Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ilé Iṣẹ́ Itẹ̀wé Aṣojú Tí Ó Múná Dóko.

  Àwọn Onírètí Bíbọ̀ ọ Jésù ni Ọlọ́run ti yàn bí ènìyàn ọ̀tọ̀, tí a yà sọ́tọ̀ nínú ayé.Nípa ìlẹ̀mọ́ ń lá a ti òtítọ́ ó ti ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ ọ́ jade lati ibi ìwakùsà ayé, tí ó sì mú wọn sínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú u RẸ̀. Ó ti fi wọ́n ṣe aṣojú u RẸ́, tí ó sì pè wọ́n láti jẹ́ àwọn ikọ̀ fún-Un nínú iṣẹ́ ìgbàlà tí ó kẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ ń lá a ti òtítọ́ ni a ti fi sí ìkáwọ́ àwọn alára kíkú títí láí, ìkìlọ̀ tí ó lọ́wọ̀ tí ó sì bani lẹ́rù tí Ọlọrun rán sí ènìyàn,ni a ti fi lé wọn lọ́wọ́ láti fifún aráyé; àti láti ní àṣeyọrí nínú iṣẹ́ yì í àwọn ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé e wa wà lára àwọn aṣojú tí ó múná dóko.- Testimonies, vol.7, p.138.IIO 148.1

  A gbé iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ẹ wa kalẹ̀ nípa ìtọ́sọ́nà Ọlọrun àti lábẹ́ ìbojútó pàtàkì.- Testimonies, vol.7, p.138.IIO 148.2

  Ní ìwọ̀n ń lá nípasẹ̀ àwọn ilé ìtẹ̀wé e wa ni àṣeyọrí ṣe lè bá iṣẹ́ ìránṣẹ́ ańgẹ́lì náà tí ó wá sílẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú agbára ń lá, tí ó sì tan ayé pẹ̀lú ògo o RẸ̀.- Testimonies, vol.7, p.140.IIO 148.3

  Mo pàsẹ láti sọ fún àwọn ilé ìtẹ̀wé: “Ẹ gbé àsìá sókè; gbé e ga jù. Polongo iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ańgẹ́lì kẹta, kí gbogbo ayé ba à le è gbọ́. Jẹ́ kí wọn rí i pé “Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà, àwọn tí ń pa òfin Ọlọrun mọ́ àti ìgbàgbọ́ ọ Jésù mọ́; Rev.14:12. Jẹ́ kí àwọn ìwé e wa jẹ́ bí ẹlẹ́rì í fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí fún gbogbo aráyé.”- Testimonies, vol.9,p.61.IIO 148.4

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents