Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Gbígba Ìkọ́ni Gẹ́gẹ́ Bí Iṣẹ́

    Nígbà tí ọmọ ìlérí àti alágbára bá ń yípadà bí ó ṣe wà nípa ti Tìmótíù, Pọ́ọ̀lù àti Bárnábà wá ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti fihàn bí ó ṣe ṣe pàtàkì láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà. Àti pè nígbà tí àwọn àpóstélì lọ sí ibòmíràn, ìgbàgbọ́ àwọn ọkùnrin yì í kò dákú, síbẹ̀ ó ń pọ̀ si ni. Wọ́n ti kọ́ wọn pẹ̀lú òdodo bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́ láì- mọ- tara- wọn- nìkan, ní pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́, ní ìdúró ṣinṣin fún ìgbàlà àwọn arákùnrin in wọn. Ìkọ́ni yìí tí a ṣọ́ra ṣe fún àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ jèrè ọkàn- an wọn ni ó jẹ́ ìṣokùnfà pàtàkì nínú àṣeyọrí tí kò lẹ́gbẹ́ fún Pọ́ọ̀lù àti Bárnábà bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìnrere ní ilẹ̀ àwọn kèfèèrí.- The Acts of the Apostles, pp.186,187.IIO 60.3

    Bí a ṣe ń fi àwọn ìjọ lọ́lẹ̀, a gbọdọ̀ gbe ka iwájú u wọn pé láàrin wọn ni áò ti mú ènìyàn tí yóò mú òtítọ́ lọ fún ẹlòmíràn, kí wọn sì tún lè gbé ìjọ tuntun kalẹ̀; fún ìdí èyí wọ́n gbọdọ̀ ṣiṣẹ́, àti láti roko títí dé ẹ̀kún àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fifún wọn, kí wọn sí kọ́ ọkàn an wọn láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn in ti adarí i wọn.- Tsetimonies, vol.3, p.205.IIO 61.1

    Àwọn òṣìṣẹ́ Ọlọ́run ní ilẹ̀ àjèjì ń rí ìjákulẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà fún àìrí àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ olùfọkànsìn tí ó tọ́,-Àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní ìfọkànsìn àti ìwà mímọ́ tí wọ́n lè jẹ́ aṣojú tòótọ́ fún ìgbàgbọ́ ọ wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà tí wọn ì bá yẹ láti jẹ́ ajíhìnrere, ṣùgbọ́n tí wọn kò ní dé pápá láíláí nítorí pé àwọn tí wọ́n so pọ̀ mọ́ wọn nínú ayé ìjọ tàbí nínú àwọn ilé-ìwé e wa kò ní ìmọ̀lára ìnilára láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú u wọn, láti ṣí síwájú u wọn àwọn ẹ̀tọ́ ọ ti Ọlọ́run lórí àwọn agbára a wọn, tí wọn kò sì gbàdúrà pẹ̀lu u wọn àti fún wọn.- Cousels to Teachers, pp.500,501.IIO 61.2

    Àwọn tí wọ́n ní àfojúsùn-un ti ẹ̀mí i ti ìjọ gbọdọ̀ wá gbogbo ọ̀nà àti ìpèsè nípa bí ànfààní ṣe le tó ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti kópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ìgbà ní ìgbà àtijọ́ ni a kò ṣe eléyì í. Kò tí ì sí àgbékalẹ̀ nípa bí gbogbo ẹ̀bùn yóò ṣe di lílò nínú iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n wà ṣùgbọ́n díẹ̀ ni wọ́n mọ iye tí ó ti sọnù nítorí èyí.- Testimonies, vol.9, p.116.IIO 61.3

    Nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ìjọ gbọdọ̀ kọ́ àti ya àkókò o wọn sọ́tọ̀ fún jíjèrè àwọn ọkàn fún Krístì. Báwo ni áò ṣe sọ níti ìjọ. “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé”, àyàfi tí àwọn ọmọ ìjọ lótítọ́ bá fi ìmọ́lẹ̀ ẹ wọn hàn? Jẹ́ kí àwọn tí ó bá wà níbi ìṣàkóso agbo ẹran Krístì jí sí iṣẹ́ ẹ wọn, kí wọn sì mú ọ̀pọ̀ àwọn ọkàn ṣiṣẹ́.- Testimonies,vol.6, p.436.IIO 61.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents