Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ṣíṣe Ìríjú Ohun Ìní Wa

    Nínú gbogbo ètò ìsúná wa, a gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti mú ìfẹ́ ẹni tí ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti Òpin gbogbo làálàá kìrìsítẹ́nì ṣẹ.-Testimonies, Vol. 9, p. 19.IIO 220.2

    Owó níye lórí púpọ̀ nítorí wí pé ó lèè ṣe ohun rere púpọ̀. Nígbà tí owó yìí bá wà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run, ó jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí ebí ń pa, omi fún àwọn tí òǹgbe ń gbẹ, aṣọ fún àwọn tí ó wà níhòòhò. Ó jẹ́ ààbò fún àwọn tí à ń pọ́n lójú, ohun èlò ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìsàn, ṣùgbọ́n owó tí a kó pamọ́ lásán láì lò fún ìmáyédẹrùn àwọn ènìyàn kò níye lórí ju ìyanrìn lásán lọ.-Christ’s Object Lessons, p. 351.IIO 220.3

    Ọlọ́run ni ó ṣe àgbékalẹ̀ bí iṣẹ́ Rẹ̀ yóò ṣe tẹ̀síwájú fúnra Rẹ̀, Ó sì ti pèsè lọ́pọ̀ yanturu fún wọn ohun tí wọn yóò lò wí pé nígbàkuugbà tí Òun bá pè fún ìrànlọ́wọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ dáhùn wí pé, “Olúwa, èrè ti gun orí owó Rẹ̀.-“Testimonies, Vol. 9, 58.IIO 220.4

    Owó kò ṣe gbé lọ sí ọ̀run nítorí a kò nílò rẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n iṣẹ́ rere tí a fi owó ṣe nípa jíjèrè ọ̀kan ni a ó gbé lọ sí gbọ̀ǹgan ìdájọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n bá fi ìmọ̀tara-ẹni-nìkan lo ẹ̀bùn Ọlọ́run láì bìkítà láti ran àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́ tí wọ́n kò sì ṣe iṣẹ́ kankan láti mú ìtẹ̀síwájú bá iṣẹ́ Ọlọ́run kò bú ọlá fún Ẹlẹ́dàá wọn. Ìwà jíja Ọlọ́run lólè ni a ó kọ síwájú orúkọ wọn nínú àwọn ìwé tí ó wà lọ́rún.-Christ’s Object Lessons, p. 266.IIO 220.5

    Kí ni pàtàkì owó nígbà tí a bá fi wé ọkàn? Ǹ jẹ́ owó níyè lórí ju ọkàn tàbí ẹ̀mí lọ bí? Gbogbo owó tí a bá ní ni ó yẹ kí a mọ̀ wí pé ti Ọlọ́run ni àti wí pé kìí ṣe tiwa, Ọlọ́run kàn fi í sí ìkáwọ́ wa ni, kìí ṣe láti fi ṣòfò lórí ohun tí kò wúlò bíkòṣe wí pé kí a lòó fún iṣẹ́ Ọlọ́run nínú iṣẹ́ gbígbà ẹ̀mí là kúrò nínú ìparun.-Life Sketches of Ellen G. White, p. 214.IIO 220.6

    Ǹ jẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìhìnrere nínú ọ̀pọ̀ yàntùru kò ṣe pàtàkì tó ohun tí a lè faramọ kí a sí tìílẹ́hìn? Ǹ jẹ́ kò yẹ kí a se ara wa kúrò nínú ìwà níná owó ní ìnákùná kí a sì fi ẹ̀bùn wa sínú ìṣura Ọlọ́run kí a lè fi òtítọ́ náà ránṣẹ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lókèèrè, kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ilé baà lè dúró? Ǹ jẹ́ kò yẹ kí ọ̀run ó fi ọwọ́ sí iṣẹ́ yìí bí? Iṣẹ́ fún àkokò ìkẹ́hìn yìí ni kò sí atìlẹhìn ọ̀pọ̀ owó fún tàbí ìtẹ̀síwájú nípa ipa àwọn ènìyàn pàtàkì ayé? Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹ̀bùn tí ó wá láti ọ̀dọ àwọn tí ó se ara wọn ni ati rí àtìlẹ́hìn fún iṣẹ́ yìí. Ọlọ́run tí fún wa ní ànfààní láì jẹ́ akópa pẹ̀lú Kírísítì nínú ìjìyà rẹ̀ níbí, Ó sì ti pèsè ìbùkún sílẹ̀ fún wa ní ayé tuntun.-Review and Herald, Dec. 2, 1890.IIO 221.1

    A fihàn mí wí pé angẹ́lì tí ó ń ṣe àkọsílẹ̀ ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́ inú gbogbo owó tí a fi sínú àpò ìṣúra Ọlọ́run àti àbáyọrísí ìkẹhìn ọ̀rọ̀ tí a fi fún ni. Ojú Ọlọ́run ń ṣe àkíyèsí gbogbo owó tí a bá fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ Rẹ̀ àti irú ọkàn tí a fi mú u sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni à ń ṣe àkọsílẹ̀ irú ọkàn tí a fi múu sílẹ̀. Gbogbo àwọn ẹ̀mi ìfarà-ẹni-jìn tí a fi da padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí Ó ti ṣe bèèrè lọ́wọ́ wa ni a ó sì fi ẹ̀ bùn rẹ̀ fún wa. Irú owó tí àwọn ènìyàn fi tọkàntọkàn fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ Ọlọ́run èyí tí ẹnikẹ́ni lèè ṣìlò lọ́nàkọnà kò dá ìbùkún èyí tí Ọlọ́run yóò fi fún àwọn tí ó fi owó náà sílẹ̀ dúró rara.-Testimonies, Vol. 2, pp. 518, 519.IIO 221.2

    Gbogbo ànfààní láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ tàbí láti mú kí iṣẹ́ Ọlọ́run tẹ̀síwájú nínú títan òtítọ́ náà kalẹ̀ dàbí òkúta iyebíye èyí tí a fi ń pamọ́ sí ilé ìfowopamọ́ ti ọ̀run. Ọlọ́run ń dán olúkúlukú wa wò. Ó ti fi ìbùkún rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu lé wa lọ́wọ́, Ó sì ń wò wá bí a ti ṣe ń lò wọ́n bóyá a ò lò wọ́n láti ran áwọn aláìní lọ́wọ́ tàbí ní ìmọ̀lára àwọn ọkàn kí a sì lo owó tí ó wà ní ìkáwọ́ wa fún ìrànlọ́wọ́ wọn. Gbogbo àwọn iṣẹ́ rere wọ̀nyìí ni Olúwa ń fi pamọ́ s’íbi ìṣura Rẹ̀ ní ọ̀run fún wa.-Testimonies, Vol. 3, pp. 249-250.IIO 221.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents