Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ẹ̀KỌ́ KẸTÀLÉLÓGÚN ÀWỌN Ọ̀NÀ ORÍṢIRÍṢI ÌHÌNRERE

    Ṣíṣe Àkíyèsí Àwọn Afọ́jú

    Ọlọ́run rán àwọn ańgẹ́lì Rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ ìrańṣẹ́ fún àwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ afọ́jú. Àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run ni wọ́n tọ́ ìṣísẹ̀ wọn tí wọ́n sì ń pa wọn mọ́ kúrò nínú ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ewu tí wọn kò mọ̀ tí ó wà ní ọ̀nà wọn.-Testimonies, Vol. 3, p. 516.IIO 215.1

    Ọlọ́run kò ní gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ̀ nígbà tí wọ́n kò bá bìkítà fún àwọn àfọ́jú àti àwọn aláìsàn àárín wọn.-Testimonies, Vol. 3, p. 518.IIO 215.2

    Tí a bá rí àwọn tí ó bá fẹ́ jẹ́ ohun ìdènà fún àwọn afọ́jú, ó yẹ kí a ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ sí àwọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ nítorí Ọlọ́run ti fi wá ṣe olùṣọ́ fún àwọn afọ́jú, àwọn tí a ń pọ́n lójú, àwọn opó àti àwọn ọmọ aláìní baba. Òkúta ìdènà tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò túmọ̀ sí òkùta lásán èyí tí a yí sí ọ̀nà àwọn afọ́jú láti lè mú wọn ṣubú, ṣùgbọ́n ìtúmọ̀ rẹ̀ pọ̀ ju báyìí lọ, ó túmọ̀ si ohunkóhun tí a lè ṣe láti bà wọ́n nínú jẹ́, tàbí ṣiṣẹ́ lòdì sí ìfẹ́ wọn tàbí tako ọ̀rọ̀ tàbí àṣeyọrí wọn.-Testimonies, Vol. 3, p. 519.IIO 215.3

    Àwọn afọ́jú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdènà ní ọ̀nà wọn nítorí ipò ìfọ́jú tí wọ́n wà. Ọkàn àwọn tí wọn kò káanú tàbí kẹ́dùn bí àwọn afọ́jú ṣe ń fọwọ́ wá ọ̀nà kiri ní ojú ọ̀na wọn nínú ayé tí kò ba wọn ṣọ̀rẹ́ yìí, ní láti jẹ́ ọ̀dájú, pẹ̀lu oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wọ́n nílò f’ọ́wọ tọ́.IIO 215.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents