Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìpè Fuń Ìtanijí

    Iṣẹ́ náà ń dópin lọ, gbogbo ọ̀nà ni ìwà ibi ń pọ̀ sì í. A ní ṣùgbọ́n àkókò kúkúrú tí a lè fi ṣiṣẹ́. Ẹ jẹ́ kí a jí lójú orun ẹ̀mí i wa, kí a sì ya ohun tí a ní tí a sì jẹ́ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ẹ̀mí i RẸ̀ yóò gbé pẹ̀lú ajíhìnrere tòótọ́, yóò sì fún wọn ní agbára fún iṣẹ́ ìsìn.-Southern Watchman, April 9,1903.IIO 80.10

    Jí ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ẹ tají. Máṣe sùn mọ́. “kín ló dé tí ò dúró níbi ní gbogbo ọjọ́ láí ṣe ohunkóhun?.” Jésù ń pè ọ́, wípé “Lọ ṣiṣẹ́ lónìí nínú ọgbà àjàrà à mi.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gba ẹ̀mí mímọ́, yóò mú kí ó farahàn; nítorí gbogbo agbára rẹ̀ ni yóò lò fún iṣẹ́ ìsìn. Gbogbo àwọn tí wọ́n gba Jésù nítòótọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ṣiṣẹ́. Wọ́n ní ìmọ̀lára ẹrù wúwo ti àwọn ọkàn. Ọlọ́run ń pe ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ní ìmọ̀ òtítọ́, ẹni tí í ṣe ìṣúra òtítọ́ tí a yà sí mímọ́, láti dìde kí ó sì fi ìmọ́lẹ̀ ọ̀run han àwọn mìíràn.- Review and Herald, Dec.6,1893.IIO 80.11

    Ẹ jí ará, nítorí ẹ̀mí tara à rẹ, ẹ jí. Láìsí oore-ọ̀fẹ́ Krístì o kò lè ṣe ohun kan, ṣiṣẹ́ nígbà tí o le è ṣè é.- Southern Watchman, July 17, 1906.IIO 80.12

    Tí ojú u wa bá ṣe é ṣí láti mọ àwọn ańgẹ́lì tí ó ṣubú lẹ́nu iṣẹ́ áti àwọn tí wọ́n ń gbé ìgbésí ayé ìdẹ̀ra tí wọ́n rò pé àwọn wà láìléwu,a ki yóò ṣe bí ẹni pé kò séwu. Àwọn ańgẹ́lì èṣù ń wá ní ọ̀nà a wa nígba gbogbo.- Testimonies, vol.2, p.302.IIO 81.1

    Ọlọrun ń pe gbogbo ènìyàn àti oníwàásù àti ènìyàn láti jí. Àwọn ọ̀run ti dìde lọ. Àwọn ìran ìtàn ayé tí ń lọ sópin kíákíá. A sì wà láarin ewu ìgbà ìkẹhìn. Ewú ń lá wà níwájú u wa, síbẹ̀ a kò tají. Àiṣiṣẹ́ àti àìnítara yìí nínú ọ̀nà Ọlọ́run jẹ́ ohun tí ó bani lẹ́rù jọjọ.Iraníyè ikú yìí sì wá láti ọ̀dọ̀ Sàtánì. - Testimonies, vol.1, pp.260, 261.IIO 81.2

    Kíni mo lè ṣe láti ta àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí ó ṣẹ́kù jí? A fihàn mí pé àwọn ìran tí ó bani lẹ́rù wà níwáju u wa; Sátánì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ń wá pẹ̀lú agbára a wọn láti lò lórí àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ó mọ̀ pé tí wọ́n bá sùn lọ fún ìgbà díẹ̀, ó dáa lójú nípa wọ́n, nítorí pé ìparun wọn dájú. - Testimonies, vol.1, p.263.IIO 81.3

    Nínú àwọn wákàtí tí ó kẹ́hìn yìí tí ìlẹ̀kùn àánú fún àwọn ọmọ ènìyàn nígbà tí ìpín ọkàn kọ̀ọ̀kan láìpẹ́ yóò ṣe ìpinnu títí láí, Ọlọrun ọ̀run àti ayé ń retí ìjọ ọ RẸ̀ láti jí dìde sí iṣẹ́ ju ti àtẹ̀hìnwá lọ. Gbogbo àwọn tí wọ́n ti dá láre nínú u Kristi nípa ìmọ̀ ọ ti òtítọ́ iyebíye, ni Jesu Oluwa kà kún àwọn àyànfẹ́ ẹ RẸ̀, tí wọn rí ojú rere ju àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀ ayé. Ó ń rò nípa tiwọn láti fi ìyìn in RẸ̀ Ẹni tí ó ó pè wọ́n jáde láti inú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu RẸ̀ hàn. Ìbùkún tí ó fifún wa nínú ìlàwọ́ ọ RẸ̀, ni a gbọdọ̀ sọ fún ẹlòmíràn. Àwọn ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà ni ó gbọdọ̀ lọ sí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, ẹ̀yà, èdè àti ènìyàn. - Prophets and Kings, pp.716, 717.IIO 81.4

    Kì í ṣe ọ̀kan nínú ọgọ́rùn ún láarin wa ni ó ń ṣe ohun kan ju kí ó kópa nínú u dídáwọ́lé àwọn kárà kátà a ti ayé. A kò tají tóbẹ́ ẹ̀ sí àwọn ọkàn tí ó ṣe iyebíye tí Kristi kú fún.- Testimonies, vol.8, p.148.IIO 81.5

    Ti àwọn àtẹ̀lé e Kristi bá jí gììrì sí iṣẹ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni yóò wà níbi tí ẹnì kan wà lónìí, polongo ìhìnrere ní ilẹ̀ àwọn kèfèrí.Gbogbo àwọn tí kò lè kópa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ ni yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ síbẹ̀ pẹ̀lú ohun ìní i wọn,ìbánikẹ́dùn un wọn àti àdúrà a wọn. Iṣẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú ìtara yóò wá wà fún àwọn ọkàn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti onígbàgbọ́.- Steps to Christ, p.81.IIO 81.6

    Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń gbádùn ìmọ́lẹ̀ ń lá àti ànfààní tí ó ṣe iyebíye, ṣúgbọ́n tí wọn kò ṣe n kànkan pẹ̀lú agbára a wọn tàbí owó o wọn láti fòye han ẹlòmíran. Wọn kò tilẹ̀ dúró fún pípa àwọn ọkàn an wọn mọ́ nínú ìfẹ́ ẹ ti Ọlọ́run, kí wọn ma baà jẹ́ ìnira fún ìjọ. Irú àwọn yìí yóò jẹ́ ìnira àti kọ̀lọ̀kọ́lọ́ tàbí ohun ìdènà ní ìjọba ọ̀run. Nítorí ti i Kristi, nítorí òtítọ́ ọ RẸ̀, nítorí i tara a wọn, irú àwọn yìí gbọdọ̀ tají kí wọn ṣiṣẹ́ láì sinmi fún ayérayé.- Review and Herald, March 1, 1887.IIO 82.1

    Ìjọ ti Kristi lè yẹ ní fífiwé ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ìgbé ayé ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan ni ó jẹ́ ọ̀kan ní ti làáàlá, ìnira, àti ewu. Ní gbogbo ọ̀nà, a rí àwọn ọ̀tá tí ó ń wòye, tí ó ń darí lọ nípasẹ̀ agbára ọmọ aládé ti òkùnkùn, tí kì í tògbé tí kò sì le fi ipò o rẹ̀ sílẹ̀ rárá. Níbikíbi tí onígbàgbọ́ bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹ̀sọ́, agbára ẹni búburú yìí yóò bìlù láìròtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìkà a rẹ̀ láti dojúkọ wọ́n. Àyàfi tí àwọn ọmọ ìjọ bá yára tí wọ́n sì ṣọ́ra, wọn yóò borí i wọn pẹ̀lú àwọn ète e rẹ̀.IIO 82.2

    Tí ó bá jẹ́ pé ìdajì nínú àwọn ọmọ ogun kò ṣe n ǹkankan tàbí sùn nígbà tí wọ́n pàṣẹ fún wọn láti wà ní ẹnu iṣẹ́; àṣeyọrí i wọn ni wọn yóò alaisootọ bì ṣubú, dì nígbèkùn tàbí ikú. Tí ẹnikẹ́ni bá bọ́ kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá, ṣé wọn yóò yẹ fún èrè ? Rárá; Ní kánkán ni wọn yóò gba ìdájọ́ ikú. Àti pé tí ìjọ Kristi kò bá bìkítà tàbí jẹ́ aláìṣòótọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu ń lá ni yóò mú lọ́wọ́. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó sùn tí ó jẹ́ àwọn jagun jagun onígbàgbọ́- kíni ó le è bani lẹ́rù tó o ? kíni ìtẹ̀síwájú tí a le ṣe tako ayé? Àwọn tí wọn kò dúró sẹ́hìn láì náání ní ọjọ́ ogun, bí ìgbà tí wọn kò ní inú dídùn, tí wọ́n dúró o kòkànmí sí ohun tí wọ́n ń jà lé lórí ni ìbá dára fún láti yí iṣẹ́ ẹ wọn padà tàbí kí wọn fi ẹgbẹ́ ológun sílẹ̀ níkánkán.- Testimonies, vol.5, p.394.IIO 82.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents