Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Èrè Tí ó Dájú

    Ẹni tí ó yan iṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn ní ìdiwọ̀n agbára a wọn, kò ní jẹ́ kí iṣẹ́ òtítọ́ lọ láì lérè. Gbogbo iṣẹ́ ìsòótọ́ àti ìgbàgbọ́ ni a yóò dé ládé pẹ̀lú àánú Ọlọ́run àti inú dídùn. Gbogbo òṣìṣẹ́ ni a ṣe ìlérí fún, ‘’Ẹní tí ó lọ tí ó sọkún, tí ó sì so èso iyebíye, kò ní siyèméjì láti wá pẹ̀lú ayò, yóò sì mú ìtí lọ́wọ́ pẹ̀lú u rẹ̀.-’’ Testimonies, vol.5, p.398.IIO 267.2

    Kò sí bí iṣẹ́ ẹ wa ti lè kéré tó, tí a bá tẹ̀lé Kristi nínú ìgbàgbọ́ aláìní àrekérekè, a kò ní dáwa lágara nípa èrè e wa, ohun tí àwọn tí ó tóbi, tí ó ní ìmọ̀ jùlọ kò lè ní, àwọn alágbára, nínú ara wọn, tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ lè rí gbà. Ọ̀nà ọ̀run kò ṣí sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń gbé ara wọn ga, kò sí fún àwọn onígbéraga nínú ẹ̀mí, ṣùgbọ́n yóò wà fún àwọn tí ó ní ẹ̀mí bíi ti ọmọdé. Ìbùkún yìí yóò jẹ́ èrè fún àwọn tí ó ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run láì ní àrekérekè nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́.- Christ’s Object Lessons, p.404.IIO 267.3

    Ojú àwọn tí ó ṣiṣẹ́ yìí yóò dé adé ìfira ẹni sílẹ̀. Ṣùgbọ́n wọn yóò gba èrè e wọn.- Testimonies,vol.6, p.348.IIO 267.4

    Fún gbogbo òṣìṣẹ́, èrò yìí lè jẹ́ kóríyá, nínú ayé yìí, iṣẹ́ ẹ wa fún Ọlọ́run lè dàbí ẹni pé kò ní èrè, Ìgbìyànjú u wa láti ṣe rere lè jẹ́ níní ìtara àti ìfaradà, síbẹ̀ a lè má fún wa ní ààyè láti rí èrè e wọn, ó lè dàbí ẹni pé ipa wa já s’ ófo, ṣùgbọ́n Olùgbàlà fún wa ní ìdánilójú pé a yóò gba èrè e wa lọ́run.- Testimonies, vol.6, p.305.IIO 267.5

    Gbogbo iṣẹ́ rere,gbogbo iṣẹ́ ẹ ti ìdájọ́ mú àwọn ọ̀run kọrin.Bàbá a wa ọ̀run lórí ìtẹ́ ẹ Rẹ̀ ń wo àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀bùn iyebíye e rẹ̀. “Wọn yóò sì jẹ́ tèmi, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, nígbà tí Èmi yóò ṣe wọ́n lọ́sọ̀ọ́.” Gbogbo iṣẹ́ àánú fún àwọn tí ó nílò àánú u wa tàbí àwọn tí ó ń jìyà ni a ṣe fún Jésù. Gbogbo àwọn tí ó bá láánú, tí ó ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́, tí ó ń tu àwọn tí a ni lára lára, tí ó ǹ ṣòrẹ́ ọmọ òrukàn ń mú ara a wọn súnmọ́ Jésù.- Review and Herald, Aug.16, 1881.IIO 268.1

    Kristi rí gbogbo iṣẹ́ àánú, ìrànlọ́wọ́ àti èròǹgbà rere fún àwọn tí ó ya, afọ́jú, arọ, aláìsàn, opó àti àwọn ọmọ òrukaǹ gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ṣe fún Òun, a sì kọ àwọn iṣẹ́ yìí sílẹ̀ nínú ìwé àkọsílẹ̀ ọ̀run, a yóò sì rí èrè e rẹ̀ gbà.-Testimonies, vol.3,pp.512.513.IIO 268.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents