Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìgbé Ayé Krìstẹ́nì Nínú Onírúurú ilẹ̀ Tí a Lè Fojú Rí

  Ọkàn tí ó gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò dàbí adágún odò tí ó gbẹ, kò dàbí àkúfọ́ àmù tí ó sọ ìṣúra rẹ̀ nù. Ó dàbí omi tí ó ń ṣàn láti orí òkè, tí ó ń bọ́ àwọn orísun omi tí kò lè yẹsẹ̀, tí tútù u rẹ̀, tí àwọn omi yẹ̀rì yẹ̀rì ń fò láti inú àpáta sínú àpáta, ń tu ọkàn àwọn tí ó rẹ̀ lára, àwọn tí òrùgbẹ ń gbẹ, àwọn tí a di ẹrù wúwo lé. Ó dàbí omi tí ó ń ṣàn látì gbà dé gbà. Ìlọsíwájú u rẹ̀ sì jìn ó sì fẹ̀, títí tí afúnni-lómi ìyè tàn káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Orísun omi tí ó ń kọrin ní ọ̀nà a rẹ̀ fi ẹ̀bùn àwọ̀ tútù nini rẹ̀ sẹ́hìn, koríko tí ó wà ní etí i bèbè ni ó tutù, àwọn igi i rẹ̀ lọ́rọ̀ ní àwọ̀ tútù, àwọn òdódó o rẹ̀ pọ̀ lápọ̀jù. Nígbà tí ayé bá wà ní ìhòhò tí ó sì pọ́n lábẹ́ ooru gbígbóná tí ń jó nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ìlà ti àwọ̀ tútù ni ó sàmì sí ipa odò.IIO 106.1

  Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ọmọ Ọlọ́run tòótọ́. Ẹ̀sìn- in Krístì fi ara a rẹ̀ hàn bí agbára, bí agbára ìwà láàyè, tí ó la ìpìlẹ̀ kalẹ̀, ààyè, ń ṣiṣẹ́ agbára ẹ̀mí. Nígbà tí ọkàn bá ṣí sílẹ̀ sí ipa òtítọ́ àti ìfẹ́ ẹ ti ọ̀run, àwọn ìpìlẹ̀ yìí yóò ṣàn lọ lẹ́ẹ̀kan síi bí odò ṣíṣàn nínú aginjù, tí ó ń mú kí àìléso farahàn níbi tí ìyàgàn àti ọ̀dá wà nísinsinyìí.-Prophets and Kings, pp. 233,234.IIO 106.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents