Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìṣẹ́gun Ti Òtítọ́

    Iyèméjì nínú Ọlọrun le mú kí àwọn ènìyàn ó máa fì ọrọ Rẹ ṣe ẹlẹyà, ẹfẹ tàbí kí wọn tilẹ sẹẹ. Ẹmí ìfẹ ayé le sọ ọpọlọpọ di aláìmọ àti wípé ní ṣíṣe takuntakun lái sàárè nìkan ló lè mú kí ọrọ Ọlọrun ó dúró níkẹhìn òtítọ náà ni yóò borí.-Prophets and Kings, p. 186.IIO 164.5

    Ní òpin iṣẹ Ọlọrun láyé ni a óò tún gbé òfin Ọlọrun sókè. Bí ó tilẹ jẹ wípé ìsìn èkè lè máa borí báyìí, kí ẹṣẹ ó sì di púpọ, ìfẹ àwọn ènìyàn si lè di tútù, kí àwọn ènìyàn sì sọ àfojúsùn wọn nípa ọnà Kalfari nù, òkùnkùn sì lè bo ayé mọlẹ, kí gbogbo ènìyàn sì tàpá sí òtítọ oríṣiríṣi ète ni àwọn ènìyàn lè máa hun láti borí àwọn ènìyàn Ọlọrun; ṣùgbọn ní àsìkò ewù ńlá, Ọlọrun Èlíjà yóò gbé àwọn ènìyàn dìde láti fọn ìpè iranṣẹ tí ìhìnrere tí kò ṣéé pa lẹnu mọ. Ní ibi tí ọpọlọpọ ènìyàn wà lórí ilè ayé àti ní ibi gbogbo tí àwọn ènìyàn ti lo láti sọrọ òdì sí Ọlọrun Ọgá Ogo ni ohùn ìbániwí tí ó lágbára yóò ti jáde pẹlú ìgboyà ni àwọn ènìyàn yóò máa kọ láti tẹlé àwọn ìjọ tí ó ti wọnú ayé. Ní tọkàn-tọkàn ni wọn yóò sì máa pe àwọn ènìyàn lọkùnrin lóbìnrin láti yàgò nínú pípa òfin ènìyàn mọ kí wọn sì máa pa Ọjọ Ìsimi tòótọ mọ.-Prophets and Kings, pp. 186, 187.IIO 165.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents