Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ — KARÙN-ÚN ILÉ ỌLỌ́RUN JẸ́ GBỌ̀NGÀN ÌKỌ́NI

    Ìnílò Ti Wákàtí Yìí

    Ohun tí a nílò ní àsìkò yìí fún ìgbélárugẹ ti àwọn ìjọ ni iṣẹ́ dára dára tí àwọn alágbàṣe tó lóye láti mọ ohun tí ó tọ̀nà àti láti mú ẹ̀bùn dàgbà nínú ìjọ,- ẹ̀bùn tí a lè kọ́ fún ìlò adarí. Àkójọpọ̀ àgbékalẹ̀ fún ìgbà ṣíṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ wà láti lọ sínú àwọn ìjọ ọ wa, títóbi tàbí kékeré, láti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́ fún ìmúdàgbà sókè ti ìjọ, àti pẹ̀lú fún aláìgbàgbọ́. Ìkọ́ni, ẹ̀kọ́ ni a nílo. Àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú u ṣíṣe àbẹ̀wò sínú ìjọ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní àwọn ìlànà bí a ṣe lè ṣe iṣẹ́ àjíhìnrere.-Testimonies,vol.9, p.117.IIO 58.1

    Ọlọ́run ń retí kí ìjọ ọ Rẹ̀ kí ó kó àwọn ọmọ ìjọ níjánu kí ó sì mú wọn yẹ fún iṣẹ́ ìlàlóye aráye. A gbọdọ̀ fún wọn ní ẹ̀kọ́ tí ó máa yọrísí pípèsè fún (ọgọ́rùn ún ènìyàn) tí yóò mú jáde sí ìpààrọ̀ àwọn ẹ̀bùn tí ó níye lórí. Nípa lílo àwọn ẹ̀bùn yìí,ènìyàn yóò lè gbèrú tí wọn yóò sì lè múra láti dí àlàfo àwọn ipò ti ìgbẹ́kẹ̀lé àti agbára àti láti di ohun mímọ́ mú, àwọn ìpìlẹ̀ tí kò díbàjẹ́, Báyì í ohun ń lá tí ó dára ni áò ṣe láṣepé fún olùkọ̀ ọ wa..- Testimonies, vol.6, pp.431,432.IIO 58.2

    Olúkúlùkù òṣìṣẹ́ ni ó gbọdọ̀ lóye tó kúnjú òṣùwọ̀n. Lẹ́hìn náà ni gíga, ní èrò tí ó jinlẹ̀ ó lè fi òtítọ́ lọ̀ bí ó ṣe wà nínú u Jésù.- Testimonies, vol.7, p.70.IIO 58.3

    Kò gbọdọ̀ sí ìdádúró nínú ìgbìyànjú tí a gbékalẹ̀ dáadáa láti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ.- Testimonies,vol.9,p.119. Ìrànlọ́wọ́ ń lá tí a lè ṣe fún àwọn ènìyàn ni láti kọ́ wọn láti ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run, kí wọn sì gbẹ́kẹ̀ Lé e, kì í sì í ṣe àwọn àlúfáà.- Testimonies, vol.7,p.19.IIO 58.4

    Ó hàn gbangba pé gbogbo àwọn ìwàásù tí wọ́n ti wà kò tíì pèsè àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ní ìfara ẹni rúbọ lọ́pọ̀ yanturu.A ní láti kíyesí n ǹkan yìí bí èyí tí ó ní àyọrísí tí ó lágbára jùlọ.Ayérayé Ọjọ́ ọ̀la a wà wà nínú ewu.Igi ìjọ Ọlọ́run ń rẹwé nítorí pé wọ́n ti bàkù láti lo àwọn ẹ̀bùn nínú títan ìmọ́lẹ̀ kalẹ̀. Ẹ̀kọ́ tí ó gba ìṣọ́ra ni wọ́n gbọdọ̀ fún èyí tí yóò jẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ olùkọ́ àgbà kí gbogbo ènìyàn le è lo ìmọ́lẹ̀ tí a fifún wọn.- Testimonies, vol.6, p.431.IIO 58.5

    Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwáásù ṣùgbọ́n ǹ jẹ́ a ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́ fún àwọn tí Krístì kú fún? Ǹ jẹ́ a ti la ọ̀nà iṣẹ́ kalẹ̀ tí a sì gbé síwájú u wọn ní ọ̀nà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò ṣe rí `idí tí wọn yóò fi kópa nínú iṣẹ́ náà?.- Testimonies, vol.6,p.431.IIO 59.1

    Nípa kíkọ́ àti ìṣẹ ni àwọn ènìyàn fi lè yẹ láti pàdé ohun tí yóò bá wọn lójijì tí ó lè dìde; àti pé àgbékalẹ̀ tó m’ọ́gbọ́n wá ni a nílò láti fi olúkúlùkù sí àyíká tí ó bá yẹ, kí ó ba à lè ní ìrírí tí yóò mu wà ní ìbámu láti gbé ẹrù náà. Testimonies, vol.9, p.221.IIO 59.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents