Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    IKÚ IRANÍYÈ LATI ỌWỌ EṢU.

    Ènìyàn Ọlọ́run gbọdọ̀ gba ìkìlọ̀ kí wọn sì ṣ’àkíyèsí àwọn àmì ìgbà ìkẹhìn. Àwọn àmì ti pípadà bọ̀ Krístì hàn gba n gba láì ṣiyèméjì.Fún ríro nǹkan wọ̀nyí, gbogbo ẹni tí ó sọ òtítọ gbọdọ̀ jẹ́ oníwàásù alààyè. Ọlọ́run ń pe gbogbo àwọn oníwàásù àti àwọn ènìyàn, láti tají. Gbogbo ọ̀run sì dìde.Àwọn ìran ti ìtàn ayé tí ń dópin. Ati wa ní àarin àwọn ewu ìgbà ìkèhìn. Àwọn ewu tí ó wà níwájú u wa lágbára, síbẹ̀ a kò tají. Àì ṣíṣẹ kankan àti àì ní ìtara nínú isẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ìbẹ̀rù.Ikú ìraníyè yìí wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù.- Testimonies,vol.1,pp260,261.IIO 37.1

    Àìgbagbọ́, gẹ́gẹ́ bí aṣọ ìlékè e pósí,tí yí àwọn ìjọ ká, nítorí pé,wọn kò lo àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fifún wọn, nípa fífi ìmọ́lẹ̀ hàn fún àwọn tí kó mọ̀ nípa òtítọ́ iyebíye yìí.Ọlọ́run ń pe àwọn ọkàn tí a ti dáríjì, àwọn tí wọ́n ti ń yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀, láti jẹ́ kí òtítọ́ di mímọ̀ fún àwọn mìíràn.- General Conference Bulletin, 1893, p.133.IIO 37.2

    Sátánì ń wá ọ̀nà nísinsiǹyí láti mú àwọn ènìyàn Ọlọ́run nínú ipò àì ṣiṣẹ́, láti má jẹ ẹ́ kí wọn kó’pa nínú títan òtítọ́ kálẹ̀, kí a baà lè wọ̀n wọ́n níkẹhìn nínú òṣùwọ̀n,( kí wọn má sì kúnjú òṣùwọ̀n.).- Testimonies,vol.1, p.260.IIO 37.3

    Ènìyàn wà nínú ewu, ogunlọ́gọ̀ ló sì ń ṣègbé. Sùgbọ́n báwo ni díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní àtẹ̀lé e Krístì ṣe ní ìnira fún àwọǹ ọkàn yìí. Àyànmọ́ ti ayé yìí ni a gbé kọ́ ní orí ìwọ̀n; àwọn tí wọ́n gba òtítọ́ yìí tí a fún ọmọ ènìyàn alára kíkú yìí kò fi taratara mì `wọ́n. Kò sí ìfẹ́ bí irú ti Krístì tí ó mú u fi ilé rẹ̀ ọ̀run sílẹ̀ tí ó sì gbé àwọ̀ ènìyàn pé kí àwọn ènìyàn lè fọwọ́ ba ọmọ ènìyàn sí Ọlọ́run fúnra a rẹ̀. Ìrayè wà, aláìlágbára, lórí àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tí ó ń dínà wọn láti ní òye iṣẹ́ ti wákàtí náà.-Christ Object lessons, p.303.IIO 37.4

    Èṣù ǹ lo alá ì jáfáfá, ọ̀lẹ tí ó ń pe ara a rẹ̀ ní onígbàgbọ́ láti mú ọmọ ogun rẹ̀ lọ́kan le, kí ó sì jèrè àwọn ọkàn sọ́dọ̀ o rẹ̀. Ọ̀pọ̀ tí ó rò pé àwọn kò ṣe iṣẹ́ pàtó fún Krístì, wọn kò ní wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa, ǹ jẹ́ kí ọ̀tá fún wọn ní iṣẹ́ kí wọn lè jogún ànfààní. Nípa ìbàkù wọn láti jẹ́ aláì ṣèmẹ́lẹ́ òṣìṣẹ́ fún Olúwa wọn,láti fi iṣẹ́ sílẹ̀ láì ṣe àti láti má sọ̀rọ̀ síta, wọ́n ti gba èṣù láàyè láti ṣàkóso àwọn ọkàn wọn tí wọn ì bá ti jèrè fún Krístì.- Christ Object Lessons, p.280.IIO 38.1

    Nígbà tí mo ṣàṣàrò nínú ìwé mímọ́, àyà mi já fún Ísírélì ti Ọlọ́run ní àsìkò ìkẹhìn yìí.Wọ́n gbà wọ́n láti sá fún ìbọ̀rìṣà. Mo bẹ̀rù nítorí pé,wọ́n sùn lọ, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ayé tí yóò sì mú kí ó nira fún wọn láti mọ̀ láarin ẹni tí ó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.Àlàfo náà fẹ̀ láarin Krístì àti àwọn ènìyàn, tí ó sì ń dínkù láarin wọn àti ayé.Àwọn àmì yìí hàn gba n gba láarin àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ènìyàn Krístì àti ayé ti fẹ́rẹ̀ parẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Isírẹ́lì ìgbà a nì, wọ́n ń tẹ̀lé ohun ìríra ti orílẹ̀-èdè tí ó yi wọn ká.- Testimonies, vol.1,p.277.IIO 38.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents