Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ọ̀nà Tí ó Tọ́ Láti Lépa

    Kíkọ jálẹ láti pa òfin ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ mọ yóò mú kí àwọn ti ó ń fẹ fi ìdí òfin yìí múlẹ túbọ lágbára síi láti máa pọn àwọn tí ó ní ìtara sí iṣẹ ìsìn lójú. Ẹ má ṣe fún wọn láàyè láti pè ọ ní arúfin. Tí wọn bá jẹ gàba lé àwọn ènìyàn tí kò bẹrù Ọlọrun tàbì ènìyàn, láìpẹ ìjẹgàbá wọn yóò sọ agbára rẹ nù, wọn óò sì wá mọ wípé kò rọrùn láti fipá mú ni láti pa ófin ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ mọ. Tẹ síwájú nínú iṣẹ ìhìnrere pẹlú Bíbélì rẹ ni ọwọ rẹ nígbà náà ni àwọn ọtá yóò mọ wípé àwọn ti pàdánù ìdí tí àwọn fi ń ja. Ènìyàn kò gbà àmìn ẹranko nígbà tí ó bá fihàn wípé òun mọ ọgbọn láti pa àlááfià mọ nípa yíyẹra kúrò nínú àwọn ìwà búburú tí ó sí wà ń ṣe àwọn iṣẹ tó ṣe pàtàki.- Testimonies, Vol. 9, p. 232.IIO 164.1

    Nígbà tí a bá ya ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ fun iṣẹ ìwàásù nígbà náà ni agbára àwọn alátakò tí wọn ń fẹ dójúti àwọn ọmọ Ijọ Onírètí yóò bọ sọnù. Nígbà tí wọn bá ríi wípé a kó ara wa jọ ní ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ láti bẹ àwọn ènìyàn wò tí a sí ń fi ọrọ Ọlọrun kọ wọn, wọn óò sì wà mọ wípé kò tọ fún àwọn láti dá wa lẹkun nípa gbígbé òfin ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ kalẹ.-Testimonies, Vol. 9, pp. 232, 233.IIO 164.2

    A lè lo ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ láti lè ṣe ọpọlọpọ iṣẹ fún Ọlọrun. A lè ṣe ìpàdé ìta-gbangba tàbí ojúlé-dé-ojúlé. Àwọn òǹkọwé lè lo ọjọ yìí láti kọ ìwé wọn. Níbikíbi tí ó bá ti ṣeéṣe ẹ jẹ kí àwọn ìsìn ìjọsìn ó wà ní ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ. Kí á si jẹ kí àwọn ìsìn wọnyí lárinrin. Ẹ kọ àwọn ojúlówó orin ìsọjí kí a sì fi agbára sọ ọrọ ìdánilójú ìfẹ Olùgbàlà. Ẹ sọrọ nípa ìwọn-tunwònsì àti ìrírí ìsìn òtítọ.-Testimonies, Vol. 9, p. 233.IIO 164.3

    Ẹ jẹ kí àwọn olùkọ ilé ìwé wa gbogbo ya ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ sọtọ fún iṣẹ Olúwa. A sọ fún mi pé ní ṣíṣe bẹẹ ni a óò lè fi ṣẹgun èrò àwọn ọtá. Jẹ kí àwọn olùkọ mú àwọn akẹkọọ wọn lọwọ láti lọ bá àwọn tí kò mọ òtítọ sọ ọrọ Ọlọrun. Nípa báyì ni wọn óò ti jẹ ṣe ohun tí ó yẹ kí wọn ṣe.- Testimonies, Vol. 9, -. 233.IIO 164.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents