Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Awọn Ti a Pe jade Laarin Awọn ti a N wo bi Eniyan Lasan.

    Àwọn ti a n wo bi eníyan lasan láti gba ipò o wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ̀ ẹ́. Pínpín nínú àwọn ìṣòro ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà ṣe nípìn ín nínú àwọn ìṣòro ọmọ ènìyàn,pẹ̀lú ìgbàgbọ́, wọ́n yóò ríi pé Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú u wọn.- Gospel Workers, p.38.IIO 24.2

    Ní àwọn pápá tí ó jìnnà tàbí tí ó wà nítòsí, àwọn ènìyàn ni á yóò pè láti ibi ìtulẹ̀ àti ibi àwọn òwò pẹ́-pẹ̀-pẹ́ tí o gba ọkàn an wọn, wọn yóò sì ṣè idánilékọ̀ọ̀ ní àjọmọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó ní ìrírí. Bí wọ́n sì ṣe ń kọ́ kí wọn ṣiṣẹ́ takun takun, wọn yóò polongo òtítọ́ pẹ̀lú agbára.Nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu ti ìpèsè ọ̀run, sísọ òkè ìṣòro kalẹ̀, àti jíjù sínú òkun.Iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ṣe kókó púpọ̀ fún àwọn olùgbé ní orí ayé, a ó ò gbọ́, òye yóò sì yé wọn. Àwọn ènìyàn yìí mọ ohun tí òtítọ́ jẹ́. Síwájú àti síwájú síi, iṣẹ́ náà yóò gbòòrò, títí tí gbogbo ayé yóò fi gbọ́ ìkìlọ̀, nígbà náà ni òpin yóò dé.-Testimonies, vol.9.p.96.IIO 24.3

    Ọlọ́run lè lo, yóò sì lo àwọn tí wọn kò ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó bẹ́ẹ̀ ní ilé ìwé. Ìsiyèméjì agbára RẸ̀ lati ṣe eyi, farahàn nínú àìgbàgbọ́; ó ń dín agbára Ọlọ́run tí ó wà níbi gbogbo ẹni tí ohunkóhun kò ṣòro fún kù.Kì bá ti dára tó, láti yẹra fún àìnígbẹ́kẹ̀lé tí a kò fiṣẹ́ rán! Tí ó mú àìlò bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára nínú ìjọ; o ń ti ọ̀nà, kí ẹ̀mí mímọ́ má baà lo àwọn ènìyàn; Ó ń ti ọ̀nà, kí Ẹ̀mí Mímọ́ má ba à le è lo àwọn ènìyàn;Ó ń mu imẹlẹ ba awọn ọkàn àwọn tí ó nífẹ̀ ẹ́ àti ìtara láti ṣiṣẹ́ fún Kristi, ọ̀pọ̀ tí ìbá jẹ́ alábàá ṣiṣẹ́ pọ̀ gidi pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọ́n bá fún wọn ní ààyè bí ó ṣe tọ́.- Gospel workers, pp.488,489.IIO 24.4

    Ànfààní ni ó jẹ́ fún ọkán kọ̀ọ̀kan láti gbé ìgbésẹ̀.Àwọn tí wọ́n sopọ̀ pẹ̀lú Krístì yóò dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ ti ọmọ Ọlọ́run, títí tí wọn yóò fi dàgbà l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin.Tí gbogbo àwọn tí wọ́n gba òtítọ́ bá ti ṣa gbogbo agbára àti ànfààní láti kọ́ àti láti ṣe, wọn yóò lágbára nínú Krístì.Iṣẹ́ yòwú ù kí wọn máa ṣe- yálà, wọ́n lè jẹ́ àwọn àgbẹ̀,onímọ̀ ẹ̀rọ,àwọn olùkọ̀ọ́,tàbí àwọn àlùfáà, tí wọ́n bá ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọn ì báà jẹ́ òṣíṣẹ́ tí ó kún ojú òṣùwọ̀n fún olùkọ́ ọ ti ọ̀run.-Testimonies, vol. 6, p.423.IIO 25.1

    Àwọn tí wọ́n wà nínu ijọ tí wọ́n ní ẹ̀bùn tí ó tó láti bẹ̀rẹ̀ nínú onírúurú iṣẹ́kíṣẹ́ ti ayé, bíi ìkọ́ni, ìkọ́lé, àwọn ilé iṣẹ́ tí ó ń ṣe n ǹkan títà àti àgbẹ̀, gbogbo wọn tí wọ́n gbọdọ̀ múra láti ṣiṣẹ́ fún ìdàgbà sókè ti ìjọ nípa ṣíṣiṣẹ́ nínú àwọn ìgbìmọ̀ tàbi olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi, ṣíṣe nínú iṣẹ́ ìjèrè ọkàn,tàbi dídí àlàfo onírúurú àwọn ipò tí ó ta mọ́ ìjọ,-Review and Herald, Feb 15,1887.IIO 25.2

    Láti mú kí iṣẹ́ yìí tẹ̀ síwájú, Krístì kò mú àwọn ẹni tí ó ní ìmọ̀, tàbí àwọn alóyin létè e àjọ ìgbìmọ̀ àwọn Júù, tàbí agbára Róòmù.Oṣiṣẹ Agba ko yan awọn olùkọ̀ aseféfé júù, Ṣugbọn o yan onírẹ̀lẹ̀,òpè ènìyàn láti polongo òtítọ́ tí yóò mú àyípadà bá ayés. Àwọn ènìyàn wọn tí ó ń pinnu láti dá lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí adarí nínú ìjọ ọ rẹ̀, kí àwọn náà lè fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn, kí wọn sì rán wọn jáde pẹ̀lú isẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Àti pé kí wọn le ṣe àṣeyorí nínú iṣẹ́ ẹ wọn, wọ́n ní láti fún wọn ni agbára ẹ̀mí mímọ́. Kìí ṣe nípa agbára ènìyàn tàbí ọgbọ́n ènìyàn ni a ó ò fi gbolongo ìhìnrere bíkòṣe pẹ̀lú agbára Ọlọ́run.-The Acts of the Apostles, p.17.IIO 25.3

    Lára àwọn tí Olùgbàlà ti fi iṣẹ́ iwaasu náà lé l’ọ́wọ́, “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa kọ́ gbogbo orílẹ̀èdè”ni ọ̀pọ̀ lára wọn wá láti àarin àwọn tí a le fojú rénà.- ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti kọ́ láti n’ífẹ̀ ẹ́ Olúwa wọn, tí wọ́n sì ti pinnu láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ iṣẹ́ àimọ- tara- ẹni- nìkan RẸ̀. Sí àwọn onírẹ̀lẹ̀ yìí,àti sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Olùgbàlà nígbà tí ó ń se iṣẹ́ ìhìnrere ní ayé ni a ti fún un ní òtítọ́ tí ó ṣe iyebíye yìí. Wọ́n ní láti mú ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà yìí tọ aráyé nípasẹ̀ Krístí.-The Acts of the Apostles, pp.105,106.IIO 25.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents