Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Tí Kìí Ṣe Aláwọ̀ Funfun

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ tí a kòì tí ì fọwọ́kàn ni ó wà ní orílẹ̀-èdè yìí. Àwọn tí kíì ṣe aláwọ̀ funfun, tí wọ́n pọ̀ bí ìyanrìn, ìpè tàbí àrọwá lọ sí gbogbo ọ̀dọ̀ ojúlówó Onígbàgbọ́ nínú Kírísítì. Àwọn ènìyàn wọ̀nyìí kò gbé ní ilẹ̀ òkèèrè, bẹ́ẹ̀ni wọ́n kò foríbalẹ̀ fún òrìṣà tí a gbẹ́ lére tàbì òkúta Kankan. Wọ́n ń gbé láàárín wa nígbà gbogbo àti nígbà gbogbo, nípasẹ̀ ìjẹ̀rí sí Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀, Ọlọ́run ń pe àkíyèsí wa sí wọn, tí Ó sì ń sọ fún wa wí pé níhìn-ín yìí ni àwọn tí a fi ojú parẹ́ wà. Iṣẹ́ ńlá yìí wà níwájú wa láìṣe tí ó sì ń pè wá kíkan-kíkan láti wá tan ìmọ́lẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi sí ìkáwọ́ wa síbẹ̀.-Testimonies, Vol. 8, 205.IIO 217.3

    Ògiri ìyapa ńlá ni a ti gbé kalẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn funfun àti àwọn ènìyàn dúdú. Ògiri ẹ̀tanú yìí yóò wó lulẹ̀ fúnra rẹ̀ gẹ́géẹ bí ògiri Jẹ́ríkò, nígbà tí àwọn Kìrìsítẹ́nì bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó pa wọ́n láṣẹ láti ni ìfẹ́ ńlá sí Ẹlẹ́dàá wọn àti ìfẹ́ tí kò ní ojúṣàájú sí àwọn aládùúgbò wọn. Ẹ jẹ́ kí gbobgo ìjọ tí àwọn ọmọ ìjọ wọn ń sọ pé àwọn gba òtítọ́ àkókò yìí gbọ́ ṣe àwárí àwọn ẹ̀yà tí a fi ojú parẹ́, tí a sì ń pọ́n lójú nípasẹ̀ ìwà òwò ẹrú, tí wọ́n kó sì ní òmìnira láti ṣe ìfẹ́ ara wọn.-Review and Herald, Dec. 17, 1895.IIO 217.4

    Ẹ jẹ́ kí a dìde kí a sì ṣe iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní Gúsù, e máa ṣe jẹ́ kí a máa wò wọ́n lásán án nípa ṣíṣe ìpinnu tí a kò ṣiṣẹ́ lé lórí; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a fi tọkàntọkàn ṣe ohun kan fún Olúwa láti mú ìpọ́njú àwọn tí kìí ṣe àwọn aláwọ̀ funfun yìí kúrò.-Review and Herald, Feb. 4, 1896.IIO 218.1

    Orúkọ ènìyàn dúdú ni a kọ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú orúkọ ènìyàn funfun nínú ìwé ìyè. Ọ̀kan náà ni wá nínú Kírísítì. Ìbí wa, ìbùgbé, orílẹ̀-èdè tàbí àwọ̀ ènìyàn kọ́ ní ó ń gbé ènìyàn ga tàbí rẹ̀ẹ́ sílẹ̀ bíkòṣe ìwà rẹ̀. Jésu fẹ́ràn gbogbo ẹnikẹ́ni tí o bá fi ayé rẹ̀ fún Ọlọ́run nínú ìgbọràn àti ìgbàgbọ́ láì sí ojúsàájú. Ó pè é ní arákùnrin mí, ẹni tí mo fẹ́ràn jù.-The Southern Watchman, p. 8, Mar. 20, 1891.IIO 218.2

    Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ọkàn àwọn ọmọ adúláwò tí ó gbàgbọ́ kò jú èyí tí Ó ní sí ọmọ Isreli lọ. Ó ń bèèrè ju ohun tí àwọn ajíhìnrere rẹ̀ ń fi fún-Un nípa iṣẹ́ ìjèrè ọkàn ni pàtàkì jùlọ láàárín àwọn ènìyàn adúláwò, àwọn ènìyàn ti ìhá Gúsù. Iṣẹ́ ńlá kọ́ la gbà láti lèè ṣiṣẹ́ fún àwọn ẹ̀yà ènìyàn dúdú ju àwọn tí a rò pé wọ́n ṣe pàtàkì ni? Ta ni ó ko àwọn wọ̀nyìí lẹ́rù? Ta ni ó sọ wọ́n di òpè? Tí àwon ẹ̀yà yìí bá rẹ̀hìn tí ìwà wọn kò gún régé, ta ni ó sọ wọ́n di bẹ́ẹ̀? Ǹ jẹ́ áwọn ènìyàn funfun kò jẹ wọ́n nígbèsè bí? Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ibi tí wọ́n ti ṣe sí wọn, ǹ jẹ́ kò yẹ́ kí á ṣe iṣẹ́ takuntakun láti fà wọ́n sókè bí? A gbọ́dọ̀ mú òtítọ́ tọ̀ wọ́n lọ. Wọ́n ní ọkàn láti gbàlà gẹ́gẹ́ bí ti àwọn náà.-The Southern Work, pp. 11, 12, Mar. 20, 1891.IIO 218.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents