Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORÍ KỌKÀNLÉLÓGÚN ILÉ JẸ́ IBI ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́ FÚN ÀWỌN ONÍṢẸ́ ÌHÌNRERE

  Ohun Pàtàkì Àkọ́kọ́

  Ilé jẹ́ ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ fún ọmọ níbẹ̀ sì ni a ti ń fi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ayérayé lélẹ̀.-The Ministry of Healing, p. 400.IIO 206.1

  Iṣẹ́ okòòwò àkọ́kọ́ ayé rẹ ni láti jẹ́ ajíhìnrere nínú ilé.-(Tesimonies, Vol. 4, p. 138.IIO 206.2

  Láti inú ilé ni ìdàgbàsókè àti ìmúbọ̀sípò ọmọ ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀. Iṣẹ́ àwọn òbí sì dá lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyìí, ìgbáyégbádùn àwùjọ, àṣeyọrí ìjọ, àṣeyọrí orílẹ̀ èdè, gbogbo rẹ̀ dá lórí ipa tí ilé ń kó lórí ọmọ.-The Ministry of Healing, p. 349.IIO 206.3

  Bí ẹ̀mí ìhìnrere bá ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó nínú ayé àwọn ọmọ, wọn yóò kọ́ bí a ṣe ń ní ayọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn àti ìfi-ara-ẹni-jìn fún àṣeyọrí elòmíràn.-The Ministry of Healing, p. 401.IIO 206.4

  Kí àwọn òbí ó máṣe gbàgbé iṣẹ́ ìjèrè ọkàn ńlá èyí tí ó wà níwájú wọn nínú ilé. Ọlọ́run ti p e gbogbo àwọn ìyá níjà lórí ọmọ tí Ó fún wọn, Ọlọ́run sọ wí pé, “Gba ọmọkùnrin yìí, gba ọmọbìnrin yìí, kí o sì tọ wọn fún Mi. Kọ́ ọ ní ìwà bí ọmọ ọba, kí ó baá lè máa dán nínú gbọ̀gán Olúwa títí láíláí”. Ògo àti ìmọ̀lẹ̀ Ọlọ́run tí ó ti orí ìtẹ́ mímọ́ wá lórí màmá tí ó jẹ́ olóòtítọ́ bí ó ti ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láti dojú ìjà kọ ipá àti ẹ̀ṣẹ̀.-Testimonies, Vol. 9, p. 37.IIO 206.5

  Láti inú ilé wa ni iṣẹ́ wa fún Kírísítì ti bẹ̀rẹ̀, kò sí ibi ìjèrè ọkàn Kankan èyí tí ó ju eléyìí lọ. Àwọn òbí lè kọ́ àwọn ọmọ láti ṣiṣẹ́ fún ìjèrè ọkàn àwọn ènìyàn nípa jíjẹ́ ápẹẹrẹ rere fún wọn. Ẹ jẹ́ kí àwon òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ṣàánú fún àwọn arúgbó àti àwọn tí à ń pọ́n lójú, wọn yóò sì jẹ́ ẹni tí ń mú ìtura bá àwọn aláìní àti àwọn oníròbínújẹ́. A gbọ́dọ̀ kọ́ wọn láti kópa ribiribi nínú iṣẹ́ ìjèrè ọkàn àti kí a jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀mí ìséra-ẹni òun ìfara-ẹni-jìn fún ìdùnnú àwọn elòmíràn àti kí a jẹ́ kí wọ́n kópa nínú ìtẹ̀sìwájú iṣẹ́ Kírísítì, kí wọ́n baa lè jẹ́ alábàṣíṣẹ́ paapọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Tí àwọn ọmọ wọ̀nyìí yóò bá jẹ́ ajíhìnrere tòótó fún àwọn elòmíràn, èyí yóò máa farahàn láti inú ilé wọn wá.-Testimonies, Vol. 6, p. 429.IIO 206.6

  A gbọ́dọ̀ tún ilé wa ṣe kí a sì sa ipá wa takuntakun láti ríi wí pé gbogbo ará ilé wa ni ó níìfẹ́ nínú iṣẹ́ ìhìnrere. A gbọ́dọ̀ ri wí pé àwọn ọmọ wa kópá nínú fífi àánú wọn hàn fún àwọn aláìgbàgbọ́, kí wọ́n baà lè sa ipá wọn tòótọ́ ní gbogbo ìgbà àti ní ibi gbogbo láti jẹ́ aṣojú rere fún Kírísítì.-Review and Herald, July 4, 1893.IIO 207.1

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents