Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Iṣẹ́ Gbọdọ̀ Wà

    A fihàn mí pé àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń dúró fún ìyípadà láti ṣẹlẹ̀,- agbára ipá kan fẹ́ gbá wọn mú. Ṣùgbọ́n wọn yóò dá wọn lára, nítorí pé wọ́n ṣìnà. Wọ́n gbọdọ̀ gbé ìgbésẹ̀; wọ́n gbọdọ̀ mú iṣẹ́ náà gírí fúnra a wọn, kí wọn kígbe tìtara tìtara sí Ọlọrun fún ìmòye tòótọ́ fún iṣẹ́ yìí fúnra a wọn. Àwọn ìran èyí tí ó ń kọjá lọ níwájú u wa tí tóbi tó fún wa láti jí dìde, àti pé ki a so òtítọ́ náà ní kíkan kíkan sí àwọn ọkàn gbogbo tí yóò fetí sílẹ̀. Ìkórè ayé fẹ́rẹ̀ ẹ́ pọ́n.- Testimonies, vol.1, p.261.IIO 82.4

    Ohun gbogbo tó wà láyé ń pe àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sí pípolongo ti òtítọ́ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fihàn wọ́n nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ángẹ́lì kẹ́ta. Pé èyí tí a ti rí tí a sì ti gbọ́ ń pè wá sí iṣẹ́ ẹ wa. Iṣẹ́ tí àwọn aṣojú sàtánì ń pe onígbàgbọ́ kọ̀ọ̀kan láti dìde ní ipò o rẹ̀.- Testimonies,vol.9, pp.25,26.IIO 83.1

    Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ìpadàbọ̀ Kristi ni a ní láti fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Ìṣọ́ra, ìgbìyànjú láì ṣàárẹ̀ ni a nílò láti borí àwọn ọmọ ogun ti ọ̀tá.Ìpín- in wa kì í ṣe kí a jòkó jẹ́ẹ́ kí a sọkún kí a sì lọ́ àwọn ọwọ́ ọ wa, ṣùgbọ́n kí a dìde kí a ṣiṣẹ́ fún àkóko àti fún ayérayé. - Southern Watchman, May 29, 1902. IIO 83.2

    “Wá n ǹkan, ṣe é láìpẹ́, pẹ̀lú gbogbo agbára à rẹ;
    Ìyẹ́ ańgẹ́lì yóò rọ̀ dẹ̀dẹ̀ tí o bá pẹ́ lórí ìsinmi;
    Àti Ọlọ́run fúnra a RẸ̀, nínú u dídáwọ́kọ́ kò ní bùkún mọ́.”
    IIO 83.3

    -Testimonies, vol.5, p.308.

    Kí ẹnikẹ́ni máṣe rò pé òun ti wà ní òmìnira láti káwọ́ gbera láì ṣe ohunkóhun. Pé ẹnikẹni yoo ri igbàlà nínú ìmẹ́lẹ́ àti àìláápọn jẹ́ àlá tí kò lè ṣẹ.” Ronú lórí n ǹkan tí Jesu ṣe láṣepé nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ RẸ̀ ní ayé. Bí ó ṣe ní ìtara, láì ṣàárẹ̀, ní àwọn ìgbìyànjú u RẸ̀ ! kò gba ohunkóhun láàyè láti yí Òun padà kúrò nínú iṣẹ́ tí a fifún Un. Ṣé à ń tẹ̀lé ìgbésẹ̀ ẹ RẸ̀ ?- Colporteur Evangelist, p.38.IIO 83.4

    Aṣojú ọ̀run àti ènìyàn ni a papọ̀ nínú iṣẹ́ ìjèrè àwọn ọkàn. Ọlọ́run ti ṣa ipá a RẸ̀, kíkópa ti onígbàgbọ́ ni a nílò báyìí, Ọlọrun ń pè ìpè fún èyí. Ó ń retí àwọn eniyan- an RẸ̀ láti kópa nínú fífi ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ọ RẸ̀ hàn fún gbogbo orílẹ̀-èdè. Tani yóò wọ inú àjùmọ̀ṣepọ̀ pẹ̀lú Jésu Krístì Olúwa?- Review and Herald, March 1, 1887.IIO 83.5

    Ìjọ gbọdọ̀ jẹ́ ìjọ tí ó ń ṣiṣẹ́ tí yóò jẹ́ ìjọ alààyè, kò gbọdọ̀ nítẹ́ẹ́lọ́rùn nínú u níní ààyè e rẹ̀ ní ìtako àwọn agbára ẹ̀sẹ̀ àti àṣìṣe lásán, láti má a tako ìtẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbésẹ̀ fònídónìí fọ̀ladọ́la, ṣùgbọ́n ó gbọdọ̀ gbé àjàgà a ti Kristi, kí ó sì máa fẹ̀gbẹ́ kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú adarí, kí ó sì jèrè àwọn ogun titun ní ojú ọ̀nà. - Review and Herald, Aug. 4, 1891.IIO 83.6

    Ogun náà kò ní í pẹ́ parí; nígbà náà ni Jésù yóò dé, àti ìran ìṣọ̀tẹ̀ yìí yóò dópin. Lẹ́hìn náà, ìgbìyànjú u wa tí ó kẹ́hìn ni áò bá ti fi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú u Krístì fún ìtẹ̀síwájú ìjọba a RẸ̀. Àwọn díẹ̀ tí ó dúró níwájú ogun, pẹ̀lú ìtara láti kojú sí ohun búburú tí ń bọ̀wá, ṣubú ní ẹnu iṣẹ́ ẹ wọn; ọ̀pọ ń wo àwọn akọni tí ó ṣubú pẹ̀lú ìbìnújẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ààyè fún wọn láti ṣíwọ́ iṣẹ́.Ẹgbẹ́ ológun ní láti kóra pọ̀, kí wọn sì gba àsìá kúrò lọ́wọ́ tí ikú ti sọ di rírọ , àti pẹ̀lú agbára ọ̀tun láti dáààbò bo òtítọ́ àti ọ́lá a ti Krístì ju bí ó ṣe rí tẹ́lẹ̀, ìdojúkọ gbọdọ̀ wà ní ìtako ẹ̀ṣẹ̀- ní ìtako àwọn agbára òkùnkùn. Àsìkò ìbéèrè fún agbára àti ìpinnu ìyára ní ipa àwọn tí ó gba òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí. Wọ́n gbọdọ̀ kọ́ òtítọ́ pẹ̀lú ìlànà àti àpẹẹrẹ. - Review and Herald, Oct.25, 1881.IIO 84.1

    Ní báyìí, Ọlọ́run ń pe àwọn Onírètí i Bíbọ̀ ọ Jésù ní gbogbo àgbáyé láti ya ara wọn sí mímọ́ fún UN, kí wọn sì ṣa gbogbo ipá a wọn, gẹ́gẹ́ bí ipò àti ààyè e wọn ṣe rí, láti ran iṣẹ́ ẹ RẸ̀ lọ́wọ́.- Testimonies, vol.9, p.132.IIO 84.2

    Àìṣiṣẹ́ àti ìsìn kò lọ ní fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́; àti ohun tí ó ń fa àbùkù nínú ayé onígbàgbọ́ àti ìrírí ni àìyára nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ẹran ara à rẹ ni yóò di aláìlágbára, tí kò sì ní níláárí tí wọn kò bá má a fi ṣe ìdárayá, bákan náà ní ó rí pẹ̀lú ohun ti ẹ̀mí. Tí o bá fẹ́ lágbára, ó gbọdọ́ ṣe ìdárayá fún àwọn agbára a rẹ̀.- Review and Herald, March, 13, 1888.IIO 84.3

    A gbọdọ̀ jẹ́ aláì ṣèmẹ́lẹ́ òṣìṣẹ́; ọ̀lẹ ènìyàn jẹ́ òtòṣì ẹ̀dá.Ṣùgbọ́n àwáwí wo ni a lè fún àìṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ń lá èyí tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí i RẸ̀ lélẹ̀ fún láti ṣé láṣepé?. Àwọn ọgbọ́n tí ẹ̀mí dẹ́kun láti wà tí a kò bá lò wọ́n, àti pé èṣù lérò pé wọ́n yóò ṣègbé. Gbogbo ọ̀run ni wọ́n ń yára láti kópa nínú pípèsè àwọn ènìyàn sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Jésù Krístì lẹ́ẹ̀kejì sínú ayé e wa, “a sì jẹ́ alábaṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” Òpin gbogbo nǹkan wà ní ọwọ́ ọ RẸ̀. Báyìí, ààyè wà fún wa láti ṣiṣẹ́.- Review and Herald, Jan. 24, 1893.IIO 84.4

    Ajíhìnrere olufọkansin ni a nílò, ìgbìyànjú u dákú dájí kò lè wúlò. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun mìíràn gba ọkàn-an wọn. A gbọdọ̀ jẹ́ kí ìtara wa jinlẹ̀ sí i. - Testimonies, vol.9, p.45.IIO 85.1

    Àwọn kàn wà lára wa tó jẹ́ pé tí wọn yóò bá rò ó, wọn yóò kíyèsi pé ipò àìṣe n ǹkankan tí wọ́n wà jẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ àfojúrénà ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fifún wọn.- Testimonies, vol.6, p.425.IIO 85.2

    Kín ni ipò o wa nínú ayé? A ti ´ní àsìkò o dídúró. Ṣùgbọ́n àsìkò yìí kì í ṣe kí a lò ó nínú àkópọ̀ àdúrà. Dúró, ṣónà àti ṣíṣọ́ra ṣiṣẹ́ ní a le kópọ̀. Ìgbé ayé e wa kò gbọdọ̀ jẹ́ ìkánjú àti darí àti ìgbèrò lórí àwọn n ǹkan ti ayé, sí ìgbàgbé ìfọkànsìn ti ọlọ́danni àti ti iṣẹ́ ìsìn ni Ọlọ́run ń fẹ́.Nígbà tí a kò gbọdọ̀ ṣọ̀lẹ nínú n ǹkan tí ó kàn wá, A gbọdọ̀ gbóná nínú ẹ̀mí, nínú sí sin Olúwa. Fìtílà ti ọkàn ni ó gbọdọ̀ jò geere, a sì gbọdọ̀ ní òróró o ti oore-ọ̀fẹ́ nínu àwọn ohun èlò pẹ̀lú àwọn fìtílà a wa.Gbogbo ìtètè funra ni a gbọdọ̀ lò láti dènà ìfàsẹ́hìn ti ẹ̀mí, kí ọjọ́ Olúwa kó má ba à dé bá wa bí olè.- Testimonies, vol.5, p. 276.IIO 85.3

    À ń gbé ní ìgbà tí sí ṣọ̀lẹ ti ẹ̀mi.Olúkúlùkù ọkàn ni ó sì gbọdọ̀ gbiná pẹ̀lú iná ọ̀run tí ó tàn kálẹ̀.- Testimonies, vol.8, p.169.IIO 85.4

    Kó àwọn iṣẹ́ rere è rẹ tí o bá lè kó jọ sínú ayé yìí.- Testimonies, vol.5, p.488.IIO 85.5

    Jesu yóò fẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó jẹ́wọ́ ọ orúkọ ọ RÈ jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ onítara. Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnìkọ̀ọ̀kan kọ́ ilé e rẹ̀ sórí àpáta Krístì Jésù. Ìjì sì ń dìde tí yóò sì fi agbára gbà tí yóò sì dán ìpìlẹ̀ ẹ̀mí i ti ẹnìkọ̀ọ̀kan títí dé òpin. Nítorí náà, yàgò fún ìpìlẹ̀ orí iyanrìn, dọdẹ fún àpáta, wádì í jinlẹ̀; jẹ́ kí ìpìlẹ̀ ẹ̀ rẹ dájú.Kọ́, mo tún-un wí lẹ́ẹ̀kan sii kọ́ fún ayérayé! Kọ́ pẹ̀lú omijé, pẹ̀lú àdúra àtọkàn wá. Jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín láti ìgbàyí lọ, mú ìgbésí ayé e rẹ̀ lẹ́wà pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn ènìyàn bí i Kálẹ́bù ni a nílò ní àsìkò ìkẹhìn yìí.- Testimonies, vol.5, pp.129,130.IIO 85.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents