 pp.19, 20IIO 13.1

    Sí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ti jẹ́ alábápín nínú oore-òfẹ́ ẹ rẹ̀, Ọlọ́run ti yan iṣẹ́ fún àwọn mìíràn, ní ẹnì kọ̀ọ̀okan ni a ní láti dúró ní ipò o wa kí a sì sọ pé èmi nìyí rán mi” a lè jẹ́ ajíhìnrere, ajíhìnrere olù rànlọ́wọ́ oníṣègùn òyìnbó, Dókítà onígbàgbọ́, onígbagb ọlọ́danni, o lè jẹ́ oníṣòwò tàbí àgbẹ̀, alákọ̀wé tàbí atọ́kòṣe, iṣẹ́ yìí wà fún gbogbo o wa.Iṣẹ́ e wa ni láti fihan eniyan ìhìnrere ti ìgbàlà wọn. Gbogbo iṣẹ́ t´i a bá n ṣe, gbọdọ̀ jẹ́ bí ọ̀nà láti fi ìgbàlà lọ ẹlòmíràn. The ministry of healing, page 148.IIO 13.2

    Nígbà tí ọ̀gá ilé pe àwọn ìránṣẹ́ e rẹ̀ ó fi iṣẹ wọn fún wọn, gbogbo ìdílé Ọlórun ni ó kópa nínú. lílo ohun tí olúwa wọ́n ní, Ní ẹnì kọ̀ọ̀kan, láti òkè dé ìsàlẹ .títí dé ẹni tí a gbéga jù ni a ti fi agbára fún láti jíyìn fún Ọlọ́run —Bible Echo,june 10,1901.IIO 13.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents