Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìgbẹ́kẹ̀lé Ìwà Ènìyàn Lásán

    Ọ̀pọ̀ tí wọ́n pe ara wọn ní onígbàgbọ́ gbẹkẹle iwa a wọn lasan. Wọn ti kọ ẹ̀bùn tí ó lè mu wọn bu ọlá fún Krístì nípa ṣíṣe aṣojú Rẹ̀ fún aráyé. Iṣẹ́ ẹ ti ẹ̀mí mímọ́ sí wọn jẹ́ iṣẹ́ àjèjì. Wọn kò jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà.Àwọn àgbékalẹ̀ tàbí ìpìlẹ̀ tí ó mú àwọn tí ó jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú u Krístì yàtọ̀ sí àwọn tó jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú ayé ti di bákan náà.Àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ bí àtẹ̀lé e Krístì kùnà láti ya ara a wọn sọ́tọ̀ bí ènìyàn ọ́tọ̀.Ohun tí ó le fi wọ́n hàn bí ènìyàn ọ̀tọ̀ ti farasin .Àwọn ènìyàn ti wá sọ ara wọn di ọmọ ẹ̀yìn fún ayé,fún ìṣe e rẹ̀,àṣà a rẹ̀ ati ìmọtara ẹni i rẹ̀. Ìjọ Ọlọ́run ti padà sínú ayé nípa títasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin, nígbà tí ó yẹ kí àwọn ayé padà sínú ìjọ ní gbígbọ́ràn sí òfin.Lójoojúmọ́ ni ìjọ ń yípadà sínú ayé.-Christ Object Lessons, pp.315,316.IIO 45.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents