Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORÍ — KẸ́TA ÀWỌN IPÒ LÁARIN ÀWỌN ÈNÌYÀN ỌLỌ́RUN

  Ẹ̀mí Ajíhìnrere Kò Sí.

  Ẹ̀mí iṣẹ́ ajihinrere Ọlọrun kò wọ́pọ̀ nínú oníretí i bíbọ̀ Jésù tí ó ń pa ọjọ́ sátidé mọ́. Tí àwọn ajíhìnrere àti àwọn ènìyàn bá ń rí kóríyá bí ó ṣe tọ́ àti bí ó ṣe yẹ, wọn kò ní má a dágunlá bẹ́ ẹ̀, nígba tí Ọlọ́run ti bu ọlá fún wọn nípa mímú wọn jẹ́ orísun ìṣúra òfin rẹ̀, nípa kíkọ wọ́n sí àyà àti ọkàn an wọn.- Testimonies, vol.3, p.202.IIO 35.1

  Ẹ̀mí ajíhìnrere tòótọ́ ti fi àwọn ìjọ tí ó ń fi iṣẹ́ náà yangàn sílẹ̀; ọkàn an wọn kò gbiná pẹ̀lú ìfẹ́ fún àwọn ọkàn, àti fífẹ́ láti darí wọn sínú agbo Krístì. A nílò òṣìṣẹ́ tí ó ní ìtara. Ṣé kò sí àwọn tí ó má a dáhùn sí igbe tí ó ń gòkè láti orígun kọ̀ọ̀kan, “Ẹ wá láti wá ràn wá lọ́wọ́”?- Testimonies, vol.4, p.156.IIO 35.2

  A fihán mí pé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, a jẹ́ alábùkù.Iṣẹ́ ẹ wa kò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa.Ìgbàgbọ́ ọ wa fihàn pé à ń gbé ní abẹ́ ìpolongo ìhìnrere tí ó lọ́wọ̀ ju àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì tí a tí fun ènìyàn alára íkú. Síbẹ̀ ní fífojú wo òótọ́ yìí, akitiyan wa, ìtara, ẹ̀mí ìfara ẹni rúbọ wa, kò ṣe é fiwé ra pẹ̀lú ìwà ti i iṣẹ́. A gbọdọ̀ jí dìde kúrò nínú òkú, àti pé Krístì yóò fún wa ní ìyè.-Testimonies, vol.2.p.114.IIO 35.3

  Ọkàn mí gbọgbẹ́ nígbà tí mo ro bí àwọn ìjọ wa ṣe fi ojú yẹpẹrẹ wo bí wọn ò ṣe fi tọ̀wọ̀ tọ̀wọ̀ jíhìn fún Ọlọ́run. Kìí ṣe ajíhìnrere nìkan ni ó jẹ́ ọmọ ogun, ṣùgbọ́n ọkùnrin àti obìnrin kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ nínú ọmọ ogun Krístì: àti pé ṣé wọ́n ṣetáń àti gba owó iṣẹ́ ọmọ ogun, gẹ́gẹ́ bí Krístì ṣe fún wọn ní àpẹẹrẹ nínú ayé ìṣẹ́ra ẹni wọ̀ ní àwọn ìjọ lápapọ̀ fihàn? Wọ́n lè fi owó tó níye lórí sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fa ara wọn sẹ́hìn.- General Conference Bulletin, 1893, p.131.IIO 35.4

  Púpọ̀ nínú àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní àtẹ̀lé e Krístì kò ní ìmọ̀lára ìnira fún àwọn ọkàn ju ti ayé lọ: ìfẹ́kúfẹ̀ ẹ́ ojú,àti ìgbéraga ti ayé, ìfẹ́ àṣehàn,ìfẹ́ sí ìdẹ̀ra, ya àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní onígbàgbọ́ sọ́tọ̀ nínú Ọlọ́run àti pé ẹ̀mí ajíhìnrere jẹ jáde nínú àwọn díẹ̀. Kíni a lè ṣè láti la ojú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Síónì,kí a sì jẹ́ kí àwọn àgàbàgebè wárìrì?-General Conference Bulletin,1893, p.132.IIO 35.5

  Ẹgbẹ́ kan wà tí Meroz ń ṣasojú u wọn. Wọn kò gba ẹ̀mí ajíhìnrere lọ́kàn-an wọn.Ìpè si iṣẹ́ ajíhìnre ní ilẹ̀ òkèèrè kò mú wọn ta gìrì.Irú ìṣirò wo ni irú àwọn wọ̀nyí yóò ṣe fún Ọlọ́run, àwọn tí kò ṣe ohun kan ní ọ̀nà-an RẸ̀,- kò sí ohun kan láti fí jèrè àwọn ọkàn fún Krístì? Irúfẹ́ àwọn wọ̀nyí yóò gbọ́ ohùn pé èmi kò mọ̀ ọ́ rí, “Ìwọ ẹni búburú àti ìmẹ́lẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀,” Historical Sketches, p.290.IIO 36.1

  Gẹ́gẹ́ bí afiwe ìbàkù rẹ nínu ṣiṣe iṣẹ́ Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí àǹfààní ti a fun ọ, A tọ́ka à mí sí ọ̀rọ̀ yìí pé: “Ègún ni fún Meroz, báyìí ni ángẹ́lì Olúwa sọ, ègún kíkorò ni fún ẹ̀yin olùgbé ibẹ̀; nítorí pé wọn kò wá láti ran Olúwa lọ́wọ́, láti ran Olúwa lọ́wọ́ ní títako alágbára”.-Testimonies, vol.2, p.247.IIO 36.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents