Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ọ̀nà Bí Ọ̀run Ti Ń Ṣẹ Àkọsílẹ̀

    Gbogbo iṣẹ́ rere tí à ń ṣe láyé ni àwọn ángẹ́lì ń fi òtítọ́ inú kọ ọ́ sílẹ̀.-Testimonies, Vol. 1, p. 198.IIO 222.1

    Gbogbo iṣẹ̀ ìfẹ́, ọ̀rọ̀ rere, àdúrà fún àwọn tí ń jìyà tí a ń pọ́n lójú ni a ń kọ sílẹ̀ níwájú ìtẹ́ ayérayé tí a sì fí ń pamọ́ sínú àkọsílẹ̀ tí kò leè parun.-Testimonies, Vol. 5, p. 133.IIO 222.2

    Gbogbo ìròyìn àṣeyọrí wa nípa tún tú iṣẹ́ òkùnkùn ká àti títan ìmọ̀ Kírísítì sí òkèèrè ni a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀run. Bí a ṣe ń sọ àwọn ìwà rere yìí níwájú Bàbá bẹ́ẹ̀ni ayọ̀ ń kún inú gbogbo àwọn ogun ọ̀run.-The Acts of the Apostles, p. 154.IIO 222.3

    Àwọn ángẹ́lì ní a gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àwọn olùránlọ́wọ̀ wa. Wọ́n rí àwọn àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ọmọ ènìyàn lọ́ sí ọ̀run nígbà gbogbo.-Southern Watchman, April 2. 1903.IIO 222.4

    Ìbá dára láti rántí àwọn àkọsílẹ̀ ní ọ̀run wí pé láti inú ìwé tí a kọ sílẹ̀ láìsí àṣìṣe ni a ó ti dá wa lẹ́jọ́. Gbogbo ànfààní tí a ní láti ṣiṣẹ́ Ọlọ́run tí a fi ojú parẹ́ ni a kọ sílẹ̀ àti nínú ìwé ìrántí ni a ń ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo iṣẹ́ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́.-Prophets and Kings, p. 639.IIO 222.5

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents