Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Dàrúdàpọ̀ ọ Ti Ayérayé

    À ń dúró ní ẹnu ọ̀nà tí dàrú dàpọ̀ ti àsìkò náà. Ní kíá kíá ni ìdájọ́ ti Ọlọ́run yóò tẹ̀lé ara wọn,- iná, àti omi, ilẹ̀ ríri, pẹ̀lu ogun àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀. Kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu ní àsìkò yì í nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tóbi àti èyí tí ó ni ipinnu; nítorí pé ańgẹ́lì ti àánú kò lè dúró pẹ́ títí láti dáàbò bo àwọn tí kò ronú pìwàdà.- Prophets and Kings, p.278.IIO 51.1

    Dàrúdàpọ̀ náà ń sún mọ́ wa díẹ̀ díẹ̀. Oòrùn ń ràn ní ọ̀run, ó sí ń yíká gẹ́gẹ́ bí ìṣe e rẹ̀, àwọn ọ̀run sì ń fi ògo Ọlọ́run hàn. Àwọn ènìyàn ń jẹ wọ́n ń mu, wọ́n ń gbìn, wọ́n ǹ kọ̀lè, wọ́n ń fẹ́ ‘yàwó, wọ́n ń fì ‘yàwó fúnni. Onìṣòwò ń rajà wọ́n sì ń tajà. Àwọn ènìyàn ń gbún ara wọn, wọ́n ń jì jàdù fún ipò tí ó ga jùlọ. Olùfẹ́ ẹ fàájì sì ń pọ̀ sí ì níbi ìṣeré, fífi ẹṣin sáré, tẹ́tẹ́ títa. Ariwo tí ó l’ágbára ń borí, síbẹ̀ àkókò tí ilẹ̀kùn àánú yóò tì ń súnmọ́ wa pẹ́kí pẹ́kí, láìpẹ́ a yóò ṣe ìpinnu ìdájọ́ ayérayé lórí iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Èṣù rí i pe àsìkò tí òun ń ní kéré. Ó sì ti fi àwọn aṣojú u rẹ̀ sí ibi iṣẹ́ pé kí a le è tan àwọn ènìyàn jẹ, fi lúúlú bojú àwọn ènìyàn, o mu ọwọ ọ wọn kun, bi ẹni tí ó wà lójú ran títí tí àsìkò láti ṣ’àtúnṣe yóò fi kọjá, tí ilẹ̀kùn àánú yóò sì tì títí láíláí.- Souther Watchman, Oct.3,1905.IIO 51.2

    Rírú òfin ti fẹ́rẹ̀ kọjá ààlà a rẹ̀. Rúdurùdu gba inú ayé, ìwárìrì ń lá sì fẹ́rẹ̀ dé sórí ọmọ ènìyàn.òpin ti súnmọ́ tòsí. Àwa tí a mọ òtítọ́ gbọdọ̀ múra sílẹ̀ fún ohun tí ó máa bọ́ sí orí ayé láìpẹ́ bí i ohun ìyanu tí ó muni lómi.-Testimonies, vol.8, p.28.IIO 51.3

    Ní àsìkò tí ibi ń gbilẹ̀, a níláti mọ̀ pé dàrú dàpọ̀ ń lá súnmọ́ lé nígbà tí àwọn tí ó yapa kúrò nínú òfin Ọlọ́run ti fẹ́rẹ̀ jẹ́ kárí ayé, nígbà tí a ó pọ́n àwọn ènìyàn an Rẹ̀ lójú tí a o sì niwọ́n lára pẹ̀lú àwọn ènìyàn ẹlẹ́gbẹ́ ẹ wọn, Ọlọ́run yóò sì ṣe olùlàjà..- Christ Object Lessons, p.178IIO 51.4

    À ń dúró ní ẹnu ìloro ohun ń lá tí ó lọ́wọ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ ń ṣẹ. Ohun àjèjì, wọ́n ń kọ ìtàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sílẹ̀ nínú ìwé ti ọ̀run. Rúdurùdu ti bá ohun gbogbo tí ó wà nínú ayé e wa yìí. Ogun wà, àti ìdágìrì ogun, àwọn orílẹ̀ èdè ń bínú,àti pé àsìkò àwọn òkú ti dé tí wọn ó dá wọn lẹjọ́. Ìṣẹ̀lẹ̀ ń yí padà tí yóò mú kí ọjọ́ Olúwa tètè dé kánkán.Àsìkò díẹ̀ bí a ṣe mọ̀ ló ṣẹ́kù.Ṣùgbọ́n nígbà tí orílẹ̀èdè ti ń dìde sí orílẹ̀èdè báyìí, àti ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba, tí kò sì sí ogun jíjà a gbo-gbo-gbò nísinsìnyí, síbẹ̀ orígun mẹ́rẹ̀rin ni a gbámú títí tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò fi fi èdìdì sàmì sí iwájú orí i wọn. Nígbà náà ni àwọn agbára ti ayé yóó tò lẹ́sẹesẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti ja ìjà ìkẹhìn.-Testimonies, vol.6, p.14.IIO 52.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents