Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Àlá Tí ó Wúnilórí

  Nínú ìran tí a fifún mi ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹsàn án ọdún 1886, mò ń rìn lọ pẹ̀lu àwọn ẹgbẹ́ ń lá kan tí wọ́n ń wá èso “Berry”, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ l’ọ́kùnrin l’óbìnrin nínú ẹgbẹ́ yì í tí wọ́n ń ṣè rànwọ́ nínú kíkó èso yìí jo.Ó dàbí i pé a wà ní ìlú ń lá nítorí ilẹ̀ díẹ̀ ló wà tó ṣófo,ṣùgbọ́n ní àyíká ìlú náà,pápá tí ó ṣí sílẹ̀ wà, igbó ṣúúrú dáradára wà àti ọgbà tí a ti ro, kẹ̀ẹ̀kẹ́ ẹrù tí ó tóbi pẹ̀lú oúnjẹ fún ẹgbẹ́ ń lọ níwájú u wa.IIO 46.3

  Ní kété tí kẹ̀ẹ̀kẹ́ yì í dúró, àwọn ẹgbẹ́ yì í túká kààkiri láti wá èso. Gbogbo àyíká kẹ̀ẹ̀kẹ́ yì í kún fún igbó tí ó ga àti èyí tí kò ga, tí wọ́n ní èso Bérrì tó l’ẹ́wà; ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ yì í ti lọ jìnnà láti rí wọn. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn èso tí ó wà ní tòsí jọ pẹ̀lú ìṣóra, fún ìbẹ̀rù láti má a kó èyí tí kò pọ́n, tí ó sì dàpọ̀ pẹ̀lú èyí tí ó pọ́n, tí mo lè ṣa ọ̀kan tàbí méjì èso ọ̀pọ̀lọpọ̀.IIO 46.4

  Díẹ̀ lára èso tí ó tóbi tí ó sì dára ti jábọ́ sílẹ̀, àwọn kòkòrò sì ti jẹ díẹ̀ díẹ̀ lára a rẹ̀.”Oh”, Mo rò, “Tí a bá ti wọ ilẹ̀ yìí ṣáájú gbogbo èso iyebíye yìí le è rí ìgbàlà! Ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù bayíì, mà á síbẹ̀ síbẹ̀,ṣà wọ́n nínú ilẹ̀, mà á sì wò ó bóyá mo lè rí èyí tí ó dára nínú un wọn. Bí gbogbo èso Berry tilẹ̀ bàjẹ́, ó kéré tán màá lè fìhan àwọn ará ohun tí wọn ì bá rí tí kò bá jẹ́ pé wọ́n pẹ́ jù.”IIO 46.5

  Lẹ́yìn ìgbà náà, méjì tàbí méta nínú ẹgbẹ́ yìí wá ń rìn káàkiri ibi tí mo wà.Nwọ́n ń ṣe àwàdà, ó sì dàbí i pé wíwà pẹ̀lú ara wọn ti gba ọkàn an wọn.Rírí tí wọ́n rí mi, wọ́n sọ pé “A ti wo gbogbo ibí, a kò rí èso kankan”. Wọ́n wò pẹ̀lú ìyanu lórí iye tí mo ní. Mo sọ pè, “ọ̀pọ̀ sì wà tí a ní láti kójọ láti inú igbó yìí.”Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sìí ṣàá, ṣùgbọ́n wọ́n dúró láìpẹ́, wọ́n sọ pé, “kò dára fún wa láti ṣà níhìn ín; o rí ibí yìí, àti pé èso ibẹ̀ jẹ́ tìrẹ.” ṣùgbọ́n mo dáhùn, “kò mú ìyàtọ̀ kankan wá, ṣà jọ níbikíbi tí ẹ bá ti le rí ohunkóhun. Ọgbà Ọlọ́run nìyí,àwọn èso rẹ̀ sì nìwọ̀nyí; àǹfààní nìyí láti ṣà wọ́n.”IIO 47.1

  ṣùgbọ́n ó dàbí i pé mo tún dáwà. Fún ìgbà díẹ̀ mo gbọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti ẹ̀rín rínrín nínú u kẹ̀ẹ̀kẹ́.Mo pe àwọn tó wà níbẹ̀ jáde,“kíni ẹ̀ ń ṣe”? wọ́n dáhùn,“A kò rí èso Berry kankan , ó ti rẹ̀ wá ebi sì ń pa wá, a rò pé a ó wá sínú kẹ̀ẹ̀kẹ́ kí a sì jẹ oúnjẹ ọ̀sán. Nígbà tí a bá sinmi díẹ̀ a o tún padà.”IIO 47.2

  “Ṣùgbọ́n” mo sọ pé ” ẹ kò tíì mú ohunkóhun wá síbẹ̀. Ẹ̀ ń jẹ gbogbo ìpèsè wa láì fún wa ní òmíràn.Èmi kò lè jẹun báyìí; èso pọ̀ púpọ̀ láti ṣà.Ẹ kò rí nítorí pé ẹ kò wò dáa dáa tó, kò jábọ́ sí ẹ̀yìn igbó, ẹ gbọdọ̀ wá a. Lóótọ́, ẹ kò lè sà á pẹ̀lú ọwọ́ kíkún; ṣùgbọ́n nípa wíwò pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ láarin àwọn èso Berry tí kò pọ́n, ẹ máa rí èso éyí tí ẹ yán láàyò.”IIO 47.3

  Garawa à mi kèkeré ti fẹ́rẹ̀ kún fún èso Berry, mo sì gbé wọn lọ sínú kẹ̀ẹ̀kẹ́, mo sọ pé “èyí ni èso tí ó dára jù tí mo ṣà, mo ṣà wọ́n jọ nítòsí, nígbàtí ẹ ti da ara a yín láàmú nípa wíwá èso lọ sọ́nà jínjìn láì ṣà ṣeyorí.”IIO 47.4

  Lẹ́yìn náà,gbogbo wọn wá láti wá wo èso tèmi.wọ́n sọ pé “Eléyì í ni èso Berry ti igbó gíga, ó dúró ó sì dára.A kò rò pé a lè rí ohun kan nínú igbó gíga,fún èyí, Berry tinú igbó tí kò ga, a rí ṣùgbọ́n kò pọ̀.”IIO 47.5

  Mo sọ pé “ṣé ẹ o tọ́jú àwọn èso Berry yíì,àti pé ẹ tẹ̀lé mi láti lọ wá èso síi ní orí igbó gíga.” Ṣùgbọ́n wọn kò múra sílẹ̀ láti tọ́jú èso. Àwọn àwo oúnjẹ wà àti àpò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a ti fi kó oúnjẹ. Àárẹ̀ mú mi láti dúró, níkẹhín mo bèèrè “ṣé ẹ kò wá láti wá kó èso? Kín ló dé tí ẹ kò fi múra sílẹ̀ láti tọ́jú u rẹ̀.’’?IIO 47.6

  Ọ̀kan dáhùn, “Arábìnrin White, a kò lérò pé a lè rí èso níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé wà, tí ohun gbogbo si ń lọ;ṣùgbọ́n nítorí pé ò ń ṣe àníyàn láti kó èso, ló mú wa pinnu láti tẹ̀lé ọ. A léro pé a ó gbé è oúnjẹ tí yóò tó láti jẹ, a ó sì gbádùn ara wa níbi ìgbafẹ́ tí a kò bá kó èso kankan jọ.” IIO 48.1

  Mo dáhùn pé “kò yé mi irú iṣẹ́ yìí. Mà á tún lọ s’ígbó láìpẹ́. Ọjọ́ sì ti bù lọ tán, òru sì fẹ́rẹ̀ dé,tí a kò ní lè rí èso kankan ṣà.” Díẹ̀ tẹ̀lé mi, nígbà tí àwọn tó kù dúró lẹ́gbẹ̀ ẹ́ kẹ̀ẹ̀kẹ́ láti jẹun.IIO 48.2

  Ní ojú kan àwọn ẹgbẹ́ kékeré ti gbà, wọ́n sì ń’ṣàròyé nípa nkàn kan tí ó wù wọ́n. Mo súnmọ́ wọn, mó sì ríi pé ọmọ kékeré tí ìyá rẹ̀ gbé lọ́wọ́ ni ó mú wọn lọ́kan. Mo sọ pé, àkókò péréte ni a ní, yóò sì dára kí ẹ ṣiṣẹ́ nígbà tí ẹ bá lè ṣè é.”IIO 48.3

  Ìfọkànsí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ mú ọkàn an wọn fà mọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n ń sáré ìje lọ sí ibi kẹ̀ẹ̀kẹ́. Nígbà tí wọ́n dé bẹ̀, àárẹ̀ mú wọn tí wọ́n sì fi ní láti jòkó kí wọn sì sinmi. Àwọn tí ó ṣẹ́kù náà ti jòkó ní orí koríko látí sinmi.IIO 48.4

  Báyìí,ilẹ̀ ń ṣú lọ, díẹ̀ sì ni ohun tí à ṣe ní àṣepé.Níkẹhìn, mo sọ pé “Ẹ̀yin ará,ẹ pe èyí ní ìrìn àjò tí kò yọrí sí rere. Tí ó bá jẹ́ báyìí ni ẹ ń ṣiṣẹ́, kò yà mí lẹ́nu nípa àì ṣe àṣeyọrí i yín. Àṣeyọrí tàbí ìbàkù u yín dúró lórí ọ̀nà tí ẹ gbà mú iṣẹ́ náà. Èso Berry wà níbí; nítorí mo rí wọn. Díẹ̀ nínú yín ni ó ń wá igbó tí kò kún lásán;àwọn mìíràn rí èso Berry díẹ̀; ṣùgbọ́n wọ́n ń kọjá lára igbó gíga, nítorí pé ẹ kò rò láti rí èso lórí i wọn.Ẹ rí pé èso tí mo ṣàjọ tóbi ó sì pọ́n. Níwọ̀n ìgbà díẹ̀, Berry míràn yóò pọ́n, a tún wá lè padà lọ sínú igbó lẹ́ẹ̀kan síi. Ọ̀nà yìí ni a fi kọ́ mi láti wá èso. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ti wà nítòsí kẹ̀ẹ̀kẹ́, ẹ le è rí èso bí èmi ṣe rí.IIO 48.5

  “Ẹ̀kọ́ tí ẹ ní lónìí, ẹ fifún àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ láti ṣe irú iṣẹ́ yìí, wọn yóò le ṣe àwòkọ́ṣe. Olúwa ti gbé iṣẹ́ èso wíwá nínú igbó kalẹ̀ láarin ibi tí àwọn ènìyàn pọ̀ sí, ó sì ń retí i yín láti ṣà wọ́n. Ṣùgbọ́n ẹ ti wà papọ̀ púpọ̀, láti jẹun, láti ṣe ìdárayá, ẹ kò wá sí pápá pẹ̀lú ìtara láti wá eso. Láti ibí yìí lọ ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìtara àti ìgbónára, àti pẹ̀lú oríṣiríṣi àfojúsun tàbí kí iṣẹ́ ẹ yín kó má láṣeyọrí. Nípa ṣí ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà tí ó dára, ẹ o le kọ́ àwọn ọ̀dọ́ òṣìṣẹ́ irú ọ̀rọ̀ bí oúnjẹ jíjẹ, àti ìgbafẹ́ jẹ́ nǹkan tí kò ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀. Iṣẹ́ àṣekára ló mú kí a lè mú kẹ̀ẹ̀kẹ́ ẹrù tí ó pèsè wá, ṣùgbọ́n ẹ ti rò púpọ̀ nípa pípèsè ju eso tí ẹ ní láti rù lọ ilé gẹ́gẹ́ bí àyọrísí àwọn iṣẹ́ ẹ yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ wá àwọn tí ó wà lọ́nà jínjìn;lẹ́yìn èyí, ẹ tún lè padà láti wá ṣiṣẹ́ ní tòsí, ẹ o sì wá ṣe àṣeyọrí.”- Gospel Workers, pp.136-139.IIO 49.1

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents