Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Oògùn tí ó Dájú

    Àtúnṣe tí ó dájú wà fún àwọn tí a bà nínú jẹ́,- ìgbàgbọ́, àdúrà àti iṣẹ́. Ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ yóò fi kún ìdánilójú àti ìtẹ́lọ́rùn wà ní ojoojúmọ́ yóò pọ̀ sí i. Ǹ jẹ́ a dán ọ wò láti gba àníyàn tàbí àì nírètí láàyè? Ní àsìkò tí àwọn ojú dúdú jùlọ, nígbà tí írísí ì fara jọ ohun èèwọ̀, má bẹ̀rù. Ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ó mọ ohun tí o ṣe aláìní. Ó ní gbogbo agbára. Ìfẹ́ àílópin àti àánú RẸ̀ kò ní fìgbà kankan ṣàárẹ̀. Má bẹ̀rù pé kò ní mú ìlérí i RẸ̀ ṣẹ. Ó jẹ́ òtítọ́ ayérayé.Kò ní fi ìgbà kankan yí májẹ̀mú u RẸ̀ tí ó ti ṣe fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ padà. Yóò sì fi iwọn agbára tí wọn nílò láti ṣiṣẹ́ sórí àwọn ìránṣẹ́ ẹ RẸ́ tí wọ́n jẹ́ olóótọ́.- Prophets and Kings, pp. 164, 165.IIO 107.1

    Ohun tí ó jẹ́ ótítọ́ tàbí tí ó jẹ́ àìṣẹ̀tàn wà tí a lè fi ṣe àwòtán ọ̀lẹ ohun ti ẹ̀mí, èyí sì ni iṣẹ́,- ṣiṣẹ́ fún àwọn ọkàn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ ọ RẸ̀.- Testimonies, vol.4, p.236.IIO 107.2

    Èyí ni ìlànà tí Krísti ti ṣàpèjúwe fún àwọn ọlọ́kàn dídákú, oníyèméjì, àwọn tí ọkàn-an wọn ń wárìrì. Jẹ́ kí àwọn oníròbìnújẹ́ tí wọ́n ń rìn pẹ̀lú ìkáánú níwájú Ọlọ́run, dìde kí wọn sì ṣè rànwọ́ fún àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. - Testimonies, vol.6, p.266.IIO 107.3

    Onígbàgbọ́ tí ó ń dàgbà lójoojúmọ́ nínú itara, ìfọkansin, nínú ìgbóná, ní ìfẹ́, - irúfẹ́ àwọn onígbàgbọ́ báyì í kì í fàsẹ́hìn. - Review and Herald, June 7, 1887.IIO 107.4

    Àwọn tì wọ́n ti kópa nínú iṣẹ́ tí kò mọ tara wọn, tí wọ́n ní ìrírí tí kò lera, tí wọ́n sì ń dògbó lọ pẹ̀lú ìjàkadì, iyèméjì, ìkùnsínú, ìdẹ́ṣẹ̀, àti ìrònúpìwàdà, títí tí wọn fi sọ òye ohun tí ó so mọ́ ẹ̀sìn tóòtọ́ nù.Wọ́n mọ̀ lára pé àwọn kò ní lè padà sínú ayé mọ́, fún ìdí èyí wọ́n rọ̀ mọ́ odi síónì,pẹ̀lú owú, ìlara, ìjákulẹ̀ àti àbámọ̀. Wọ́n kún fún wíwá àṣìṣe tí wọ́n sì ní inú dídùn si àwọn àṣìṣe àti àwọn ìṣìnà àwọn ará a wọn.Wọ́n ní àìnírètí, àìnígbàgbọ́,àlàílòórùn ìrírí nínú ìgbé ayé ẹ̀sìn-in wọn.- Review and Herald, Sept. 2. 1890.IIO 107.5

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents