Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Nípa Kálàmù àti Ohùn

    Pẹ̀lú u kálàmù àti ohùn polongo pé Jesu gbé láti ṣe alágbàwí fùn wa. Darapọ̀ pẹ̀lú òṣìṣẹ́ Olùkọ́ Àgbà, tẹ̀lé ìṣẹ́ra -ẹni Olugbala nípa ìrìn-àjò ìfẹ́ ẹ RẸ̀ sí ayé.- Review and Herald, Jan 24, 1893.IIO 130.3

    Àwọn díẹ̀ yóò ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà kan àti àwọn díẹ̀ ní ọ̀nà mìíràn bí Ọlọ́run yóò ṣe pè tí yóò sì darí i wọn. Ṣùgbọ́n gbogbo o wọn ni ó ní láti gbìyànjú papọ̀ kí wọn sì wá láti mú kí gbogbo iṣẹ́ náà wà ní pípé. Pẹ̀lú u kálàmù àti ohùn un wọn ní láti ṣiṣẹ́ fún-Un,- Testimonies, vol.9, p.26.IIO 130.4

    Wọ́n kan Kristi mọ́ àgbélébù ú, - sọ ọ́ síta, gbàdúrà a rẹ̀, kọ ọ́ lórin, yóò sì fọ́ yóò sì jèrè àwọn ọkàn.- Testimonies, vol.6, p.67.IIO 130.5

    Kálàmù jẹ́ agbára ní ọwọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ náà wà ní orí i pẹpẹ àwọn ọkàn-an wọn, àti ẹni tí ó ní ìtara ìmọ̀ fún Ọlọrun, tí ó sì dọ́gba pẹ̀lú ìdájọ́ tí ó yè kooro. Kálàmù, ni a kìbọ inú ìsun òtítọ́ mímọ́ náà, tí a lè rán ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ ẹ RẸ̀ sí àwọn orígun ayé, èyí tí yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ ẹ rẹ̀ padà sẹ́hìn, tí yóò fikún agbára titun, tí yóò fi kún ìmọ́lẹ̀ tí ó ní láti tàn káàkiri níbi gbogbo.- Life Sketches, p.214.IIO 130.6

    Àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run kò gbọdọ̀ fi gbogbo agbára wọn wàásù, kí wọn sì jẹ́ kí iṣẹ́ náà parí síbẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ kọ́ awọn ọmọ ìjọ láti mú àti láti mú àṣeyọrí tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀ka iṣẹ́ yìí. (Ìwé ajíhìnrere), èyí tí ó dàbí ìwé ìléwọ́ ọ wa àti ẹgbẹ́ ajíhìnrere tí ó sì dàbí i àyíká a kẹ̀ẹ̀kẹ́ nínú àyíká a kẹ̀ẹ̀kẹ́.Yiyipo ti ayika kẹ̀ẹ̀kẹ́ ti inú ń mú ìlera àti agbára bá ayika a kẹ̀ẹ̀kẹ́ ẹ ti ìta.Jẹ́ kí àyíká a kẹ̀ẹ̀kẹ́ ti inú dáwọ́ iṣẹ́ dúró, a yóò sì rí àyọrisí i rẹ̀ nínú ìdínkù ìgbé ayé àti ẹgbẹ́ tí ó ń pín ìwé ìwàásù. - Review and Herald, June 10, 1880. IIO 131.1

    Máṣe káárẹ̀ nínú ìṣọ́ra ti iṣẹ́ ìhìnrere. Iṣẹ́ tí gbogbo o wa lè kópa nínú u rẹ̀ ni, tí a bá fẹ́ ṣùgbọ́n tí a bá ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Kí ó tó di pé o kọ ìwé fún ìwadì í, gbé ọkàn-àn rẹ sókè sí Ọlọ́run pẹ̀lú àdúrà nígbà gbogbo pé kí o le ṣe àṣeyọrí nínú u kíkó àwọn ẹ̀ka èyí tí a yóò lọ́ sínú àjàrà tòótọ́, tí yóò sì so èso fún ògo Ọlọ́run. Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí, ni yóò má a kọ́ ẹ̀kọ́ láarin ara a wọn léra léra bí i àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà a Olúwa. - Review and Herald, June 10. 1880.IIO 131.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents