Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí ó Ń bọ̀

    Àwọn ènìyàn wa ni àwọn ènìyàn rò wípé kò ṣe pàtàkì láwùjọ, ṣùgbọn ṣá ìyàtọ ń bọ láìpẹ. Àwọn Onígbàgbọ àgbáyé ni wọn ti ń ṣe ètò láti jẹ kí àwọn ènìyàn tí ń pa òfin Ọlọrun mọ di gbájúmọ. Gbogbo ìgbà ni àwọn ènìyàn ń gbíyànjú láti fi èrò inú wọn àti ìkọni èké tí ó ti ọwọ ènìyàn wá rọpò òtítọ Ọlọrun. Àwọn àgbékalẹ ni ó sì ti wà tí wọn ti ṣe láti fi ọkàn àwọn tí wọn jẹ olóòòtọ sí Ọlọrun sínú ìgbèkùn. Àwọn aṣòfin wọnyí yóò sì takò àwọn ènìyàn Ọlọrun. Gbogbo ọkàn ni a ó sì dánwò.-Testimonies, Vol. 5, p.546.IIO 155.4

    Àwọn ènìyàn yóò ṣe àgbékalẹ ófin ti ó le koko láti ṣe àtakò sí òfin Ọlọrun. Bí ó tilẹ jẹ wípé pẹlú ìtara ni wọn yóò fi ìdi òfin wọn múlẹ, wọn ó sì tipasẹ ṣiṣe bẹẹ yí kúrò nínú “Báyìí ni Olúwa wí”. Nígbà tí wọn ń bọla fún ayédèrú ọjọ ìsinmi, wọn ó si fẹ fi tipátipá mú kí àwọn ènìyàn tàpá sí òfin Jèhófà èyi tíí ṣe ìwà Rẹ. Nínú àìmọkan ìwà búrúkú wọn, wọn óò mú kí àbùkù kan àwọn òjíṣẹ Ọlọrun bẹẹni wọn óò sì fi ìyà jẹ wọn pẹlú láti ọwọ àwọn tí wọn gba ìmísí láti ọwọ Sátánì, àwọn tí ọkàn wọn kún fún owú jíjẹ àti ìtakò ti ẹsìn.-Testimonies, Vol. 9, p.229.IIO 156.1

    Àwọn agbára ẹsìn tí wọn ní àfarawé ìwà Ọlọrun àti ìwà ti Ọdọ Àgùtàn ni wọn yóò sẹ agbára Ọlọrun nípa wọn fifi hàn wípé ọkàn dragoni ni àwọn ní àti wípe dragoni yìí ni ó ń darí àwọn. Àkókò kan ń bọ wá, èyí tí àwọn ènìyàn Ọlọrun yóò rí ìpọnjú nítorípé wọn ń pa Ọjọ Isinmi tòótọ mọ.... ṣùgbọn àwọn ènìyàn Ọlọrun wọnyí ni ó gbọdọ dúró gbọin fún Ọlọrun. Ọlọrun yóò si gba ọwọ wọn ṣiṣẹ nípa fifi hàn wípé Òun ni Ọlọrun àwọn Ọlọrun.-Testimonies, Vol. 9, pp. 229, 230.IIO 156.2

    Gbogbo ìdójútini òun àbùkù, ẹgàn àti ìwà búbúrú tí Sátánì ń gba ọwọ àwọn ènìyàn ṣe ni a óò fi pọn àwọn atẹle Jésù lójú. Èyi pàápaà ni yóò fi ara hàn ni ọna ti o han gbangba nítorípé ọkàn ara máa ń ṣe lòdì sì òfin Ọlọrun bẹẹ sì ni irú ọkàn ara bẹẹ kò ní tẹríba sí àṣẹ Ọlọrun. Ayé pàápàá kò wà ní ìbárẹ pẹlú àgbékalẹ Kristi mọ lóde òni gẹgẹbí ó ti ri ní ìgbà ayé àwọn aposteli. Irú ìkórìíra kan náà tí ó mú kí àwọn ènìyàn kìgbe pè “kàn-an mọgi, kàn-an mọgi” ni ìgbàa nì. Òun kan náà ni yóò mú ki wọn ó ṣe inúnibíni sí àwọn aposteli, òun náà ni ó sì ń ṣiṣẹ nínú àwọn ọmọ àlàìgbọràn. Irú agbára yìí kan-náà tí ó ṣíṣẹ nígbà tí ọrọ Ọlọrun kò fẹsẹ múlẹ tí wọn ń gbé àwọn ènìyàn jù sẹwọn, tàbí lé wọn jù sẹhìn odi tàbí pa àwọn ènìyàn, òun náà ni yóò ṣe ìpinnu ìyà tó le koko fún àwọn tí a ti ṣe ìwádìí rẹ, agbara yìí kan-náà ti ó ṣe iṣẹ ibi ní Bartholomew àti Smithfield sì ń tẹ síwájú nínú iṣẹ ibi yìí ni ọkàn àwọn tí kò tí paradà di tuntun. Ìtàn fi ìdí rẹ múlẹ wípé títí láé ni ìjàkadì ti máa ń wà láàrin rere àti wìpé láàrin rògbòdìyàn àti idààmú yìí ni àwọn ọmọ Ọlọrun ti máa n polongo ìhìnrere.- The Acts of the Apostles. - pp. 84, 85.IIO 156.3

    Ijọ tí ó ṣẹku yóò fi ojú wi iná ìpọnjú àti ìbànújẹ. Àwọn tí ó ń pa òfin Ọlọrun àti ìgbàgbọ Jésù mọ yóò rí ìbínú dragoni àti àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ayé ni ó ti wà ni àbẹ àkóso Sátánì bẹẹni ó sì ti jẹ gàba lòrí àwọn ìjọ tí ó ti kọ òtítọ sílẹ ṣùgbọn ó mọ wípé òun kò tíì ní ẹkúnrẹrẹ àkóso ayé àyàfi ìgbà tí ó bá pa gbogbo àwọn tí ó kọ láti ṣe tirẹ run. Gẹgẹ bi ó ti ṣe mú kí àwọn orílè èdè abọrìṣà tí ó yí orílẹ èdè Ísírẹlì ká gbógun tì wọn láti pa wọn run bẹẹ gẹgẹ ní ọjọ iwàjú ni yóò ti se gbé agbára àwọn ènìyàn búburú dìdè láti pa àwọn ènìyàn Ọlọrun run. Gbogbo olùgbé orílẹ èdè ayé ni wọn yóò sọ fún wípé kí wọn máa bọwọ fún ófin àtọwọdá ènìyàn ju òfin ti Ọlọrun lọ. Gbogbo ènìyàn ni yóò sì dalẹ àwọn ti o ba jẹ olótìítọ sí Ọlọrun ati sí iṣẹ Rẹ lai yọ àwọn òbí, ẹbí, ará ati ọrẹ wọn silẹ.-Testimonies, Vol. 9, p. 231.IIO 157.1

    Ọjọ ìdánwò yìí kì yóò pẹ pupo mọ ti yíì fi ṣẹlẹ si gbogbo ènìyàn èyí ti wọn yóò fi ipá mú gbogbo ènìyàn láti máa pa Ọjọ Ìsinmi èké mọ. Ìjàkadì náà yóò wà láàrin ofin Ọlọrun àti ofin ti ènìyàn. Àwọn tí wọn ti ń darapọ mọ ayé àti àṣà rẹ diẹdiẹ ní àkókò yìí ni wọn yóò jọwọ ara wọn pátápátá sí agbára ayé ti àkókò náà nítorí pé wọn kò ní lè fi ara da àbùkù, ìtìjú, ìjunisẹwọn àti ikú. Ní àkókò yìí ni a óò mọ ìyàtọ láàrin ojúlówó àti ayédèrú.IIO 157.2

    Ọpọlọpọ àwọn ti wọn tí fi ìgbà kan ṣiṣẹ tọkàntara fún Ọlọrun ṣúgbọn tí wọn kò gba òdodo Kristi, ni wọn yóò pẹhìndà kúrò nínú ìgbàgbọ.-Prophets and Kings, p. 188.IIO 157.3

    Àfojúsùn kan ti a ní, èyí tí ó wà níwájú wa bí a ti ṣe ńtẹsíwájú nínú ìjàkadì wa láìwò ti àwọn ewu tí ó rọ mọọ gẹgẹbi ìjunisẹwọn, ìpàdánù ohun ìní wa tàbí ikú, òun ni láti dáàbò bo òfin Ọlọrun èyí tí àwọn ènìyàn ti sọ di asán nípa àwọn òfin ènìyàn.-Testimonies, Vol 5, p. 712.IIO 157.4

    Àkókò náà ń bọwa kánkán nígbàtí àwọn tí ó bá dúró láti dáàbò bo òtíìtọ yóò mọ nípa ìrírí wọn, ohun tí ó túmọ sí láti jẹ alábàápín ìyà Kristi. Olùpọnnilójú ńláa nì, ti iṣe eṣu sá mọ wípé àkókò diẹ ni òun ní, èyí tí òun yóò fi pàdánù agbára tí òun ní lórí ènìyàn tí Ọlọrun yóò sì gba agbára náà lọwọ òun, nítorí náà ń ṣe nì ó ń ṣiṣẹ takuntakun pẹlú gbogbo ìtànjẹ àìṣòdodo nínú àwọn ti yóò ṣegbé.IIO 158.1

    Àwọn ìgbàgbọ èké àti àṣìṣe ni ó jẹ gàba lóri òtíìtọ àti ìdájọ tòótọ àti gbogbo àwọn àgbára tí ó jẹ alátakò ni a túbọ ń ró ni àgbára.-Southern Watchman, Oct. 31, 1905.IIO 158.2

    Iṣẹ tí ijọ ti bàkù láti ṣiṣẹ nígbàti wọn wà ni ìfọkànbalẹ ni wọn yóò wa ṣe ni àkókò wàhálà àti ìpòrúùru ọkan. Àwọn ìkìlọ èyí tí ìbárẹ ayé ti palẹnumọ ni wọn ṣe lábẹ àtakò èyí tí ó gbóná janjan láti ọwọ àwọn alátakò ìgbàgbọ. Ní àkókò yìí, àwọn kògbóna-kòtutù, àwọn ti kò látinúdá, àwọn ti ipa wọn ń fi gbogbo ìgbà mú ìfàsẹhìn wà, ni wọn yóò kọ igbagbọ wọn sílẹ tí wọn yóò sì fi ara mọ àwọn ti ń tako òdodo, àwọn tí o jẹ wípé ọkàn wọn tí ń fàá sí tipẹtipẹ. Àwọn tí wọn yapa wọnyíí ni wọn yóò fi gbogbo àgbára wọn gbógun ti àwọn tí ó ti fìgbà kan jẹ arákùnrin wọn. Irú ọjọ báyìí ni ó wà níwájú wa èyí tí a dán ẹnìkọọkan nínú àwọn ọmọ ijọ wò. Ọpọlọpọ ni a fipá mú láti jẹrìí òtítọ, ọkàn wọn yóò sí wá kún ìbànújẹ àti ọgbẹ nígbàtí wọn ba rántí pé áwọn ti si ànfààní àti kéde òtítọ yìí lọ nígbàtí wọn ní oore ọfẹ rẹ ṣùgbọn tí àwọn kò lò iyẹn nígbà tí wọn bá ti lè mú kí àwọn mìíran dúró ní ilé ìdájọ àti níwájú àwọn ìgbìmọ.-Testimonies, Vol. 5, p. 463.IIO 158.3

    Gbogbo àwọn ẹlẹsìn ìgbàgbọ gbogbo tó kù kárí ayé ni wọn yóò máa fi ojú tìkà tẹgbin wo àwọn ẹgbẹ kékeré tí ó ń pa Ọjọ Ìsinmi Olọrun mọ àti òfin Rẹ gẹgẹ bí tí wọn yóò sì máa gbìmọ láti pa wọn run kúrò lórí ilẹ alààyè.-Testimonies, Vol. 5, p. 450.IIO 158.4

    Sátánì pàápàá yóò bínú gidigidi sí àwọn ẹgbẹ kéréje wọnyìí tí wọn kún fún irẹlẹ ṣùgbọn tí wọn kọ jálẹ láti darapọ mọ àṣà àti ìkọni ènìyàn yìí. Gbogbo àwọn ènìyàn tí wọn lààmi-laka ní gbogbo àgbayé gẹgẹ bí àwọn olórò, ìjọba, ọmọwé, àwọn olórí pípé ẹdá ni wọn yóò jọ fọwọsowọpọ láti máa ṣe ẹtánú àti àtakò àwọn ènìyàn wọnyí. Ohun gbogbo tí wọn ní ní wọn yóò sì lò láti gbógun tì wọn gẹgẹ bì ohùn wọn, gégé wọn, ìdúnkokò mọ ni, ni wọn yóò sì lò láti dojú wọn bolẹ. Nípa rírú ìbínú àwọn ènìyàn sókè nípa ọnà èkè àti àlùmọkọrọyí, níwọn ìgbà tí wọn kò rí ọnà láti takò Ọjọ Ìsinmi tòótọ làti inú Bíbélì nígbà náà ni wọn yóò wá ọnà ẹwẹ láti rii wípé ẹkọ òdì wọn wọ ọpọlọpọ àwọn ènìyàn létí tí àwọn ènìyàn wọnyí yóò sì faramọ òfin ìjọsìn tipátipá, tí wọn yóò gbé kalẹ. Ní ojú ogun yìí ni ìjà ìkẹhìn ńlá tí ó wà nínú ìjàkadì láàrin rere àti àṣiṣe ti fi ojú hàn (Testimonies, Vol. 5, pp. 450-451).IIO 159.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents