Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìtọ́jú Olùṣọ́àgùtàn

    Olùsóàgùtàn tí ó rí pé òkan nínú àwon àgùtàn ti sonù, kìí wá irú àgùtàn béè láì bìkítà láarin àwon tí ó wà nílè, pé “Mo ní mókàndínlógórùn-ún, yóò sì ná mi ni òpòlopò wàhálà láti wá èyí tí ó sonù lo. Jé kí ó padà wálé fúnra a rè, mà á sílèkùn agbo àgùtàn láti jé kí ó wolé”. Ní kété tí irú àgùtàn béè bá ti sonù ni olùsóàgùtàn yóò ti wà nínú ìbànújé àti ìkóokàn sókè. Ayóò ka àwon àgùtàn tí ó wà nínú ogbà láìní iye ìgbà. Nígbà tí ó bá dájú pé òkan ti sonù, kò ní jáfara. Yóò fi àwon mókàndílógórùn-ún yókù tó wà nínú ogbà sílè láti wá èyí tí ó sonù lo. Bí òkùnkùn bá se ń bolè, tí ewu mì lótùn-ún àti lósì, béè ni okàn olùsóàgùtàn yóò se má pòsi, tí yóò má gbìyànjú sí láti wá èyí tí ó sonù lo. Yóò sa gbogbo ipá rè láti wá alo.IIO 245.3

    Pèlú ìfòkànbalè ni yóò jé nígbà tí ó bá gbó ekún àgùtàn tí ó sonù ní jìnà réré, yóò sì má fi ekùn rè tò ó lo, bí ó ti ń gun òkè, òun gégé lé tí ó léwu. Bí ekún àgùtàn yìí bá sì ń dínkù ni yóò má ronú pé àgùtàn ńaà láti fé kú. Ìgbèyìn làálàá rè, yóò já sáyó, nígbà tí ó bá rí àgùtàn tí ó sonù yìí. Kò ní bá a wí pé ó ti da òun láàmú púpò, kó nàá tàbí pariwo mó o. Kò tilè ní darí rè lo sílé pèlú pàsán. Nínú ayò ni yóò se gbé àgùtàn tí ó ti rí náà sí èjìká rè. Tí ó bá ti ní egbò, yóò tún gbé sí àyà rè dáadáa, kí oru àyà rè lè fún àgùtàn tí ó ti rè yí lókun. Pèlú opé nínú ayò rè pé wíwá àgùtàn yìí kò já sásán, yóò mú àgùtàn náà bó ságbo padà.-Christ’s Object Lessons, pp. 187, 188.IIO 246.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents