Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ —KEJÌLÁ ÌWÀÁSÙ ÌHÌNRERE E TI BÍBÉLÌ

    Èrò Ìbí i Ti Ọ̀run

    Èrò láti gbé Bibeli kíkà kalẹ̀ jẹ́ èrò láti ọ̀run. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà, àti àwọn ọkùnrin àti àwọn ọbìnrin, tí wọ́n lè kópa nínú ẹ̀ka iṣẹ́ ajíhìnrere. A lè jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò fẹ́ jẹ́ alágbára eniyan Ọlọrun gbèrú. Nípa ọ̀nà yìí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ni wọ́n ti gba ọrọ Ọlọrun; àwọn òṣìṣẹ́ ni a múwá sínú ìfojúrinjú pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà. A gbé Bíbélì lọ sínú àwọn ìdílé, àwọn òtítọ́ mímọ́-ọn RẸ̀ ni a sì mú lọ sí ẹ̀rí ọkàn.Àwọn ènìyàn ni a bẹ̀ láti kà, láti yẹ̀wò, kí wọn sì ṣe ìdájọ́ fúnra a wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ wà lábẹ́ ànfààní i ti gbígbà tàbí kíkọ ìfòyehàn láti ọ̀run. Ọlọ́run kò ní gba iṣẹ́ iyebíye tí wọ́n ṣe fún-Un yìí láàyè láti lọ láì lérè.. Yóò dé gbogbo àṣeyọrí yì í ládé pẹ̀lú ìgbìyànjú tí a ṣe pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ní orúkọ ọ RẸ̀.- Gospel Workers, p.192.IIO 141.1

    Iṣẹ́ ẹ wa ni a ti fi àmì sí fún wa nípaṣẹ̀ bàbá a wa tí ń bẹ lọ́run.A ní láti gbé Bibeli i wa, kí a lọ láti ṣe ìkìlọ̀ fún aráyé.A ní láti jẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ń ran ni lọ́wọ́ nínú u gbígba ọkàn là,-àwọn orísun ibi tí ìfẹ́ ẹ RẸ̀ ojoojúmọ́ ti ń sun fún àwọn tí ó ń ṣègbé.- Testimonies, vol.9. p.150.IIO 141.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents