Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Aṣáájú Nínú Làálàá Àti Ìfara-ẹni-rúbọ

    A gbọdọ̀ fi ìgbẹ́kẹ̀lé hàn nínú àwọn ọ̀dọ́ ọ wa l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú nínú ìdáwọ́lé tí ó ní làálàá àti ìfara ẹni rúbọ, nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n fi ara wọn jì fún Krístì gbọdọ̀ gbóríyìn tàbí kẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn, láti gbà wọ́n níyànjú àti láti bùkún àwọn tí wọ́n ń jà fún Ọlọ́run.-Counsels to Teachers, pp.516,517.IIO 32.2

    A nílò àwọn ọ̀dọ́. Ọlọ́run ń pè wọ́n láti jẹ́ ajíhìnrere ní ilẹ̀ àjèjì. Nípa àfiwé, wọ́n ní òmìnira kúrò nínú àníyàn ati iṣẹ́, wọ́n wà ní ipò tí ó sàn ju àwọn tí wọ́n ni iṣẹ́ láti pèsè ikọ́ni àti àtìlẹyìn fún àwọn ìdílé tó tóbi.Síwáju síi, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lè bá dọ́gba ní kíá kíá sí àwọn afẹ́fẹ́ ìlú àti ẹgbẹ́ titun, wọ́n sì lè faradà ohun tí kò rọrùn àti wàhálà. Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìfaradà, wọ́n lè dé sàkání àwọn ènìyàn níbi tí wọ́n bá wà. - Counsels to Teachers, p.517.IIO 32.3

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ l’ọ́kùnrin tí wọ́n ti ní irú ẹ̀kọ́ gidi ní ilé ni wọ́n gbọdọ́ kọ́ fún iṣẹ́ ìsiǹ, kí wọn sì gbà wọ́n níyànjú láti gbé òdiwọ̀n ti òtítọ́ ga ní ibi tuntun nípa àgbékalẹ̀ tó dára àti iṣẹ́ òdodo. Nípa dídara pọ̀ pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti àwọn òṣìṣẹ̀ tó lóye nínú iṣẹ́ ìlú ńlá, wọn yóò ní àǹfààní tí ó dára nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Ṣísàkóso ní abẹ́ ìtọ́ni Ọ̀run, àti gbígbèrò nípa àdúrà àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní ìmọ̀, wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí ó dára àti èyí tí ó ní ìbùkún. Bí wọ́n ṣe da iṣẹ́ wọn pọ̀ mọ́ ti àwọn àgbà òṣìṣẹ́, lílo agbára ọ̀dọ́ ọ wọn sí ìdáhùn tó dára, wọn yóò ní àwọn ańgẹ́lì ọ̀run ni ẹnìkejì, àti pé gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run,àǹfààní ni ó jẹ́ fún wọn láti kọrin àti láti gbàdúrà, àti láti ‘gbàgbọ́ kí wọn sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìgboyà àti òmìnira.Ìgbẹ́kẹ̀lé àti òtítọ́ ti wíwà níbì kan tí àwọn àṣojú ọ̀run yóò mú wá fuń wọn àti alábàá ṣiṣẹ́pọ̀ wọn, yóò darí wọn sí àdúrà àti ìyìn àti ti ìwọ̀ntúwọ̀nsì ti ìgbàgbọ́ tòótọ́.-Testimonies, vol.9, p.119.IIO 32.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents