Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìrẹ̀lẹ̀

    Ní yíyan okùnrin àti obìnrin fún isé Rè, Olórun kìí bèèrè bóyá wón ní ìmò tàbí èbùn òrò síso tàbí orò ayé. Ó máa ń bèrè “Sé wón rìn nínú ìrèlè tí máa fi lé won ní ònà mi? Sé mo lè fi òrò mi sí enu won? Sé won á se asojú mi?.-Testimonies, Vol. 7, p. 144.IIO 246.2

    Nígbà tí a bá ń gbìyànjú láti ran àwon aláìní lówó, àwon tí a kò sílè, a kò gbodò ràn wón lówó nítorí iyì ara wa, nítorí ní síse eléyìí, a kò ní rí ohun kankan se tàbí gbà.- Testimonies, Vol. 6, p. 277.IIO 246.3

    Ohun tí yóò mú ìjo wa yege àti làmìlaka kòsí nínù ìse ariwo tàbi àsehàn sùgbón isé. Isé tí a fi ìrèlè, àdúrà àti ìsóra se.-Testimonies, Vol. 5, p. 130.IIO 246.4

    Ìtìjú tí ó wà nínú ìbìsubú jé ìbùkún láti jé kí a mò pé a yóò lè sisé Olórun, kìí sí ìrànwo rè.-Patriarch and Prophets, p. 633.IIO 246.5

    Èbùn olùgbé onírèlè ilé-kékeré wúlò fún isé ìhìnrere ojúlé-dójúlé, ó sì lè se isé púpò ju èbùn tí ó dárajù lo.-Testimonies, Vol. 9, pp. 37, 38.IIO 246.6

    Ohun tí òrun fé ni isé àwon òjísé tí wón gbé káàkiri gbogbo ayé lórúko Jésù tí Názárétì. Isé ń lá ni èyí, ará, a sì gbodò rè wá sílè lójoojúmó níwájú Olórun, Kí a má rò pé ogbón wa ni. A gbodò se isé náà pèlú ìtara. A kò gbodò gbàdúrà sí Olórun láti rè wá sílè, nítorípé ìgbà tí Olórun bá mú wa, yóò rè wá sílè ní ònà tí ó nífèẹ́. Sùgbón a gbodò lójoojúmó re ara wa sílè ní owó Olúwa. A gbodò sisé ìgbàlà wa pèlú ìbèrù. Olórun ni ó sì ń sisé nínú wa láti se ìfé Rè àti isé rere Rè. A gbodò fowósowópò pèlú Rè nígbà tí Ó bá ń sisé nínú wa.-Review and Herald, July 12, 1887.IIO 246.7

    A gbodò làkàkà láti wolé ní enu ònà tí ó há. Enu ònà yìí kìí yí pèlú ìròrùn. Kò ní gba àwon tí ó ń siyèméjì. A gbodò làkàkà nísinsìnyí fún ìgbé ayérayé pèlú agbára tí ó fi èbùn tí ó wà níwájú hàn. Kìí se owó, ilé tàbí ipò sùgbon nínú ìwà bí Krístì, tí yóò sílèkùn parádísè sílè níwájú wa. Kìí se àmúye tàbí ogbón ni yóò gba adé ìyè fún wa. Àwon onírèlè nínú ohun gbogbo tí ó ń fi Olórun se agbára won ni yóò gba èbùn yìí.-Southern Watchman, Apr, 16, 1903.IIO 247.1

    Nígbà tí ó bá dé láti ibi isé Olúwa, má yin ara re sùgbón gbé Jésù ga, gbé àgbélébùú Kálfárì ga.-Testimonies, Vol. 5, p. 596.IIO 247.2

    Kí a tó gbé wa ga, a gbodò ní ìrèlè láti fi ènìyàn sí ibi gíga níwájú ènìyàn, Olórun ma yan àwon òsìsé bíi Jòhánù Onítèbomi, tí ó yan ipò kékeré níwájú Olórun. Omo èyìn tí ó ní ìwà kékeré ni ó wúlò jùlo nínú isé Olórun. Ogbón òrun má ń bá won sepò, àwon tí ó wà láì gbé ara won ga bíkòse láti gba okàn là.-The Desire of Ages, p. 436.IIO 247.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents