Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Àwọn Ẹ̀kọ Láti Inú Ìrírí Èlíjà

  Láti inú ìrírí Èlíjà ní ayé ọjọ́sí tí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìṣẹ́gun tí ó hàn gbangba, orísirísi ẹ̀kọ́ ni a lè mú jáde, - àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ṣe iyebíye sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní àsìkò yìí, tí ó fi ara hàn bí ó ṣe jẹ́ nípa yíyà kúrò nínú ohun tí ó tọ́.Yiya kuro ninu ẹ̀kọ́ tí a gba tí ó ń borí lónì í jẹ́ ìjọra sí èyi tí ó wà nígbà ayé àwọn wòlíì tí ó tàn ká Ísírẹ́lì. Nínú gbígbéga ti ènìyàn ju ti Ọlọ́run, nínú u yínyin àwọn aṣáájú tí ó lókìkí, nínú u sínsin mámóónì àti nínú u gbígbé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sórí àwọn òtítọ́ ọ ti ìfihàn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lónì í ni wọ́n ń tẹ̀lé òrìṣà a Báálì. Iyèméjì àti àìgbàgbọ́ ni ó ń ṣa ipá a ibi i wọn lórí èrò àti ọkàn, àti pé ọ̀pọ̀ ni wọ́n ń ṣe pàsípààrọ̀ fún ọ̀rọ̀ ìyè ti Ọlọ́run sí ìmọ̀ ọ ti ènìyàn. Ní gbangba ni a ti ń kọ́ àwọn ènìyàn pé a ti dé àkókò ibi tí aó ti gbé èrò ọmọnìyàn ga ju ti ìkọ́ni ọ̀rọ̀ ọ Rẹ̀. Òfin Ọlọ́run, ìdiwọ̀n Ọlọ́run ti òdodo ni wọ́n kéde pé kò ní ìyọrísí. Àwọn ọ̀tá òtítọ́ ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára ìtànjẹ láti mú kí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin gbé àwọn àgbékalẹ̀ ènìyàn síbi tí ó yẹ kí Ọlọ́run wà, kí wọn sì gbàgbé ohun tí wọ́n ti yàn fún ìdùnnú àti ìgbàlà ti aráyé. Síbẹ̀ ìyípadà kúrò nínú ẹ̀kọ́ tí a ti gbà tí ń tàn kálẹ̀ tí ó sì ti wà láti dúró, kì í ṣe ti gbo-gbo-gbò, kì í ṣe gbogbo àgbáyé ní arúfin àti ẹlẹ́ṣẹ̀; kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ti wà ní ìhà ti ọ̀tá. Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹgbẹ̀rún tí kò tí ì fi orúnkún un wọn kúnlẹ̀ fún òrìṣà a Báálì.Ọ̀pọ̀ ni ó ń wọ̀nà láti ní òye kíkún sí i nínú bíbìkítà fún Ọlọ́run àti òfin, ọ̀pọ̀ ni wọ́n nírètí ìdojúkọ ìrètí pé Jésù yóò wá láìpẹ́ láti wá fi òpin sí ìjọba ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àti pé ọ̀pọ̀ ló wà tí wọn ti sin òrìṣà a Báálì láì mọ̀ ṣùgbọ́n pẹ̀lú awọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń bá làkàkà.- Prophets and Kings, pp.170,171.IIO 57.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents