Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ṣíṣe Ìtọ́jú Àwọn Ọmọ Òrukàn

    Títí di ìgbà tí a o fi gbé ikú mì ní ìṣẹ́gun, ni a o máa rí àwọn ọmọ òrukàn tí wọ́n nílò ìtọ́jú, tí wọn yóò jẹ́yà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ti wọn kò bá ni àwọn ọmọ ìjọ wa tí wọ́n ní ojú rere àti àánú sí wọn. Ọlọ́run rọ̀wa “Ẹ mú àwọn aláìní tí a tanù wá sí ilé Mi”. Ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ ni ó gbọ́dọ̀ jẹ bàbá àti ìyá fún àwọn ọmọ alárìnká. Àánú tí a ṣe sí àwọn opó àti àwọn ọmọ òrukàn ti o sì tún farahàn nínú àdúrà àti ìṣe wa, ni a ó mú wá sí ìrántí níwájú Olúwá, tí a ò sí pín wọn ní èrè rẹ̀ nígbòóṣe.- Review and erald, June 27, 1893.IIO 215.5

    Tí a bá ṣe ìrànlọwọ fún àwọn aláìní, tí a sì kẹ́dù pẹ̀lú àwọn tí a pọ́n-lójú àti onírẹ̀wẹ̀sì ọkàn, ti a d’ọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ òrukàn, èyí yóò mú àṣepọ̀ wa túnbọ̀ súnmọ́ Jésù sí.- Testimonies, 2, p. 25.IIO 216.1

    A ní àwọn ọmọ òrukàn tó pọ̀,tí wọ́n yí wa ká láti tọ́jú, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò ní gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ náà, nítorí wàhálà tí ó wà níbẹ̀ pọ̀ ju èyí tí wọ́n rò wí pé àwọn lè ṣe, èyí tí kì í yóò sí àyè fún wọn láti gbádùn ara wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọba bá wá ṣe ìwádì, irú àwọn aláìní-kan-ń-ṣe, àwọn ahun, àwọn onímọ-tara-ẹni-nìkan wọ̀nyìí yóò mọ̀ wí pé ọ̀run kò sí fọ́lẹ bíkòṣe àwọn òṣìṣẹ takuntakun tí wọ́n ti fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ nítorí ìfẹ́ Kírísítì. Kò sí ìpèsè kankan fún àwọn tó jẹ́ wí pé kìkí ara wọn ni wọ́n ń tọ́jú jù, irú ìpèsè ìjìyà èyí tí Ọba ti ṣèlérí fún àwọn tí ó wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ní irú ẹjọ́ báyìí, kìí ṣe nítorí pé wọ́n dáràn ni o, tàbí fún ìwà ohun tí wọ́n ti ṣe bíkòṣe èyí tí wọ́n fi sílẹ̀ láì ṣe. Wọn kò ṣe ohun tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láti ṣe. Wọ́n tẹ́ ara wọn lọ́rùn bẹ́ẹ̀ni ipò wọn yóò wà pẹ̀lú àwọn olùtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn.-Review and Herald, Aug. 16, 1881.IIO 216.2

    Àwọn ọmọ òrukàn kan wà tí Ọlọ́run ti fi sí ìkáwọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ láti máa bójútó ṣùgbọ́n tí a ti fi ojú parẹ́. Wọ́n lè jẹ́ alákìísà, ènìyàn-rádaràda, tí kò fanimọ́ra ní ọ̀nàkọnà, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ohun ìní Ọlọ́run ni wọ́n. A ti rà wọ́n padà ní iye kan, wọ́n sì ṣe iyebíye ní ojú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa náà. Wọ́n jẹ́ ọmọ ìdílé Ọlọ́run, àti gẹ́gẹ́ bí Onígbàgbọ́ ṣe jẹ́ ìríjú Rẹ̀, ni a ti fi irú àwọn wọ̀nyìí sí ìkáwọ́ wọn. “Ọkàn wọn”, ni Ó sọ wí pé, “Èmi yóò bèèrè ní ọwọ̀ rẹ.-“Christ’s Object Lesson, pp. 38, 387.IIO 216.3

    Ìpè Ọlọ́run sí àwọn ọmọ òrukàn. E máà ṣe jẹ́ kí a ṣiṣẹ́ fún wọn nítorí pé a kàn kàá sí iṣẹ́ lásán bíkòṣe wípé a fẹ́ràn wọn àti wí pé Kírísítì kú láti gbà wọ́n là. Kírísítì ti ra ọkàn àwọn tí wọ́n nílò àbójútó rẹ̀, Ó sì fẹ́ kí o nífẹ́ẹ̀ wọn à ní bí Òun pàápàá ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti nígbàtí ó ṣáko lọ.-Review and Herald, June 27, 1893.IIO 216.4

    Kò ní gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ̀ nígbàtí wọ́n bá ń fi ojú pa àwọn ọmọ òrukàn, àwọn aláìní-bàbá, àwọn arọ, àwọn afọ́jú àti àwọn aláìsàn tí ó wà láyìíká wọn rẹ́.-Testimonies, Vol. 3, p. 518.IIO 217.1

    Iṣẹ́ tí ó pọ̀ wà fún gbogbo àwọn tí yóò ṣiṣẹ́ fún Olúwa láti ṣe ìtọ́jú àwọn tí a tí kọ̀ sílẹ̀ láwùjọ, nígbà tí à ń mú wọn wá sí ipò tó bójúmu láti ní ìwà rere kí wọ́n baà lè di ọmọ Ọlọrun. Ó yẹ kí a ṣe àwárí àwọn ọmọ kan tí a ti lérò wí pé ọjọ́ ọ̀la wọn kò lèè dára mọ, irú àwọn tó jẹ́ wí pé tí wọ́n bá lè dàgbà sínú ipò tí wọ́n wà báyìí, irú wọn yóò padà ya ọmọ burúkú lẹ́hìnwá ọ̀la, kí a sì ṣe akitiyan láti fi ìwà Kírísítì kọ́ wọn kí wọn baà lè di ẹni ìgbàlà lẹ́hìnwá ọ̀la. Irú iṣẹ́ yìí èyí tí ó le tí ó gba ìfarà-ẹni-jìn, ìséra-ẹni àti ìfi-ara-ẹni-rúbọ, ṣùgbọ́n irú ìfi-ara-ẹni-rúbọ wo ni a leè ṣe ti a lè fi wé ẹ̀bùn ńlá tí Ọlọ́run fún wa nípa fífún aráyé ní ọmọ Rẹ̀ kan ṣoṣo? Ọlọ́run ti fún wa ní ànfààní láti jẹ́ alábàṣíṣẹ́ paapọ̀ Rẹ̀.-Review and Herald, June 27, 1893.IIO 217.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents