Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Àfiwé Tí Ó Lágbára

  Ìtara ti ifẹ́ ọ̀run ni irúsókè rẹ̀ ti kọjá ohun tí a lè fojú díwọ̀n-an fún ànfààní àwọn ènìyàn. Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn ańgẹ́lì láti rí i pé àwọn tí ó jẹ àǹfààní ìfẹ́ ń lá yìí fi ìmoore ojú lásán hàn. Ẹnu ya àwọn ańgẹ́lì sí ìdúpẹ́ tí kò jinlẹ̀ tí ènìyàn ṣe ní ti ìfẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀run ń dúró pẹ̀lú ìbínú sí ti àìkíyèsí tí ó hàn sí àwọn ọkàn ènìyàn ṣe ní ìfẹ́ Ọlọ́run tó. Báwo ni a mọ̀ bí Krístì ṣe bùyìn fún tó? Báwo ni ìyá àti bàbá yóò ṣe ní ìmọ̀lára, ǹ jẹ́ wọ́n mọ̀ pé ọmọ wọn, sọnù sínú òtútù àti inú u yìnyín, tí wọ́n sì kọjá níbẹ̀, tí wọ́n fi sílẹ̀ láti ṣègbé, nípa àwọn tí ó yẹ kí wọn gbà á là? ṣé wọn kò ní banújẹ́, bínú burúkú? Ṣé wọn kò ní bá àwọn apànìyàn náà wí pẹ̀lú ìbínú gbígbóná bí omijé e wọn kíkankíkan sí ìfẹ́ ẹ wọn? Àwọn ìrora tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ní àwọn ìrora tí ọmọ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò bá na ọwọ́ ìrànlọ́wọ́ sí àwọn ará a wọn tí ó ń ṣègbé ń mú òdodo RẸ̀ bínú.- The Desire of Ages, p.825.IIO 92.2

  Mo ti kà nípa ọkúnrin kan tí, ó ńrìn ìrìn àjò ní ìgbà òtútù sí ìhà ibi tí ó jìn, nínú u yìnyín, tí ó si ti di aláìmọ ìrora nípa òtútù, èyí tí ó sì fẹ́rẹ̀ láìmọ̀ jí agbára ìwà láàyè e rẹ̀ lọ. Ó sì fẹ́rẹ̀ gbọ̀n kú nípa ìgbàmọ́ra ọba òtútù nini, tí ó sì fẹ́rẹ̀ ẹ kú, ó gbọ́ ìkérora ti ọkùnrin arìnrìnàjò, tí ó ń ṣègbé pẹ̀lú otútù bí ó ti ń ṣègbé e lọ. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbé e dìde láti gbà á là. Ó fi ọwọ́ ra n ǹkan án gbóná tí ọkuǹrin tí kò lóríire yìí àti lẹ́yìn ìgbìyànjú, ó gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀, bí kò sì ti le dìde, ó gbé sí apá ìbánidárò o rẹ̀ nípasẹ̀ èrò tí ó rò pé òun kò lè ṣe àṣeyọrí ní òun nìkan. Nígbà tí ó sì ti ru ẹrù arìnrìnàjò ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ dé ibi àìléwu, òtítọ́ yìí sọ sí i lọ́kàn pé ní gbígba aládùgbó ò rẹ̀ là ó ti gba ara a rẹ̀ là bákan náà. Ìtara ìgbìyànju láti gba ẹnìkejì là ni ó jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú àwọn iṣan ara a rẹ̀,tí ó ti ń dì yọ́ láti jẹ́ kí ìgbooru àlááfìa àti ìdènà otútù ní àwọn òpin ara. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí ni a gbọdọ̀ kàn nípá fún àwọn ọ̀dọ́ onígbàgbọ́ láti ìgbà dé ìgbà, kì í ṣe nípa àṣẹ, ṣùgbọ́n nípa àpẹẹrẹ, pé nínú ìrírí ìgbàgbọ́ ọ wọn lè mọ àyọrísí tí ó jọra.- Testimonies, vol.4, pp.319,320.IIO 93.1

  O kò lè dá wà ní ìwọ nìkan, kí o sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nítorí pé a ti bùkún ọ pẹ̀lú ìmọ̀ òtítọ́. Tani ó mú òtítọ́ yìí wá fún ọ? Tani ó fi ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn fún ọ? Ọlọ́run kò fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ ẹ RẸ̀ láti gbé pamọ́. Mo ti kà nípa ìrìn- àjò tí wọ́n rìn láti wá ọ̀gbẹ́ni Jòánù Franklin. Àwọn ọkùnrin tí ó gbóyà fi ilé e wọn sílẹ̀ wọ́n sì ń rìn kiri ní àwọn òkun ti ìhà àríwá, ǹ jìyà ìdáwà làwọn nìkan, ebi, òtútù, àti ìpọ́njú. Àti kíni gbogbo o rẹ̀ wà fuń?- Ó wà sáá lásán fún iyì i ṣíṣe àwárí àwọn ara òkú tí àwọn aláwárí, tàbí, tí ó bá ṣe é ṣe, láti yọ àwọn ẹgbẹ́ díẹ̀ kúrò nínú ikú burúkú tí ó gbọdọ̀ wá sí orí i wọn, àyàfi tí ìrànlọ́wọ́ bá dé ọ̀dọ̀ ọ wọn lásìkò. Tí wọ́n bá le gba ẹnìkan là kúrò nínú ègbé, wọ́n yóò ka wàhálà a wọn bí ohun tó lérè tóyẹ. Èyí ni wọ́n ṣe pẹ̀lú ìfijì i gbogbo ìtùnú àti ìdùnnú u wọn.IIO 93.2

  Ronú lórí èyí, kí o sì ro bí ó ṣe kéré tó bí a ṣe ń fẹ́ láti ṣè rúbọ fún ìgbàlà àwọn ọkàn tí ó ṣọ̀wọ́n ní àyíká a wa. A kò fi agbára mú wa láti lọ kúrò nínú ilé, lójú ọ̀nà tí ó jìn tí ó sì dáni lágara, láti gba ẹ̀mí ẹni kíkú là. Ní ẹnu ọ̀nà ilé e wa, gbogbo o rẹ̀ nípa wa, ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn ọkàn wà tí a lè gbàlà, àwọn ọkàn tó ti ń ṣègbe, - IIO 93.3

  Àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin ń kú láì nírètí, láì lọ́lọ́run, -síbẹ̀ à dúró ní ìdúró kòkànwá, tí a sì ń sọ pẹ̀lú ìse e wa, tí kò bá jẹ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ ọ wa. “Èmí jẹ́ olùtọ́jú arákùnrin-ìn mi bí.”? Àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ ẹ̀mí i wọn nù nípa ìgbìyànjú láti gba ẹlòmíràn là jẹ́ ìyìn nípasẹ̀ àgbáyé bí àwọn akọni àti àwọn tí a pa nítorí ìgbàgbọ́ ọ wọn. Báwo ni àwa tí à ń wo iwájú u wa fún ìyè ayérayé ní ìmọ̀lára tí a kò bá lè ṣe ìfara ẹni rúbọ díẹ̀ tí Ọlọ́run ń fẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ wa, fún ìgbàlà fún ìgbàlà ọkàn àwọn ènìyàn? - Review and Herald, Aug.14, 1888.IIO 93.4

  Ní ìlú kan ní ìlú England titun, kànga kan wà tí a gbẹ́. Nígbà tí iṣẹ́ náà fẹ́rẹ̀ parí, tí ọkùnrin kàn sì wà nísàlẹ̀, ilẹ̀ lanu ó sì bo ọkùnrin yìí mọ́lẹ̀. Lọ́gán igbe ewu ta, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ, àwọn àgbẹ̀, àwọn oníṣòwò, àwọn agbẹjọ́rò, sáré wàràwàrà láì lẹ́mì í láti gba ọkùnrin yìí là. Àwọn òkun, àwọn atẹ́gùn, àwọn ọkọ́ ìbulẹ̀, àti àwọn ọkọ́ ni wọ́n múwá pẹ̀lú ìtara, àwọn ọwọ́ ìfẹ́. Gbà á là; Gbà á là! Ni igbe tí wọ́n ń ké.IIO 94.1

  Àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lu agbára àìnírètí, títí tí òógùn dúró bí ìlẹ̀kẹ̀ nínú ojú u wọn tí ó ń gbọ̀n rìrì pẹ̀lú ìlo agbára. Ní gígun òpó kan ni a gùn sísàlẹ̀, ní èyi tí wọ́n kígbe sí arákùnrin náà láti dáhùn tí ó bá sì wà láàyè. Ìdáhùn náà wá, “Ààyè, ṣùgbọ́n ẹ ṣe kíákíá. Ìbẹ̀rù wà níhìn-ín.” Pẹ̀lú igbe ayọ̀, wọ́n tún ìgbìyànjú u wọn ṣe, ní ‘kẹhìn wọ́n dé ibi tí ó wà, wọ́n sì gbà á là, ayọ̀ tí ó gòkè fẹ́rẹ̀ wọ inú àwọn ọ̀run lọ. “Ó ti rí ìgbàlà!” ni wọ́n ń ké ní òpópónà àti nínú ìlú.IIO 94.2

  Ṣé eléyìí jẹ́ bí ìtara ń lá àti ìfẹ́ ọkàn an wọn, ìgbóná ọkàn ń lá láti gba ẹnìkan là? Dájú dájú kò rí bẹ́ẹ̀ ; kíni sísọ ìgbé ayé tí ó wà fún ìgbà díẹ̀ nínú fífiwé pẹ̀lú kí a sọ ẹ̀mí nù? Tí ìdẹ́rùbà a sísọ ẹ̀mí kan nù yóò bá dìde nínú àwọn ọkàn ènìyàn ìmọ̀lára tí ó jẹ́ kíákíá, kò gbọdọ̀ mú kí sísọ ẹ̀mí nù dìde pàá pàá jinlẹ̀ nínú àníyàn àwọn ènìyàn tí wọ́n gbà láti mọ òye níti àwọn wọ̀nyí yàtọ̀ sí krístì? Ṣé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò ní fi ìtara ń lá hàn nínú ṣí ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ọkàn bí a ṣe ṣàfihàn nínú ayé ọkùnrin náà tí wọ́n sin sínú u kànga?- Gospel Workers, pp.31, 32.IIO 94.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents