Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Àṣìṣe tí ó burú jáì

  Àṣìṣe tí ó burú jáì ni láti rò pé iṣẹ ìjèrè ọkàn dúró lórí i iṣẹ́ iranṣẹ. Àwọn onígbàgbọ́ tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀, tí a ya sí mímọ́ lórí àwọn tí Oluwa ọgbà àjàra gbé àjàgà àwọn ọkàn fún ni a ní láti gbà níyànjú nípa awọn eniyan ti Oluwa ti gbé iṣẹ títóbi yì í lé lọ́wọ́.Awọn ti wọn duro nípò adarí nínú ijọ Ọlọrun ní láti mọ̀ pé iṣẹ iranṣẹ ti Olugbala ni a fifún gbogbo awọn ti ó gbágbọ́ nínú orúkọ ọ Rẹ̀.Ọlọrun yóò rán lọ sínu ọgbà àjàrà a Rẹ̀ ọpọlọpọ tí kò tí ì fi ara wọn jì fún iṣẹ́ iranṣẹ nípa ìgbọ́wọ́ lé lórí.- The Acts of The Apostles, p.110.IIO 68.5

  Èrò o wípé alufaa ni ó gbọdọ̀ ru àwọn ìṣòro kí ó sì ṣe gbogbo iṣẹ jẹ́ àṣìṣe tí ó lágbára. Iṣẹ́ àṣejù àti ìsọni dàláìsàn, lè mú u lọ sí isà òkú, nigba ti, ó bá pín ìṣòro yìí bi Oluwa ṣe làá sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí ó yè. Pé kí a lè pín iṣoro, a ní láti dá àwọn ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa awọn tí ó lè kọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lati tẹ̀lé Krístì kí wọn sì ṣiṣẹ́ bí Ó ṣe ṣiṣẹ́.-Testimonies,vol.6, p.435.IIO 68.6

  Ki alufaa máṣe rò pé iṣẹ́ òun ni láti ṣọ gbogbo ọ̀rọ̀ àti gbogbo iṣẹ́ ati gbogbo àdúrà;ó gbọdọ̀ kọ́ àwọn olùrànlọ́wọ́ nínú ijọ kọ̀ọ̀kan.Jẹ ki àwọn tó yàtọ̀ lákọ́kọ́ darí àwọn ìpàdé, àti fífún ni ní Bíbélì kíkà;nipa ṣíṣe báyìí wọn á le pè wọ́n láti lo àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fifun wọn, ati bakan naa wọn á gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́.-Gospel Workers, P.197.IIO 69.1

  Awọn alufaa kò gbọdọ ṣe iṣẹ́ tí ó wà fún ijọ,eyi ti o le mu aarẹ ba wọn, ati pe yóò mú ìdènà bá awọn mìíràn lati ṣe iṣẹ́ ẹ wọn. Wọ́n gbọdọ kọ́ awọn ọmọ ijọ bí wọ́n ṣe le ṣiṣẹ́ nínú ijọ ati agbègbè.- Historical Sketches, p.291.IIO 69.2

  Nigba ti a bá gbìyànjú lati fi igbagbọ ọ wa lọ àwọn aláìgbàgbọ́, awọn ọmọ ijọ nigba miran má a ń takété, bí ìgbà tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ tí kò nínú dídùn, àti pé gbogbo ìṣòro wà lórí àlùfáà. Fún ìdí èyí iṣẹ̀ ẹ ti awọn alufaa nígbà míìran má a ń sèso dídára kékeré. Gospel Workers, p.196.IIO 69.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents