Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Sísọ Àpẹẹrẹ Ìrírí i Ti Ara Ẹni

    Gbogbo àwọn tí wọ́n ti gbé Kristi wọ̀ yóò sọ ìrírí i wọn, wọn yóò lépa ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé àwọn ìdarí Ẹ̀mí Mímọ́, - pípebi àti pípòǹgbẹ ẹ wọn fún ìmọ̀ Ọlọrun àti ti Jésù Kristi ẹni tí ìwọ rán, àyọrísí i tí wíwá inú ìwé mímọ́, àwọn àdúrà a wọn, ìrora ọkàn àti ọ̀rọ̀ ọ Kristi sí wọn, “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ rẹ jì ọ́”. Ó jẹ́ ohun tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá fún ẹnikẹ́ni láti fi àwọn n ǹkan wọ̀nyí pamọ́, àti pé àwọn tí ó kún fún ìfẹ́ ẹ Krístì kò ní ṣe bẹ́ ẹ̀. Nínú òṣùwọ̀n gẹ́gẹ́ bí Oluwa ṣe fi wọ́n ṣe ohun ìdógò o ti òtítọ́ mímọ́ yóò jẹ́ ìfẹ́ ọkàn-an wọn pé àwọn mìíràn yóò gba irú ìbùkún kan náà. Àti pé bí wọ́n ṣe mú wọn mọ ìṣúra tí ó lọ́rọ̀ níti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Síwájú àti síwájú sí i ni a yóò fi oore-ọ̀fẹ́ Kristi fún wọn.- Christ Object Lessons, p.125.IIO 124.2

    Sọ agbára ẹ̀mí jí fún iṣẹ́. Sọ fún gbogbo àwọn tí o bẹ̀wò pé òpin gbogbo àwọn n ǹkan ti súnmọ́ tòsí. Jesu Kristi Oluwa yóò ṣí ìlẹ̀kùn àwọn ọkàn-an wọn, yóò sì tẹ́ àwọn ohun ìkẹhìn mọ́ wọn ní àyà. Gbìyànjú láti sọ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin jí kúrò nínú u ìkúra ti ẹ̀mí. Sọ fún wọn bí o ṣe bá Jesu pàdé, àti bí ó ṣe bùkún fún ọ láti ìgbà tí o ti ní ìrírí nínú iṣẹ́ ìsìn-in RẸ̀. Sọ fún wọn ìbùkún tí ó wá sí ọ̀nà à rẹ bí o ṣe ń jókò ó lẹ́sẹ̀ ẹ Jesu, tí o sì ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye láti inú ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀. Jẹ́ kí wọn mọ inú dídùn àti ayọ̀ tí ó wà nínú ìgbé ayé e Krìstẹ́nì. Àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀ rẹ tí ó ní ìtara yóò mú dá wọn lójú pé o ti rí Pérílì ń lá tí ó ní iye lórí. Jẹ́ kí inú dídùn ù rẹ, ọ̀rọ̀ ìgbìyànjú ù rẹ fihàn pé lótítọ́ o ti rí ọ̀nà tí ó ga jù. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ ojúlówó nì yí, àti pé bí o ṣé ń ṣe wọ́n, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò tají bí ẹni tí ń lá àlá. - Testimonies, vol.9, p.38.IIO 124.3

    Àwọn tí Ọlọrun gbà síṣẹ́ bí ohun èlò o RẸ̀ ni àwọn mìíràn lè kà sí aláìlágbára; ṣùgbọ́n tí wọ́n bá lè gbàdúrà, tí wọ́n bá sì lè sọ òtítọ́ ní ọ̀nà tí ó rọrùn, tí wọ́n ń kà nínú ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀, tàbí tí wọ́n ń mú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti sẹlẹ̀ wá sí ìrántí, Ẹ̀mí Mímọ́ náà yóò fi sí wọn ní ọkàn àti sínú ìwà a wọn. Ìfẹ́ ọkàn ènìyàn yóò sì wà lábẹ́ ìfẹ́ ẹ ti Ọlọ́run; òye òtítọ́ tí ó ti wà ṣáájú àkókò yìí tí kò yé wọn ni yóò wá sí ọkàn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó wá láàyè, tí yóò sì jẹ́ ohun ẹ̀mí ní tòótọ́. - Testimonies, vol.6, p.444.IIO 125.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents