Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ÀJÀKÁLẸ̀ IBI

    À ń gbé láarin “àjàkálẹ̀ ibi” níbi tí a ò ti lérò, ènìyàn tí ó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run n wo tìyanu tìyanu Ìwà ìbàjẹ́ ń borí, ó kọjá agbára tí ènìyàn lè fi gègé ṣ’àkàwé. Ojoojúmọ́ ṣe àfihàn tuntun ti ìjà òṣèlú, àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àti ayédèrú. Ojoojúmọ́ ń mú àárẹ̀ ọkàn an rẹ̀ wá, àkọsílẹ̀ ìwà ibi àti àìlófin, ti onírúurú sí ìrora ẹ̀dá, ti rírorò, ti èṣù ọ̀tá tó ń wá ìparun ẹ̀mí ènìyàn.Ojoojúmọ́ ń jẹ́rìí sí lílé sí ti ìwà a wèrè, ìpànìyàn, àti pípokùn so. Tani yóò ṣiyèméji pé àwọn aṣojú èṣù ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ láarin àwa ọmọ ènìyàn nípa pípọ̀si iṣẹ́ láti daàmú àti láti ba ọkàn jẹ́, àti láti sọ ọ́ di àìmọ́ àti kí ó pa ara run?- Ministry of Healing, pp.142,143.IIO 53.2

    Ẹ̀mí rúdurùdu ń wo gbogbo orílẹ̀ èdè, àti awọn iṣẹlẹ atigba-de- igba ti o n ṣokun fa a ìpayà ti ilé ayé jẹ́ àpẹẹrẹ ti iná àjórun ti ìfẹkufẹ àti ìsòdì sí òfin nínú èyí tí a ti fi ìgbà kan sá àsálà yóò fi ìpọ́njú àti ìsọdahoro kún inú ayé.Àfiwe eyi ti ìṣípayá ṣe nípa awọn ti o gbe ni asiko ìkún omi,ni afijọ pẹlu ipò tí ayé wa nìsinsinyìí. Bákan náà, ní àsìkò o wa yìí,àti ní ilẹ̀ àwọn tí ó ń pe ara a wọn ní, onígbàgbọ́, ìwà ibi ń pọ sii lójoojúmọ́, o dúdú ó sì burú bí i èyí tí ó mú ayé ẹ́ṣẹ̀ ìgbà a nì parun. Kí ìkún omi tó dé, Ọlọ́run rán Nóàh láti kìlọ̀ fún aráyé, kí ayé ba à lè wá sí ìrònú pìwàdà, kí wọn sì lè bọ́ kúrò nínú ìparun tí ó bani lẹ́rù.Bí bíbọ̀ wá Krístì lẹ́ẹ̀kejì ṣe ń súnmọ́ etílé, Olúwa rán àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú ìkìlọ̀ sí aráyé láti gbáradì fún ìṣẹ̀lẹ̀ ń lá náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń gbé nínú títàpá sí òfin Ọlọ́run àti nísinsinyìí ní àánú, Ó ń pè wọ́n láti ṣè’gbọràn sí àwọn òfin mímọ́. Gbogbo àwọn tí ó máa gbé ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn tì sápá kan nípa ríronú pìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Krístì, ni a fún ní ìdáríjì.- Patiachs and Prophets, p.102.IIO 53.3

    Ipò tí àwọn n ǹkan inú ayé wá fihàn pé ìgbà ewu ti súnmọ́ tòsí i wa, Àwọn ìwé ojoojúmọ́ kún fún ìkọlù tí ó bani lẹ́rù ní ọjọ́ iwájú.Ìlọ́nilọ́wọ́gbà pẹ̀lú ìgboyà jẹ́ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ìwà ipá jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀. Olè jíjà àti ìpànìyàn ni ó ń ṣelẹ̀ lemọ́ lemọ́. Àwọn ènìyàn tí ẹ̀mí èṣù ń bá lò tàbí tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù ń gba ẹ̀mí ọmọ ènìyàn l’ọ́kùnrin, l’óbìnrin, àti àwọn ọmọ kékèké.Àwọn ènìyàn ti di ẹni tí a ra níyè pẹ̀lú ẹ̀tàn, àti gbogbo oríṣiríṣi ìwà ibi sì ń borí.- Testimonies, vol.9, p.11.IIO 54.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents