Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Èrò Tí ó Rọ̀ Mọ́ Àṣeyọrí

    Ohunkóhun tí a bá ṣe nínú ìfé òtító, bí ó tilè wù kí ó kéré tó níwájú omo ènìyàn, ó ní èso tí ó dára, tí ìrí Olórun bòwò fún isé tí a se pèlú ìfé ju iye isé tí a se lọ.-Testimonies, Vol. 2, p. 135.IIO 262.3

    Tí a bá yí àwon méwàá tí yóò se déédéé tokàntokàn padà, tí ó lè sisé ìhìnrere ó dára ju àwon ogórùn-ún tí a yípadà tí kò lè lo ipa àti agbára won láti jíhìnrere lọ.-Testimonies, Vol. 4, p. 602.IIO 262.4

    Kìí jé agbára tí o ní tàbí agbára tí o máa ní ni yóò mú àseyorí wá. Ohun tí Olórun lè se fún o ni. A gbodò ní ìgboyà kékeré nínú ohun tí ènìyàn lè se, kí a sì ní ìgboyà tí ó pò nínú ohun tí Olórun lè se fún gbogbo okàn tí ó gbàgbó. Ó ń fé láti gbà ó, kí o ní ìrètí ohun ń lá láti òdò ọ Rè. Ó fé láti fún o ní ìmò nínú ohun ayé àti ti èmí. Ó lè tún ogbón-ọ̀n re se. Fi èbùn-ùn re sisé fún-Un, bèèrè fún ogbón, yóò sì fi fún o.-Christ’s Object Lesson, p. 146.IIO 262.5

    Òróró ore-òfé ń fi ìgboyà fún omo eniyan, ó sì fi ìdí láti se isé Olórun fún àwon tí ó yàn lójoojúmó. Àwon òpònú omidan márùn-ún ní àtùpà (èyí túmò sí ogbón ìmo òrò Olórun), sùgbón won ò ní oore-òfé Krístì. Lójoojúmó ni wón lo sí ibi àpèje àti isé òde sùgbón isé ẹ won ṣàìní òdodo Kristi. Oòrùn òdodo kò tàn nínú okàn àti àyà a won, won kò nífèẹ́ òtító tí ó wà ní ìbámu sí ayé àti ìwà, àwòrán àti àmúye Krístì. Òróró oore-òfé kò dàpò mó isé ẹ won. Òfìfo asálè ni èsìn-in won jé. Wón dínà ìlànà èsìn won, sùgbón wón wà ní ètàn nínú ayé ìgbàgbó won, torípé wón rò pé àwón mó ní ònà ara won, wón sì kùnà láti kó èkó ní ilé-èkó Kristi, tí ó jé pé tí wón bá se yóò jé kí won ó mòye sí ònà ìgbàlà.-Review and Herald, Mar. 7, 1894.IIO 263.1

    A gbodò gbé isé Olórun títí di ìparí ní ìbásepò ènìyàn àti àwon èmí òrun. Àwon tí ó tán nínu ara won lè wà ní ìse déédéé nínú isé Olórun, sùgbón won kìí gbàdúrà, isé ẹ won jé lásán. Tí wón bá wo àwo túràrí tó wà lówó ańgélì tí ó dúró níbi pepe wúrà níwájú ìté, won yóò rí pé itòsí Kristi gbodò dàpò mó àdúrà àti ipa wa, bí béè kó won ó jé aláìwúlò bí ebo Káìnì. Tí gbogbo wa bá lè rí ìwúlò isé omo ènìyàn, bí ó ti wà níwájú Olórun, a yóò rí i pé isé tí a se pèlú àdúrà púpò, tí a yà sí mímó pèlú ìtóyè Krístì, yóò lè dúró níwájú ìdájó. Ní ojó ìdájó ni a yóò mo eni tí ó ń sin Olórun àti eni tí kò sìn- Ín.-Review and Herald, Jul 4, 1893.IIO 263.2

    Èsìn kò ní lè dáhùn ní ìgbà yìí. A lè se gbogbo isé Kànmí kí a sì jé aláìní ipa èmí-mímó bí òkè Gìlbóà se se aláìní ìrì àti òjò. Gbogbo wa la nílò ìdàpò pèlú èmí-mímó, a sì tún nílò ìtànsán iná oòrùn òdodo láti rò àti gba okan wa. A gbodò dúró gboin nígbogbo ìgbà bí àpata sí ìlànà Olórun.-Testimonies, Vol. 6, pp. 417, 418.IIO 264.1

    Àseyorí kò dúró lé èbùn wa bí agbára àti ìfé láti sisé náà. Kì í se kí a ní èbùn tí ó dára jùlo ni ó jé ká lè rí isé tí ó ní ìtéwógbà, sùgbón bíkòse síse isé pèlú òtító inú lójoojúmó, èmí ìtélórùn, ìfé òtító nínú ìgbésí ayé elòmíràn. Nínú isé ìrèlè tí ó jùlo, a lè rí àseyorí tòótó tí ó tayo jùlo. Isé tí ó rorùn jùlo, tí a se pèlú ìfé, inú rere lè wà níwájú Olúwa.-Prophets and Kings, p. 219.IIO 264.2

    Àmúye isé yì í gbodò jé èyí tí ó lè wá, tí ó tó, tí ó sì lágbára. Ayé e wa gbodò ní àmúye òtító lónà gbobgo. Ìwà òtító nínú ohun kékeré, ìsé ogun kékeré nínú òtító yóò fayò sónà ayé wa. Nígbà tí isé ẹ wa bá parí nínú ayé, a yóò rí i pé gbogbo isé kékeré tí a se nínú òtító ó ti fi ipa rere sórí i wa. Ipa tí kò lè parun.-Patriachs and Prophets, p. 574.IIO 264.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents