Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ — KÌN-ÍN-NÍ—ÌPÈ ỌLỌ́RUN SÍ ISÉ ÌSÌN

    Ìgbáralé Ènìyàn Aṣojú

    Olórun kò lo àwọn áńgélì tí wọn kò subú rí láti jé aṣojú òun láarin àwon ènìyàn, ṣùgbon ó lo àwọn ènìyàn tí wọn ní ìwà kan náà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fẹ́ gbàlà.Olọ́run gbé àwọ̀ ènìyàn wọ̀ láti lè bá wa pàdé.Olùgbàlà ti’ ó wá ní ìwá ènìyàn wá láti fún aráyé ní ìgbàlà. A sì ti fi isé yìí sí ìkáwọ́ ọkùnrin àti obìnrin láti jẹ́ kí “àwọn ènìyàn mọ̀ nípa ọrọ̀ Ọlọ́run tí a kò le è ṣàwárí nípa Krísítì” — The Acts of the Apostles, p. 134.IIO 7.1

    Wo ìfowọ́kàn an rẹ̀, Wo bí ogo ọ̀run ṣe yí àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá tí ó yàn ká.Ó sì fẹ́ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣé ẹ rẹ̀.Nípa ọ̀rọ̀ àti ẹ́mí i rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìlera yìí,ó ṣe é kí èto ìgbàlà le è wà ní àrówótó” o wa.- The Acts of the Apostles, p.18IIO 7.2

    “Rán áwọn ènìyàn sí Jóppà, kí o sì pe Símíónì” èyì, Olọ́run fi ẹ̀rí lélẹ nípa bíbu ọlá fún iṣẹ iranṣẹ ìhìnrere àti fún ìjọ ọ RẸ̀ tí ó ṣètò.A kò fi àṣe fún angẹli láti sọ fún Kọ̀nélíù ìtàn ti orí àgbélébù ú.Ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀hìn pàápàá bíi balógun ọ̀rún fúnra a rẹ̀, àti sí àwọn àìlera ènìyàn àti àwọn ìdánwò, ni ó yẹ kí ó sọ fún un ní ti Olùgbàlà tí a kàn mọ́gi tí ó sì jíǹde.-The Acts of the Apostles, p.134IIO 7.3

    Angẹli ti wọn ran si Filipi i ba ti funra a rẹ ṣe iṣẹ fun ara Etopia, ṣugbọn ki i ṣe bi Ọlọrun ṣe ma a n ṣiṣẹ niyi.Ètó Olọ́run ni pé kí a ṣiṣẹ́ fún ọmọnìkéjì i wa.The Acts of the Apostles.- p.109.IIO 7.4

    “A ni iṣura yii,“Àpóstélì tẹ́ síwájú láti sọ fún wa pé a ní ìṣúra yìí tí a pamọ́ tí agbára àti ọlá a rẹ kìí ṣe tiwa bíkòṣe ti Olọ́run. Olọ́run le è lo àwọn a ángélì tí kò dẹ́ṣẹ̀ láti fi òtítọ́ ọ rẹ̀ hàn ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe èrò o rẹ̀.Ó lo àwọn ènìyàn aláìlera bí ohun èlo fún iṣẹ́ tí ó gbé kalẹ̀.Ìṣúra tí kò níyelórí yìí ni a fi pamọ́,nípasẹ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí,àwọn ìbùkún rẹ̀ gbọdọ̀ lọ sí gbogbo ayé.Nípasẹ̀ wọn bákan náà,ògo Olọ́run gbọdọ tàn sínú ayé ẹ̀ṣẹ̀ yìí.Nínú iṣẹ́ ìhìnrere ìfẹ́ yìí,wọ́n gbọdọ̀ bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,àti àwọn tí ó nílò ìraǹlọ́wọ́ pàdé kí a sì fi ọ̀rọ̀ àgbélébùú lọ̀ wọ́n,kí wọn sì fi ògo, ọlá àti iyìn fún ẹnití ó ju gbogbo ayé lọ nínú iṣẹ́ ẹ wọn.-The Acts of the Apostles, p. 330.IIO 7.5

    Èròǹgbà Olọ́run ni pé lẹ́yìn ìgòkè re ọ̀run un rẹ̀ láti jẹ́ alágbàwí i wa, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀ síwáju nípa iṣẹ́ tí ó ti bẹ̀rẹ̀.Tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò bá ní inú dídùn láti tan ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere sí àwọn tí wọ́n jòkó sínú òkùnkùn?Díẹ̀ lára àwọn ènìyàn ni wọ́n ṣetán láti lọ sí òpin ayè láti tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ọ̀rọ̀ o rẹ̀ sí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n Olọ́run ń bèèrè pé gbogbo ọkàn tí ó mọ̀ nípa òtítọ́ yìí yóò wá ọ̀na láti fi òtítọ́ àti ìfẹ́ Olọ́run han àwọn ẹlòmííràn.Tí a kò bá ṣetán láti jọ̀wọ́ ara wa fún iṣẹ́ ìgbàla ọkàn tí o ṣetán láti ṣègbé, báwo ni a ó ṣe ye fún ìlú Olọ́run.-Testimonies, vol. 9, P. 103.IIO 8.1

    Olọ́run nínú ọgbọ́n ọn rẹ̀ ti mú àwọn tí won ń wá òtítọ́ yìí pàdé àwọn tí wọ́n mọ̀ nípa òtítọ́ yìí. Àgbékalẹ̀ ọ̀run ni pé àwọn tí wọ́n ti ní ìmọ́lẹ̀ yìí yóò tàn sí àwọn tí ó wà lóòkùn.Àwọn ẹni àmúyẹ yìí gba agbára wọn láti orisun ọgbọ́n tí ó tóbi jùlọ,tí a sì mú wọn jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí ìhìnrere yóò fi wọ ọkàn àti àyà àwọn èniyàn pẹ̀lú agbára ìyípadà a rẹ̀s.-The Acts of the Apostles, p. 134.IIO 8.2

    Olọ́run lè bá ọkàn awọn ẹlẹ́sẹ̀ yìí padé láì sí ìrànlọ́wọ́ o wa; ṣùgbọ́n láti ní ìwà bí i ti Kírísitì, a gbọdọ̀ ṣe alábapin nínu iṣẹ́ ẹ rẹ̀. Kí a ba à le wọ inú ayọ̀ o rẹ̀, àní ayọ̀ rírí ọkàn tí a gbàlà nípa ìrúbọ rẹ̀, a gbọdọ̀ darapọ̀ nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀ fún ìgbala a wọn.-Desire of Ages, p142.IIO 8.3

    Gẹ́gé bí aṣojú láarin àwọn ènìyan, Ọlọ́run kò yan àwọn angélì tí kò tíì subú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ó yan ènìyàn tí ìwà wọ́n jọra a wọn pẹ̀lú àwọn tó wá láti gbàlà. Enití kò dẹ́ṣẹ̀ rí nílò èniyàn; nítorí pé iṣẹ́ yìí nílò ẹnití kò dẹ́ṣẹ rí àti ènìyàn láti mú ìgbàlà tọ aráyé.Eni mímọ́ nílò ènìyàn, kí ènìyàn lè jẹ́ bí orísun ìbásọ̀rọ̀ láarin Olọ́run àti ènìyàn- The Desire of Ages, P.296.IIO 8.4

    Pẹ̀lú ìwà à nwára àwọn áńgélì dúró fún ìfowósowópò o wa, nítorí ènìyàn gbọdọ̀ jẹ́ orísun ìbásòrò fún ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀.Tí a bá sì wá fi gbogbo ọkàn an wa fún Olọ́run, inú àwon ańgélì yóò dùn tí wọn yóò sì fi le máa fi ohùn un wa sọ̀rọ̀ láti fi ìfẹ́ Olọ́run hàn. Desire of Ages, p. 297IIO 9.1

    A gbọdọ̀ jẹ́ alábáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Olọ́run, nítori pé Olọrún kò ní parí iṣẹ́ ẹ rẹ̀ laísì ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀. Review and Herald, March 1, 1887.IIO 9.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents