Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìpè Tí ó Dájú

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọn yóò pè lọ sí pápá láti ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run láti ojúlé dé ojúlé, fífún ni ní àwọn Bíbélì kíkà, àti láti gbàdúrà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ ẹ́.- Testimonies, vol.9, p.172.IIO 141.3

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ ni ó ní láti kó ipa a wọn, nínú ẹ̀kọ́ ọ Bíbélì láti ojúlé dé ojúlé kí wọn sì fún wọn ní Bíbélì kíkà nínú àwọn ìdílé.- Testimonies, vol.9, p.141.IIO 141.4

    Àwọn ọbinrin tí wọ́n ya ara a wọn sí mímọ́ gbọdọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ẹ Bibeli láti ojúlé dé ojúlé. - Testimonies, vol.9, pp.120, 121.IIO 141.5

    Tí a ba tẹ̀lé àwọn ipaṣẹ̀ ẹ Kristi, a gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn tí wọ́n nílò iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ wa. A ní láti ṣí Bibeli láti ní òye, kí a sì sọ ohun tí Ọlọrun ń béèrè nínú òfin, sọ àwọn ẹ̀tọ́ Ọlọ́run nínú òfin, ka àwọn ìlérí fún àwọn tí wọ́n ń lọ́ tìkọ̀ tìkọ̀, sọ àwọn aláìbìkítà jí, kí o sì fi agbára fún aláárẹ̀.- Gospel Workers, p.336.IIO 141.6

    Nínú ìrírí i Fílípì àti ti Etópíà ṣe àfihàn iṣẹ́ tí Ọlọrun pe àwọn ènìyàn-an RẸ̀ sí. Ará Etópíà ni ó dúró fún ẹgbẹ́ ń lá kan tí ó nílò ajíhìnrere bí i Fílípì, àwọn ajíhìnrere tí wọn yóò gbọ́ ohùn Ọlọ́run, tí wọn yóò sì lọ sí ibi tí ó rán wọn. Àwọn mìíràn wà nínú ayé tí wọn ń ka ìwé mímọ́, ṣùgbọ́n tí wọn kò ní òye ìtumọ̀ pàtàkì i rẹ̀. Àwọn ọkunrin ati awọn obìnrin, tí wọn ní ìmọ̀ ọ ti Ọlọrun ni a nílò láti ṣàlàyé ọrọ yìí sí àwọn ọkàn.- Testimonies, vol.8, pp.58,59.IIO 142.1

    Láarin àwọn ọmọ ìjọ ọ wa, a gbọdọ̀ ní iṣẹ́ ojúlé dé ojúlé nínú fífún ni ní àwọn Bibeli kika. - Testimonies, vol.9, p.127.IIO 142.2

    Jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ lọ láti ojúlé dé ojúlé, kí wọn ṣí Bibeli fún áwọn ènìyàn. - Testimonies, vol.9, p.123.IIO 142.3

    Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú ni àwọn tí wọn le è ṣiṣẹ́ kalẹ̀ sí, àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n rí ṣe dáadáa, tí wọn kò tí ì gbọ́ òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí rárá. A gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi wọ̀nyí. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ìjọ tí a kò gbọ́wọ́ lé lórí mú ọ̀nà iṣẹ́ yìí. Nípa yíyá tàbí títa àwọn ìwé, nípa pínpín àwọn ìwé, àti nípa Bibeli kíkà, àwọn ọmọ ijọ tí a kò gbọ́wọ́ lé lórí lè ṣe púpọ̀ ní àwọn àdúgbò o wọn. Ní ìfẹ́ kíkún fún àwọn ọkàn, wọ́n lè polongo ìhìnrere pẹ̀lú agbára tí ọ̀pọ̀ yóò sì ní ìyípadà ọkàn.- Testimonies, vol.9, p.35.IIO 142.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents