Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ẹ̀rí Ìrírí Ẹnìkọọkan

    Gẹ́gẹ bí ọmọlẹ́hìn Kírísítì a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀mí wa ó jẹ́ ìrànlọ̀wọ́ àti móríyá fún ara wa nínú ìgbé ayé ìgbàgbọ́ wa. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a gbọ́dọ̀ maa sọ̀rọ̀ nínú àwọn ìrírí wa tí ó ṣọ̀wọ́n.- Christ’s Object Lessons, p. 338.IIO 212.4

    Ìjọ nílò àwọn ẹ̀rí ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun tí ó múnádóko láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ìjọ tí ó ń gbàdúrà nígbà gbogbo. Àwọn ẹ̀rí tí kò ní ìtumọ̀ tí kò ní ìfarahàn Kírísítì kò leè ran àwọn ènìyan lọ́wọ́. Tí ìgbàgbọ́, ìmọ́lẹ̀ òun ìyè bá kún inú ayé àwọn tí ó pe ara wọn ní ọmọ Ọlọ́run, irú ẹ̀rí àgbàyanu báwọ̀nyìí ni àwọn tí wọ́n wá gbọ́ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà yóò gbọ́! Àti wí pé tá ni yóò lè ka àwọn ọkàn tí a ó jèrè fún Kírísítì.-Testimonies, Vol. 6, p. 64.IIO 212.5

    Ìjẹ́wọ́ òtítọ́ Rẹ̀ nínú ayé wa ní ọ̀nà tó tọ́ jùlọ tí a lè gbà fi Kírísítì hàn gbogbo ayé. Ó yẹ kí a gba oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a tí fihàn nípasẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìgbaanì ṣùgbọ́n ìjẹ́rì ìrírí wa ní ọ̀nà tí ó dára jùlọ tí a lè fi ṣe eléyìí. A jẹ́ ẹlẹ́rì fún Ọlọ́run bí a ṣe ń ṣe àfihàn agbára Ọlọ́run èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ayé wa. Bí ìgbé ayé wa ṣe yàtọ̀ sí ara wọn bẹ́ẹ̀ni àwọn ìrírí wa ṣe yàtọ̀. Ọlọ́run ń fẹ́ kí olúkúlúkù wa máa yin Òun, kódà nínú ìyàtọ̀ tàbí àìdọ́gba wa. Gbígbà láti máa yìn-Ín lógo nínú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bíi Kírísítì jẹ́ àgbára tí a kò lée fọwọ́ rọ́ sẹ́hìn, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ọkàn.-The Ministry of Healing, p. 100.IIO 213.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents