Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Èrè Ọjọ́ Iwájú

    Ayérayé.- Nígbà tí a fi ìtara ṣe ìrànlọ́wọ́ níbi tí ó ti wúlò, onígbàgbọ́ tòótọ́ ń fi ìfẹ́ ẹ rẹ̀ hàn sí Ọlọ́run àti fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀. O le è pàdánù ẹ̀mi i rẹ̀ nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé láti kó àwọn ọ̀ṣọ́ ọ Rẹ̀ jọ sí ọ̀dọ̀ ara a Rẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò tún rí ẹ̀mí i rẹ̀ he.- Testimonies, vol.9, p.56.IIO 271.5

    Ìfi Ayọ̀ kíni Kú Àbọ̀ Sílé. - Dúró ní ìloro ẹnu ọ̀nà ayérayé, kí o sì gbọ́ ìkíni kú àbọ̀ olóore òfẹ́ tí wọ́n ń fi fún gbogbo ènìyàn tí ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi nígbà tí wọ́n wà láyé, tí wọ́n gbà wípé ànfààní àti ọlá ni ó jẹ́ fún wọn láti jìyà nítorí i Rẹ̀....Níbẹ̀ ni àwọn tí a ti rà padà yóò máa kí àwọn tí ó darí i wọn sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà tì a gbé gá. Wọn yóò sì dàpọ̀ láti má a yin Ẹni tí ó kú kí ènìyàn ba à lè ní ayé tí ó dógba pẹ̀lú ayé ti Ọlọ́run. Ìjà dópin. Gbogbo ìpọ́njú àti ìjà tí parí. Orin ìṣẹ́gun sì kún gbogbo ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rà padà ti dúró yí ìtẹ́ Ọlọ́run ká. Wọn yóò sì fi agbára kọ orin ayọ̀, “Yíyẹ, yíyẹ ni Ọ̀dọ́ -Àgùtàn náà tí a pa”, Ó sì ti rà wá padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọrun. The Ministry Of Healing, pp.506,507.IIO 271.6

    Tí àkọsílẹ̀ bá fihàn pé bí ayé e wọn ti rí nìyí, àti wípé wọ́n ní ìwà a sùúrù, ẹ̀mí ìṣẹ́ra-ẹni, ohùn àánú, dájúdájú wọn yóò gba ìbùkún àti oore-ọ̀fẹ́, “Kú àbọ̀”. “Ẹ wá ẹ̀yin alábùkún Bàbá à Mi, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún-un yín láti ìpilẹ̀sẹ̀ ayé wá”.-Testimonies,0vol.3,p.525.IIO 272.1

    Àyíká Ọ̀run.- Nísinsinyìí ìjọ ti di ológun. Nísinsinyìí ni a ní ìdojúkọ láti ọ̀dọ̀ ayé tí ó kún fún òkùnkùn, tí ìbọ̀rìṣà ti fẹ́rẹ̀ gba àkóso o rẹ̀ tán. Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀wá tí a yóò jagun tí a yóò sì ṣẹ́gun. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni ó yẹ kí a ṣe láyé gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀run. Gbogbo orílẹ̀-èdè tì a ti gbàlà kì yóò mọ òfin mìíràn mọ́ bíkòse òfin ti ọ̀run. Gbogbo ènìyàn ni yóò jẹ́ ọmọ ìdílé kan náà tí ó ní ìṣọ̀kan àti ayọ̀ tí a sì fi aṣọ ìyìn àti ọpẹ́ bò tí í ṣe aṣọ òdodo Kristi. Gbogbo ẹ̀dá nínú ìfẹ́ tí ó tayọ ni wọn yóò fi orin ìyìn àti ìjúbà fún Ọlọ́run. A yóò sọ ayé di mímọ́ nípa ìmọ́lẹ̀ ọ̀run. Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá yóò mọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ti oòrùn nígbà tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn yóò lágbára lọ́nà méje ju bí ó ti wà báyìí. Àwọn ọdún yóò má a tẹ̀síwájú pẹ̀lú inú dídùn. Níbì kan àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò jùmọ̀ kọrin papọ̀, àwọn ọmọ Ọlọ́run àti Kristi yóò fohùn sọ̀kan kígbe pé, “Kì yóò sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ikú mọ́”. —The Ministry of Healing, p.504.IIO 272.2

    Ayọ̀.- Èrè Kristi fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ Rẹ̀ ni kí wọn wọ inú ayọ̀ ọ Rẹ̀. Irú ayọ̀ tí Kristi pàápàá ń fi ìtara wo ọ̀nà fún nígbà tí ó gbé ẹ̀bẹ̀ ẹ rẹ̀ lọ síwájú u Bàbá a Rẹ̀ wípé, “Mó fẹ́ kí àwọn pàápàá, tí ẹ̀yin ti fifún Mi wà pẹ̀lú ù Mi níbi tí Èmi pàápàá wà”.- Testimonies, vol.6, p.309.IIO 272.3

    Nínú ayé e wa níbí, ayé níhìn-ín, níbi tí a ti ń gbìyànjú láti dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀, ayọ̀ tí ó ga jù àti ẹ̀kọ́ tí ó ga jù wà nínú iṣẹ́ ìsìn. Àti ní ọjọ́ iwájú, níbi tí ènìyàn ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ ọ gbèdéke ẹ̀ṣẹ̀, nínú iṣẹ́ ìsìn ni a ti ní ayọ̀ tí ó ga jù àti ẹ̀kọ́ tí ó gajù lọ- ìjẹ́rìí, bẹ́ẹ̀ ni à ń kọ́ ẹ̀kọ́ titun bí a ti ń ṣe ìjẹ́rì í. “Ọ̀rọ̀ ti ògo tí ó wà nínú ohun ìjìnlẹ̀ yìí” èyí tí í ṣe Kristi nínú u wa, ìrètí ògo” Education,p.309.IIO 273.1

    Bí wọ́n ti ń ṣe alábápín nínú ìyà a Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò tún jẹ́ alábápín nínú ògò o Rẹ̀. Ẹni tí ó bá mu nínú aago ìjìyà a Rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú u Rẹ̀, yóò jẹ́ alábápín nínú ayọ̀ ọ Rẹ̀.- Thought From the Mount of Blessing, p.27.IIO 273.2

    Àbáyọrí i fífúnrúgbìn.- Gbogbo bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ń fa ọkàn —an wa tí a sì ń ṣe rere tí a tún ń fà sí Ọlọ́run ni wọn ń ṣe àkọsílẹ̀ ẹ rẹ̀ nínú àwọn ìwé ọ̀run àti ní ọjọ́ Ọlọ́run, olúkúlùkù ènìyàn tí ó ti jọ̀wọ́ ara a rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun èlò lọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni wọn yóò gbà láàyè láti wo ohun tí ìgbé ayé e wọn.- Testimonies, vol.6, p.310.IIO 273.3

    Nigba ti awọn ti a ra pada ba duro niwaju Oluwa, awọn ọkan iyebiye ni yoo ma a dahun nigba ti wọn ba pe orukọ wọn nitori iwa otitọ ati suuru ti wọn lo fun wọn ati ẹbẹ adura ti o n parọwa kikankikan fun wọn lati sa lọ si ilu odi. Nipa bayi gbogbo awọn ti o ti jẹ oṣiṣẹ pẹlu Ọlọrun nigba ti wọn wa laye yii ni yoo gba ere e wọn. - Testimonies, vol.8, pp.196, 197.IIO 273.4

    Irú ayọ̀ ń lá wo ni yóò jẹ́ nígbà tí àwọn tí a rà padà wọ̀nyí bá pàdé ní ìfojúkojú pẹ̀lú àwọn tí ó jìyà fún wọn! Báwo ni ọkàn àwọn tí kò tẹ́ ara wọn lọ́rùn nípa ṣíṣe ìfẹ́ ẹ wọn yóò ṣe kún fún ìtẹ́lẹ́rùn tó bíkòṣe pé kí wọn jẹ́ ìbùkún fún àwọn tí ó ku díẹ̀ káà tó fún àní àwọn tí ìbùkún un wọn kéré jọjọ. Nígbà náà ni òye ìlérí yìí yóò wá yé wọn, ” Ẹ yóò jẹ́ alábùkún, nítorí pé a kò lè san wọ́n ní èsan nítorí tí wọn yóò gba èsan —an wọn nígbà tí àwọn olódodo bá jíǹde”.- Gospel workers, p.519.IIO 273.5

    Ní ọ̀run, a yóò rí ojú àwọn ọ̀dọ́ tí a ràn lọ́wọ́, àwọn tí a pè sí ilé e wa, àwọn tí a kóyọ kúrò nínú ìdánwò. A yóò rí ojú u wọn tí yóò má a fi dídán ògo Ọlọ́run hàn.- Testimonies, vol.6, p.348.IIO 273.6

    Irú iṣẹ́ wo ni a le fi wé jíjẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú u Kristi àti àwọn angẹ́lì ọ̀run nínú ìpinnu iṣẹ́ ìgbàlà! Àkójọpọ̀ ògo Ọlọrun ni yóò wà nípasẹ̀ àwọn ọkàn kọ̀ọ̀kan tí a gbàlà èyí tí yóò hàn lára àwọn tí a gbàlà àti àwọn tí ó jẹ́ ohun èlò nínú ìgbàlà a Rẹ̀.- Testimonies, vol.2, p.232.IIO 273.7

    Àwọn tí a ràpadà yóò pàdé bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì mọ àwọn tí wọ́n pe àkíyèsí i wọn sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà tí a gbé sókè. Irú u gbédè gbẹ́yọ̀ wo ni wọn yóò ní pẹ̀lú àwọn ọkàn yìí! “Mo jẹ́ Ẹlẹ́ṣẹ̀”. wọn yóò sọ bayii, “laini Ọlọrun ati laini ireti laye, o si tọ mi wa, o si pe akiyesi I mi si ọdọ Olugbala ti o sọwọn gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun mi. Mo si gba A gbọ. Mo ronu piwada kuro ni u ẹṣẹ ẹ mi, a si mu mi joko pẹlu awọn eniyan Mimọ ọ Rẹ ni ọrun ninu u Kristi Jesu”. Awọn miiran yoo sọ pe, Mo jẹ keferi ni ilẹ ẹ keferi. O fi awọn ọrẹ ẹ rẹ silẹ ati ibugbe e rẹ to rẹwa, o si wa kọ mi bi a ṣe le ri Jesu, ki n si gba A gbọ gẹgẹ bi Ọlọrun otitọ kan ṣoṣo. Mo pa awọn oriṣa mi run, mo si n sin Ọlọrun, ni bayii mo ri I lojukooju. A ti gbami la, titi aye, lati ma a wo ẹni ti mo fẹran titi lai. Mo si fi oju igbagbọ nikan ṣoṣo ri I, ṣugbọn ni bayii, mo ri I gẹgẹ bi O ti ri. Mo le e fi ẹ̀mí ìmoore è mi hàn fún —Un fún àánú ìràpadà àní fún Ẹni tí ó fẹ́ mi tí ó sì fi ẹ̀jẹ̀ ẹ Rẹ̀ wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù. - Gospel Workers, p.518.IIO 274.1

    Àwọn mìíràn yóò fi ẹ̀mí ìmoore wọn hàn fún àwọn tí ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa tí wọ́n sì fi aṣọ bo àwọn tí wọ́n wà ní ìhòhò. “Nígbà tí àìnírètí so ọkàn mi pọ̀ mọ́ àìgbàgbọ́, Ọlọ́run rán ọ sí mi”, wọn yóò sọ bẹ́ẹ̀ “láti sọ ọ̀rọ̀ ìrètí àti ìtùnú. Ó fi oúnjẹ fún mi láti tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún mi èyí tí ó ta ọkàn mi jí sí ohun tí n kò ní nínú ẹ̀mí. Ó ṣe mí gẹ́gẹ́ bí arákùnrin-in rẹ̀. Ó bá mi kẹ́dùn nínú ìbànújẹ́ ẹ̀ mi bẹ́ ẹ̀ ni ó mú ọgbẹ́ ọkàn mi sàn kí n bà a le di ọwọ́ ọ Kristi tí a nà sí mi mú láti gbàmí là. Nínú àìmọ̀kan-an mi ó kọ́ mi pẹ̀lú u sùúrù pé mo ní Bàbá kan ní ọ̀run tí Ó bìkítà fún mi. Ó ka àwọn ìlérí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó sọ̀wọ́n fún mi. Ó ru ìgbàgbọ́ sókè nínú ù mi pé yó Ò gbàmí là. Ọkàn òkúta à mí rọ̀, ó fọ́ ọ wẹ́ẹ́wẹ́, ó gbọgbẹ́ bí mo ṣe ronú lórí ìrúbọ tí Kristi ṣe fún mi. Nígbà náà ni ebi àkàrà ìyè náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa mí, tí òtítọ́ náà sì jẹ́ iyebíye sí ọkàn- àn mi. Báyìí, a ti gbàmí là, àní ìgbàlà títí ayé, láti má a wà níwájú u Rẹ̀, kí n sì má a yin Ẹni tí ó fún mi ní ìyè e Rẹ̀.- Gospel Workers, pp.518,519.IIO 274.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents