Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Àfiwe Tí ó múná Dóko

    Àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ àánú u RẸ̀ yàtọ̀ láti bá àwọn olùgbọ́ ọ RẸ̀ mu. Ó mọ̀ “bí a ṣe le sọ̀rọ̀ ní àsìkò sí ẹni tí àárẹ̀ ẹ́ mú,” nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a tú jáde sórí ahọ́n-ọn RẸ̀, pé kí ó lè fi àwọn ìṣúra ti òtítọ́ han àwọn ènìyàn lọ́nà tí ó rọrùn. Ó ní ọgbọ́n láti bá àwọn ọlọ́kàn búburú pàdé, kí ó sì yà wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ tí yóò gba ìfarabalẹ̀ ẹ wọn. Nípa òye Ó dé ọkàn. Àwọn àpẹẹrẹ ẹ RẸ̀ ni ó mú jáde láti ara àwọn n nkàn ìgbé ayé ojoojúmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rọrùn, wọ́n ní ìyanu tí ó jinlẹ̀ fún ìtumọ̀. Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, ewéko ìgbẹ́, àwọn èso, olùṣọ́ àgùtàn àti àgùtàn, - pẹ̀lú u gbogbo àwọn ohun tí a rí Krístì ṣe àpẹẹrẹ òtítọ́ tí kì í kú, àti pé nígbẹ̀hìn, nígbàtí àwọn olùgbọ́ ọ RẸ̀ ṣe alábàápàdé láti rí àwọn ohun tí a dá, wọ́n mú àwọn ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀ wá sí ìrántí. Àwọn àpẹẹrẹ Kristi má a ń ṣe àwítúnwí àwọn ẹ̀kọ́ ọ RẸ̀ lemọ́lẹmọ́. - The Desire of Ages, p.254.IIO 125.2

    Àwọn àpóstélì gbìyànjú láti fi ìmọ̀ Ẹlẹ́dàá àti ti ọmọ ọ RẸ̀, Olùgbàlà ìran ènìyàn kọ́ àwọn abọ̀rìṣà. Lákọ́kọ́ ná, wọ́n fi ìfarabalẹ̀ ẹ wọn sí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun, - oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀, ẹwà a títò lẹ́sẹẹsẹ àwọn àsìkò tí ó ń ṣe tẹ̀lé n tẹle, àwọn òkè tí ó fi yìnyín borí, àwọn igi gíga, àti àwọn onírúurú ohun ẹ̀dá tí ó yani lẹ́nu, tí ó fi ọgbọ́n èyí tí ó kọjá òye eniyan hàn. Nípa àwọn iṣẹ́ Alágbára jùlọ, àwọn àpóstélì darí ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ láti ṣe àṣàrò lórí Alákóso ayé tí ó lágbára. - The Acts of the Apostles, p.180.IIO 125.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents