Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ipò o Rírí Gbà

    Èmí Mímó yóò lo sí òdò àwon tí ó ń bèbè fún oúnje, orun fún àwon ara won.- Testimonies, Vol. 6, p. 90.IIO 252.1

    Nígbà tí a bá mú okàn wa wà ní ìsòkan pèlú Krístì, tí a sì wà ní ìbáré pèlú isé Rè, èmí tí ó bà lé àwon omo èyìn ní ojó Péntékòstì yóò bà lé wa.-Testimonies, Vol. 8, p. 246.IIO 252.2

    Kìí se pé ìhámó tàbí ìdènà kankan wà lódò Olórun, tí ó wípé kí òlá rè kó má sàn dé òdò omo ènìyàn.-Christ’s Object Lesson, p. 419.IIO 252.3

    Èmí fé kí a béèrè, òun yóò sì fi fún wa.-Christ’s Object Lesson, p. 121. Nígbà tí èyí jé ònà tí àwa ní láti lò láti gba agbára, kíni ìdí tí àwa yóò fi pòǹge fún èbùn èmí-mímó. Kílódé tí a kìí fií so, gbàdúrà láti ní, kí a sì wàásù nípa rè.-The Acts of Apostles, p. 50.IIO 252.4

    Tí a kò bá rí mímúse ìlérí náà bí ó ti ye, ìdí ni pé a mo rírì ìlérí náà bí ó ti ye. Tí gbogbo ènìyàn bá ń fé, gbogbo ènìyàn náà ni yóò rí èbùn èmí-mímó gbà.-The Acts of Apostles, p. 50.IIO 252.5

    Ní ìtèbomi èmí-mímó lójoojúmó, gbogbo òsìsé ní láti téwó èbè rè sí Olórun lójoojúmó. Ìpéjopò àwon òsìsé Olórun gbodò bèèrè fún àánú òtò, fún ogbón òrun, wón sì gbodò mò bí won yóò se gbèrò àti sisé pèlu ogbón. Ó se pàtàkì kí won gbàdúrà kí Olorun kó wè wón sínú isé Rè pèlú èmí rè tí ó pò gidi.-The Acts of Apostles, pp. 50, 51.IIO 252.6

    Kí gbogbo Krìsténì mú ìyapa kúrò, kí won ó sì fi ara wò fún Olórun fún ìgbàlà àwon tí ó sonù. E jé kí won ó bèrè pèlú ìgbàgbó fún ìbùkún tí a sèlérí fún won, yóò sì wà.-Testimonies, Vol. 8, p. 21.IIO 252.7

    Àwon omo èyìn yóò bèèrè fún ìbùkún nítorí ti ara won. Wón rè sílè nítorí àwon tí wón ní láti gbà sílè. Ìhìnrere náà gbodò tàn kálè gbogbo ayé, wón sì gba agbára èmí-mímó tí Jésù sèlérí fún won, èmí-mímó rò sórí won, a sì yí òpòlopò èmí padà ní ojó kan.-Southern Watchman, Aug. 1905.IIO 252.8

    Olórun ti se ìlérí èmí-mímó fún ìjo Rè, ìlérí sì jé ti wa bí ó ti wà fún àwon omo èyìn àkókó. Sùgbón bí gbogbo ìlérí, a fifún wa pèlú àwon ohun tí ó ròmọ. Òpòlopò ni ó gbàgbó tí wón sì so nípa iléri Oluwa, wón sòrò nípa Krístì, síbè wón kò gba èrè kankan tàbí ànfààní kankan. Won kò fi okàn won sílè láti dára àti tó nípasè àwon èmí òrun. A kò lè lo èmí-mímó, èmí-mímó ni ó lè lò wá. Nípasè èmí-mímó, Olórun ṣiṣẹ́ nínú àwon ènìyàn Rè “láti sisé àti láti se ìfé Rè”. Sùgbón òpòlopò ni kò se èyí, wón fé darí ara won, ìdí nìyí tí won kò se gba èmí òrun. Àwon tí ó dúró ní ìrèlè nínú Olúwa nìkan, tí ó dúró ní ìtósónà àti ògo Rè ni à ń fi èmí-mímó fún. Agbára Olorun dúró de ìbéèrè won. Ìlérí ìbùkún yìí, tí a gbà pèlú ìgbàgbó mú gbogbo ìbùkún mìíràn tèle. A fi fún un nínú ewà olá Olúwa wa, Ó sì setán láti fi fún àwọn okàn tí ó setán àti gbà á.-The Desire of Ages, p. 672.IIO 253.1

    Òjò èmí-mímo Olórun náà, tí ó tan ìmólè sí gbogbo ayé pèlú ògo Rè, kò ní wá títí tí a yóò fi ní àwọn tí ó mòye, àwon tí ó mò pèlú ìrírí ohun tí ó túmò sí láti jé òsìsé pèlú Olórun. Nígbà tí a bá rí ìfarasìn tó fi tokàn-tokàn sisé Olúwa, Olórun yóò ròjò èmí-mímó Rẹ̀ láì ní òdiwòn, sùgbón èyí kò ní selè nígbà tí òpò àwon omo ìjo kò bá jé òsìsé Olórun.- Review and Herald, July 21, 1896.IIO 253.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents