Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ó Yẹ Kí Àwọn Ọmọ Ó Jẹ́ Alábàápín Àjàgà Ti Ara Àti Ti Ẹ̀mí

    Gbogbo wa ni a lèè ṣe ohun kan. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá fẹ́ ṣe àwáwí ni a ò maa sọ wí pé, “Iṣẹ́ ilé mi, àwọn ọmọ mi ń gba àkókò mi àti ọ̀nà mi”. Ẹ̀yin òbí, ó yẹ kí àwọn ọmọ yín ó jẹ́ olùgbọ̀wọ̀ọ́ yín, tí yóò máa mú okun àti agbára láti ṣiṣé fún Ọ̀gá Àgbà. Àwọn ọmọ ni ọmọ ìdílé Ọlọ́run tí ó kéré júlọ. Ó yẹ kí a tọ́ wọn láti ya ara sí mímọ́ fún Ọlọ́run Ẹni tí ó jẹ́ Ẹlẹ́dàá àti Olùrapadà wọn. Ó yẹ kí a kọ́ wọn wí pé gbogbo ara wọn jẹ́ ti Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ kọ́ wọn láti kópa nínú gbogbo iṣẹ́ ìsìn tí kò ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni nìkan. Ẹ máà ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ yìí jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ alábàápín àjàgà ti ara àti ẹ̀mi pẹ̀lú yín. Nípa ríran àwọn elòmíràn lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ni ìdùnnú àti ìwúlò ti wọn náà yóò máa pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ.-Testimonies, Vol. 7, p. 63.IIO 207.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents