Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Ẹ̀kọ́ Láti Ara Nehinmáyà

    Ní àwon odún tí ó tí kojá séhìn ní mo tí sòrò wípé ó dára láti fi ìpinnu àti ìlànà isé ìránsé wa han àwon òré àti àwon aládùgbò wa tí mo sì tí tóka sí àpeere Nehemiah. Nísisìnyí mo fẹ́ láti rọ àwon arà lókùnrin àti lóbìnrin láti se àkíyèsí ìrírí okùnrin yìí tí ó kún fún èmí àdúrà gbígbà, ìdájó òdodo àti ìgbàgbó tí ó yé kooro enítí ó fi ìgboyà tọ àwon òré rè lọ pèlú oba Ataksari fún ìrànlówó láti lè tẹ̀ síwájú nínú isé Olúwa.-MS, “Consecrated Effort to Reach Unbelievers”, June 5, 1914.IIO 171.3

    Bíbèèrè lówó àwon tí ó le se ìrànlówó: Àwon ènìyàn tí ó lè gbàdúrà gbódò jé àwon ènìyàn tí ó lè sisé. Àwon tí wón ti múrasílè tí wón sí ńfẹ́ yóò rí ònà láti ṣiṣẹ́. Nehemiah kò gbékèlé ohun tí kò dájú. Ó bèèrè àwon ohun tí kò ní lówó àwon tí ó ní.-Southern Watchman, Mar. 15, 1904.IIO 171.4

    Nípase àdúrà ni ìgboyà láti sisé ti ń wá: Nehemiah àti Ataksasi fojú kojú — ọ̀kan jẹ́ erú láti ìran tí kò já mó ohun kóhun nígbàtí ìkéjì jè oba aláyélúwà tí ó ní agbára ní gbogbo àgbayé. Sùgbón ohun tí ó mú ìyàtò nlà wà laarín won ní ìwa rere. Nehemiah tí tèlé àse èyí tí Oba àwon oba fi pèé “Jé kí ó di agbára Mi mú kí ó baà lè bá Mi làjà, yóò sì bá Mi làjà ní tòótó”. Àdúrà kélékélé tí ó gbà sí Olórun òun ní àdúrà kan náà tí ó tí ń gbà fún òpòlopò òsè wípé kí Olórun ó fi àse sí ìbéèrè òun. Ǹjé nísìsinyí tí ó tí ní ìgboyà, tí ó sì tí mò wípé òun ní Òré, Ẹní tí Ó lè ṣe ohun gbogbo tí Ó sí mọ ohun gbogbo wípé Ó ń ṣiṣẹ́ fún òun, ènìyàn Olórun yìí lọ gba àṣẹ láti òdò Oba fún ààyè láti lọ tún Jerusalemu kọ́ kí ó bà tún lè jé ìlú olódi tí ó ní ààbò gégébí ó tí wà télè rí. Esì pàtàkì sí ìlú àti orílè èdè àwon Júù yìí dá lórí ìbéèrè Nehemiah lodo Oba.-Southern Watchman, Mar. 8, 1904.IIO 172.1

    Ídáhùn sí ìbéèrè léèkejì: Gégébí Nehemiah tí rí ìdáhùn gbà sí ìbéèrè, èyí wá fún ní ìgboyà láti béèrè fún ìrànlówó èyí tí ó nílò láti le se ohun tí ó fẹ́ ṣe. Láti bu olá àti láti fún-un ní àse fún èròńgbà rè àti kí ó tún leè rí ààbò tó dájú lórí ìrìn àjò rẹ̀ gbà, béènì oba sì fún-un ní àwon èsó láti sìn-ín lo sí àjò naa. Ó gba lẹ́ta láti òdò oba láti fihàn fún àwon gómìnà àwon ìgbèríko gbogbo títí tí ó fi kojá Efúrété bákannà ní ó tún gba létà lọ sí òdò àwon asógbó oba ní àwon orí òke Lébánónì láti leè yàǹda àwon igi tí ó dára èyi tí yóò lò fún ògiri Jerusalemu àti àwon ìlé tí Nehemiah fẹ́ kó. Kí ó má baà sí àtakò wípé ó tí ń bèèrè fún ohun tí ó pòjù, ìdí nìyí tí Nehemiah se gba àse èyí tí ó tó.-Southern Watchman, Mar. 15, 1904.IIO 172.2

    Létà èyí tí ó gbà lọ sí òdò àwon gómìnà tí ó wà lójú ònà rè yìí fún-un ní àpónlé àti ọ̀wò tí ó ye láti leè rí ìrànlówó tí ó fẹ gbà, bẹ́ẹ̀ sì ní kò sí eni kéni tí ó jé fi owó pa ìdà oba Pásíà lójú láti leè denà rẹ̀ ní ojú ònà rẹ̀ èyí sí mú kí ìrìn àjò Nehemiah ó rorùn kí ó sí ní ìfòkànbalè.-Southern Wachman, Mar. 22, 1904.IIO 172.3

    Ṣiṣe Alábàápàdé Ìdíwọ: Nígbà tí ó dé Jerusalemu pẹlú àwọn èsó ológun tí ó wá pẹlú rẹ èyí fihàn wípé ó ní iṣẹ pàtàkì èyí tí ó wá ṣe, elèyìí sì mú kí owú jíjẹ àti ìkórìíra o wà láàrìn àwọn ọmọ ọtá àwọn ọmọ Isrẹli. Àwọn ẹyà kèfèrí tí wọn wà ni àgbègbè Jerusalemu ti kókó ń fi ọtá hàn sí àwọn Júù nípa kíkàn wọn lábùkù ní ọnà tí ó yé wọn. Àwọn olóyè ẹyà wọnyìí tí wọn sí jẹ olórí nínú àwọn iṣẹ ibi wọnyìí ni Sambalati ara Hórónì, Tobia ara Àmónì ati Geremu ara Arábíà; àti láti àkoko yìí ni àwọn olórí wọnyi ti ń fi ẹmí ìjowú ṣọ ìrìn ẹsẹ Nehemiah, tí wọn sì ń sá gbogbo ipá wọn láti má jẹẹ kí Nehemiah ó ṣe àṣeyọrí.-Southern Watchman, Mar. 22, 1904.IIO 173.1

    Nípa gbíngbín ẹmí ẹrù àti àìgbàgbọ sínú ọkàn àwọn òṣiṣẹ, wọn bẹrẹ sí ní mú ìyapa wá sí àárín wọn kí wọn má báà ṣe àṣeyege.-Southern Watchman, Mar. 22, 1904.IIO 173.2

    Wọn gbìyànjú láti mú kí ìyapa ó wà láàrín àwọn òṣìṣẹ́ nípa fífi èrù àti ẹ̀mí àìgbàgbọ́ sínú ọkàn wọn, kí wọn má baá ṣe àṣeyọr´. Gbogbo akitiyan àwọn òṣìṣẹ́ wọnyìí ni wọn fí ń ṣe ẹlẹ́yà tí wọ́n sì ń sọ wípé wọn kò lè ṣè àṣeyọri, tí wọn sì ń sọ wípé òfo ọjọ keejì ọjà ni wọn ń ṣe. Àtakò tí ó gbóná janjan ni wọn ń gbé ko ojú àwọn ọ̀mọ̀lé wọnyìí. Nígbà tí ó yá ni àwọn tí ń mọ odi bá kúkú dé fìlà máwobẹ̀ sí gbogbo àwọn akitiyan àwọn ọtá wọnyí. Àwọn àṣòjú àwọn ọ̀tá wọ̀nyí gbìyànjú láti mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn òṣìṣẹ́ wọnyí nípa sísọ ohun tí wọn kò ṣe fún àwọn ènìyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìditẹ̀ mọ́ni ni wọn ṣe láti ṣí Nehemiah lọ́wọ́ iṣẹ́, bẹ́ẹ́ sì nì àwọn kan nínú àwọn ọmọ Júù ti gbà wọn gbọ́ tí wọn sì ṣetán láti ṣí wọn lọ́wọ́ iṣẹ́. Àwọn aṣojú àwọn ọ̀tá wọnyí tí wọn jẹ́ àfojú fẹ́ni má fọkàn fẹ́ni wọnyí darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá láti yí ìlànà iṣé tí wọn ń ṣe padà.-Southern Watchman, Apr. 12, 1904.IIO 173.3

    Irú Ìṣòro Báyìí Sì Ń Kojú Àwọn Adari Lónìí: Irú ìrírí Nehemiah yìí ṣí ń dojúkọ àwọn ọmọ Ọlọ́run ní irú àkokò yìí. Àwọn òṣìsẹ́ Ọlọrun yìí yóò mọ wípé àwọn kò leè ṣe iṣẹ́ náà làirí ìbínú àwọn alátakò wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Ọlọrun ni ó pè wọn sínú iọẹ́ yìí, síbè kò sí ìgbà tí wọn kò ní dojúkọ ẹ̀gàn àti àbùkù. À óò si máa pè wọn ní orúkọ búburú lóríṣirìṣi èyí tí ó bá ìfẹ́ ọkàn àwọn ọ̀tá wọn mú gẹ́gẹ́bí aláìṣeégbẹ́kẹlèé, elérò búbúrú, alágàbàgebè àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Wọn óò sì màa sàfihàn àwọn ohun tí ó mọ julọ ní ọ̀nà èyí tí yóò fi bá ìfẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́ mu. Ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn díẹ̀ èyí tí ó dàpọ̀ mọ ọ̀rọ̀ àìlọ́gbọ́n, àìbọ̀wọ̀ fún àti ìkórìíra ti tó láti mú inú àwọn ẹlẹ́gàn àti eléfè dùn. Àwọn ẹlégàn wọnyí á sì máa elégbè lẹ́hìn ara wọn nínú ohun tí kìí ṣe òtítọ, wọn óò sì fùn ara wọn ní móríyá nínú ṣíṣe iṣẹ́ òdì wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn á máa mú ìrora bá ọkàn ènìyàn ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó ba jẹ́ olótìítọ́ sí Ọlọrún ni ó gbọ́dọ̀ faradà àwọn ńkan wọnyí nítorí tí ó jẹ àgbékalẹ̀ Sátánì làti ṣí ọkàn àwọn ènìyàn kúrò nínú iṣẹ́ Ọlọrun àti pè wọn sí.-Southern Watchman, Apr. 12, 1904.IIO 174.1

    Fífún Àwọn Ọkàn Tí Kò Lókun Làgbára: Ní ìdákẹ́jé àti bòńkẹ́lẹ́, Nehemiah parí iṣẹ́ odi mímọ. Ó sọ wípé, “Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí ohun tí mo ṣe bẹ́ẹ̀ni mi ò tilẹ̀ tíì sọ́ fún àwọn Júù tàbí àwọn àlúfà, àwọn ọlọ́lá, àwọn olórí tàbí fún gbogbo àwọn tí ó ṣiṣẹ́ náà”. Nínú ṣíṣe àyẹ̀wò yìí kò fẹ́ pe àkíyèsí ẹnikẹ́ni èyí tí ó lè mù kí inú wọn ó dùn tayo débi wípé àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ròyìn káàkiri èyí tí ó sì lè típasẹ̀ bẹ́ẹ̀ mú ìdíwọ tàbí ìkùnà bá ìlàná rẹ̀. Nehemiah fi òru tókù gbàdúrà wípé kí agbára tí ó tó ó wà láti fi mú ìṣọ̀kan bá àwọn ènìyàn rè tí wọn kò lókun mọ́.- Southern Watchman, Mar. 22, 1904.IIO 174.2

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Nehemiah ní àṣẹ ọba èyí tí ó rọ àwọn ènìyàn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún àṣeyọrí iṣé yìí, síbẹ̀ ó yàn láti máa gbẹ́kẹ̀lé àṣẹ ọba nìkan, ṣùgbọ́n ó gbìyànjú láti gbé ìgbésẹ̀ èyí tí yóò jẹ́ kí ó rí àánú àti ìgboyà áwọn ènìyàn gbà nítorí ó mọ wípé ìṣọ̀kan ọkàn àti ọwọ̀ ni ó ṣe pàtàkì jùlọ láti ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ tí ó fẹ́ ṣe.IIO 174.3

    Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ tí ó sii pe àwọn ènìyàn jọ, ò ṣe àgbékalẹ́ rẹ̀ níwájú wọn ní ọ̀nà èyí tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú wọn. Lẹ́hìn tí ó ti fi yé wọn wípé òun ní àtìlẹhìn àṣẹ ọba Persia àti ti Ọlọrun Isreli, ó wá béèrè lọwọ wọn bóyá wọn óò lo àǹfàní náà láti mọ odi yìí. Wọn gba àrọwà yíì lẹ́hìn ìgbà tí wọn ti mọ wípé àwọn ti rí ìfarahàn ojú rere Ọlọrun, èyí tí ó dójú tì àwọn èrù wọn, pẹ̀lú ọhún wípé, “Ẹ jẹ kí á dìde kí á sì mọ odi náà.-“Southern Watchman, Mar. 29, 1904.IIO 174.4

    Okun àti ìrètí ńlá Nehemiah yìí ni ó gbé àwọn ènìyàn wọ̀. Bí irú ẹ̀mí Nehemiah yìí sì ti bà lé wọn, wọn dìde pẹ̀lú ọkàn kannáà tí ó wà nínú olórí wọn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá dàbí Nehemiah, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí ní ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà.-Southern Watchman, Mar. 29, 1904.IIO 174.5

    Àwọn Àlúfà Ísírẹ́lì Ni Àwọn Àkókó Tó Dáhùn: Lára àwọn tì irú ẹ̀mí Nehemiah kọ́kọ́ bà lé ni àwọn àlúfà. Nínú ipò tí wọn wà, wọn mọ̀ wípé àwọn lè mú ìkùnà tàbí ìtẹsíwájú bá iṣẹ́ yìí. Ìfọwọ́sowọ́pọ́ wọn sì mú àṣeyọrí gidi bá iṣẹ́ náà. Báyìí ni ó sì yẹ kí ó máa rí nínú gbogbo àdáwọ́lé. Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ nínú ìjọ Ọlọrun tí wọn sì ní ipa lórí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa wà níwájú níbi tí wọn bá ti ń ṣìṣẹ́. Tí wọn bá fà sẹ́hìn, àwọn tó kù náà yóò kúkú padà ní. Ṣùgbọ́n ìtara wọn yóò pe ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ níjà bẹ́è sì ni ìmọ́lẹ̀ wọn yóò ran ẹgbẹlẹgbe.-Southern Watchman, Apr. 5, 1904.IIO 175.1

    Nehemiah Gẹgebii Oluṣeto: Gbogbo àwọn ènìyàn ni wọn kún fún ọkán áti ẹ̀mí ìṣọ̀kan fún iṣẹ́ ṣíṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn tí wọn ní ipá àti agbára sì ṣe ètò àwọn ènìyàn sí onírúurú ẹgbẹ́ tí àwọn olórí kọ̀ọ̀kan sì ń ṣíwájú láti mọ abala odi èyí tí wọn fún wọn. Èyí jẹ́ ohun tí ó dùn mọ Ọlorun áti àwọn angeli láti rí irú àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn fi tọkàntara pẹ̀lú ìrẹ́pọ̀ ṣiṣé lórí odi Jerusalemu tí ó wó lulẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ohun ayọ̀ ni ó jẹ́ láti máa gbọ́ ìrú àwọn ohun èlò àwọn òṣìṣẹ́ wọnyí láti òwúrọ kùtùkùtù títí di àṣálẹ nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá yọ.-Southern Watchman, Apr. 5, 1904.IIO 175.2

    Ṣiṣe Àfihàn Jíjẹ Àṣíwájú Tòótó: Ìtara àti okùn òun agbára Nehemiah kò fìgbà kan dúró pàápàá jùlọ ní àkókò tí iṣẹ́ yìí bẹ̀rẹ̀. Kò káwọ́ gbera ṣùgbọn pẹ́lú àmójútó tó péye, ni ó ń darí àwọn óṣìṣẹ́, tí ó ń kíyèsí àwọn ohun ìdènà tí ó sì ń pèsè ọ̀ná àbáyọ tí ó tọ́. Ipa rẹ̀ lórí wọn sì kan gbogbo ènìyàn ní ibi gbogbo. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìmóríyá ní ó ń fún àwọn tí ń bẹ̀rù ní ìgboyà, ni ó ń gbé òṣùbà fún áwọn tó ń ṣiṣẹ́ takuntakun tí ó sì ń ta àwọn afà bí ìgbín jí. Bákannáà ni ó sì ń fojú apákan sọ àwọn ọ̀tá tí wọn ń fẹ́ fi ọ̀rọ̀ kòbákùngbé dí àwọn òṣiṣẹ́ lọ́wọ́ láti sí ọkàn wọn kúrò nínú iṣẹ́ àjọṣe náà.IIO 176.1

    Bí ojú gbogbo ṣe ń wo Nehemiah tí wọn sí ṣetán àti tẹ̀lé àṣẹ rẹ, bẹ́ẹ̀ni ọkán Nehemiah pàápàá wà lọ́dọ Ọlọrun tí Ó jẹ́ Alámòjútó Àgbà fún iṣẹ́ náà. Ẹni tí Ó sì fi si ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti mọ odi náà. Gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ tí dàpọ mọ agbára nínú ọkàn rẹ̀, Nehemiah kígbe tí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ń ró kogókogó létí àwọn òṣìṣẹ́ wípé “Olọrun yóò bùkún wa” sì ń mú ọkàn àwọn òṣìṣẹ́ wọnyí yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.-Southern Watchman, Apr. 5, 1904.IIO 176.2

    Nehemiah àti àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rè kò fà sẹ́hìn nígbà ìniran àti ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ní wọn kò fì ìgbà kankan bọ aṣọ wọn sílẹ tàbí dẹ́kun àti ṣíṣẹ́ bóyá lọ́sàn-án tàbí lóru. “Nítorí náà bóyá èmi ni tàbí àwọn aráà mi tàbí áwọn ọmọ iṣéẹ̀ mi tàbí àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọn tẹ̀léè mi wá, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bọ́ aṣọ wa sílẹ̀ bíkòṣe ìgbà tí a fẹ́ fọ̀ wọn.-“Southern Watchman, Apr. 26, 1904.IIO 176.3

    Títako Ipa Inú Ẹsìn Gbogbo: Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ àwọn olórí àti ọlọ́lá ilẹ́ Isrẹli ni wẹn fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ṣe iṣẹ ẹ wọn ṣùgbọn àwọn diẹ kán wà, àwọn ọlọ́lá Tékóì tí wọn kò fi tọkàntara ṣe iṣẹ́ Olúwa náà. Bí a ṣe dárúkọ àwọn tó fi òtítọ́ ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ipò ọlá bẹ́ẹ̀ní a sì fi ìtìjú wo àwọn ọ̀lẹ òṣìṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ìkìlọ̀ fún àwọn tí ọjọ́ ọ̀la.IIO 176.4

    Nínú gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan ni ati máa ń rí àwọn tí wọn kò leè ṣé wípé iṣẹ́ náà kìí ṣé tí Olúwa sùgbọ́n síbẹ̀ tí wọn yóò sì tún ta kété tí wọn kò sì ní sa ipa kankan láti mú iṣẹ́ náà tẹ̀síwájú. Ṣùgbọ́n nínú ìgbìyànjú láti fi ìmọ ti ara ẹni nikan hàn, àwọn ènìyàn wọnyí ni wọn máa ń sáábà jẹ́ òṣìṣẹ́ tí ó lágbára jùlọ. Ó dára láti rán wa léti wípé Ọlọrun ní ìwé àkọsílẹ̀ ní ọ̀run èyí tí a ń kọ èrò àti iṣe wa sí, ìwé tí a kò sì ṣe àṣìṣe tàbí àsìko èyí tó sì jẹ wípé láti inú ìwé náà ni a óó ti dá wa lẹ́jọ́. Níbẹ̀ gbogbo awọn àǹfàní tí a ní láti ṣiṣẹ́ fún Ọlọrun síbẹ̀ tí a kò ṣé ni a óò fi òtítọ́ kọ sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo iṣẹ́ ìgbàgbọ́ wa àti ìfẹ́ bóṣe wù kí ó kéré tó ni yóò wà nínú ìrántí ayérayé.- Southern Warchman, Apr. 5, 1904.IIO 177.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents