Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìsinmi Àti Ìjíròrò

    Òsìsé Olórun gbodò ní ìmò bí wón se gbodò sisé àti bi wọn ṣe le sinmi. Lónìí, ó yẹ kí àwon tí Olórun ti yàn gbóràn sí òfin Kristi pé kí won ó yapa, kí won sì sinmi fún ìgbà díè. Òpòlopò èmí ni ó ti lo, nítorí àì tétí sí òfin yìí, èyí kò ye kí ó rí bé ẹ̀. Bí ó tilè jé pé ìkórè pò, tí alágbàse kò sì tó, a kò rí èrè kankan tí ìlera wa tàbí èmí bá sòfò. Òpòlopò àwon òsìsé tí ó ti rè lópò, tí wón ní ìtara nígbà tí wón bá rí bí isé tí ó wà láti se ti pò tó àti bí ohun tí wón lè se ti kéré tó. Bí wón ti wá agbára láti se púpò síi — àwon wọ̀nyí ni Jésù ń so fún wípé, “Kí ó yára lo sí aginjù, kí won kó sì sinmi fún ìgbà díè.-“Review and Herald, Nov. 7, 1893.IIO 249.1

    Ayé Krìsténì kò wà pèlú isé àsekú-dórógbó tàbí isé ìsìn tí kò lópin. Kristeni gbodò sisé taratara fún ìgbàlà àwon tí ó sonù, wón tún gbodò fi àyè sílè fún àsàrò, àdúrà àti kíkó òrò Olórun. Kìí se kí a má a fi gbogbo ìgbà sisé tàbí seré, nítorí nínú èyí, ìbòwó fún ara eni kò ní sí, ìpalára ẹ̀mí àti ọkàn yóò sì wà.IIO 249.2

    Gbogbo àwon tó wà lábé èkó Olórun nílò láti ní àkókò ìparóró láti bá ara won sòrò. A kò gbodò rìn pèlú won ní ìbáré ayé, isé àti ìwà ayé, wón sì gbodò ní ìbásepò pèlú Olórun kí ó sòrò sí okàn wa lénì kòòkan, nígbàtí gbogbo ohun bá wà ní ìpanumó, tí ó wà níbi ìparóró okàn jé kí a gbó ohùn Olórun yékéyéké — “Má mikàn, kí o sì mò pé èmi ni Olórun”. Èyí ni ìmúra tí ó jù láti se isé Olórun. Nínú gbogbo rúkèrúdò ayé, àní tí e bá ní ìmúlárayá yìí ni ìmólè àti àlàáfíà gégé bí olùkejì ká, yóò rí okun ara àti èmí gbà. Ayé rè yóò má mí èémí dídùn jádè, yóò má fi agbára òrun hàn tí ó má tu okàn omo ènìyàn.-The Ministry of Healing, p. 58.IIO 249.3

    Olórun fé láti fún àwon omo Rè lókun pèlú èmí-mímó, kí a tèwón bomi nínú ìfé Rè. Kò sí ìwúlò àwon èmí-mímó nínú ìjo. Léyìn ìgbà tí Jésù jíǹde, èmí-mímó bà sí orí àwon omo èyìn tí ó ń sónà, gbàdúrà, tí ó sì gbàgbó láti dínkù pèlú agbára tí ó to okàn lo. Ní ojó iwájú, ayé gbodò rí ìmólè nínú ògo Olórun. Ipa láti òrun ni láti lo iwájú nípasè àwon tí a yàn nípa òtító. Èmí mímó ní láti sisé nínú okàn omo ènìyàn ní gbígba àwọn ohun ti Olórun kí a sì fihan omo ènìyàn.-Southern Watchman, p. 5, 1905.IIO 249.4

    Lótító ni pé ní ìgbà ìkehìn, nígba ti isé Olórun nínú ayé yìí bá parí, ìtara ìgbìyànjú ti àwọn onígbàgbọ́ tí a yà sí mímọ́ lábẹ́ ìtọ́ni Ẹ̀mí Mímọ́ , ni ó gbọdọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ nípa ojú rere láti ọ̀run.Lábẹ́ òye òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò tí ó ń rọ̀ ní àríwá ìlà oòrùn ní àsìkò ohun ọ̀gbìn àti àsìkò ìkórè, àwọn wòólì Hébérù sàsọtẹ́lẹ̀ nípa títú oore ọ̀fẹ́ ọ̀run tí kò lẹ́gbẹ́ sórí àwọn ìjọ Ọlọ́run.Títú Ẹ̀mí jáde nígbà ayé àwọn àpóstélì ni ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò, àyọrísí èyí tí ó lógo.Títí di òpin ayé, ìfarahàn Ẹ̀mí ni ó ní láti salábágbé pẹ̀lú ìjọ tòótọ́.- The Acts of The Apostles, pp.54,55.IIO 249.5

    Títú Ẹ̀mí jáde nígbà ayé àwọn àpóstélì ni ó jẹ́ “àkọ́rọ̀ òjò”, àyorísí i rẹ̀ sì jẹ́ ológo. Sùgbọ́n òjò àròkúrò ni yóò wà lọ́pọ̀lọpọ̀. Kínni ìlérí tí a ṣe fún àwọn tí wọ́n ń gbé ní àsìkò ìkẹyìn yìí?- “Yí sí ilé agbára,èyin ẹlẹ́wọ̀n tí ó ní ìrètí;lónìí pàápàá ni mo sọ pé Èmi yóò fún —un yín ní ìlọ́po méjì.” Ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa òjò ní àsìkò òjò àrọ̀kúrò; kí Ọlọ́run le è mú kí ojú ọ̀run mọ́lẹ̀ kí ó sì rọ òjò, sí orí i koríko kọ̀ọ̀kan ní orí ilẹ̀”.- Testimonies, vol.8, p.21.IIO 249.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents