Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìran Tí ó Wọni Lọ́kàn

  Àwọn ọgọọ́gọ̀rún àti àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni wọ́n rí tí wọ́n ń bẹ àwọn ìdílé wò, tí wọ́n sì ń ṣọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun níwájú u wọn. Àwọn ọkàn ni a dálẹ́bi nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, àwọn ẹ̀mí ìyípadà nítòótọ́ sì farahàn.- Testimonies, vol.9, p.126.IIO 142.5

  Àwọn òṣìṣẹ́ ẹ Bibeli méjì jòkó nínú ìdílé kan.Pẹ̀lú ṣíṣí Bíbélì sí iwájú u wọn, wọ́n fi Jesu Kristi Oluwa lọ̀ wọ́n bí Olùgbàlà tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni. Wọ́n gbàdúrà pẹ̀lú ìtara sí Ọlọ́run, wọ́n sọ àwọn ọkàn di rírọ̀ wọ́n sì borí i wọn nípa ipa tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run. Wọ́n gba àdúrà a wọn jáde pẹ̀lú àwọ̀tútù àti agbára. Bí wọ́n ṣe ń ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo rí i pé ohun rírọ̀, ìtàṣán ìmọ́lẹ̀ tàn sí àwọn ìwé mímọ́, mo sì sọ jẹ́jẹ́ pé ” Lọ sí àwọn òpópónà àti ẹ̀bá ọ̀nà, rọ̀ wọ́n láti wọlé, kí ilé è Mi ba à le è kún.”-Testimonies, vol.9, p.35.IIO 142.6

  Ọ̀pọ̀ ló ń ka ìwé mímọ́ tí òye pàtàkì i rẹ̀ kò yé. Káàkiri àgbáyé ni àwọn ọkùnrin ati àwọn obìnrin ti ń wò ní títẹjúmọ́ ọ̀run. Àwọn àdúrà àti àwọn omijé àti àwọn ìwádì í ń jáde láti inú àwọn ọkàn tí ń wọ̀nà fún ìmọ́lẹ̀, fún oore-ọ̀fẹ́, fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì wà ní etí i bèbè ti ìjọba náà, tí wọn ń dúró láti gbájọ wọlé.- The Acts of the Apostles, p.109.IIO 143.1

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents