Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí ó Wọni Lọ́kàn.

    Níǹú àwọn ìran òru ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wọni lọ́kan kọjá níwájú ù mi. Mo rí iná tí ó ṣùjọ tí ó sì tóbi púpọ̀ láarin àwọn ilé ń lá ń lá tí ó lẹ́wà, tí wọ́n fa ìparun ẹsẹ̀kẹsẹ̀ bá ara a wọn. Mo gbọ́ tí ẹnìkan sọ pé. “A mọ̀ ìdájọ́ Ọlọrun ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n a kò mọ̀ pé yóò dé kánkán”. Àwọn mìíràn pẹ̀lú àwọn ohùn ìrora ń sọ “Ó mọ̀! Kín ló dé tí o kò sọ fún wa? A kò mọ̀!” Ní ẹ̀gbẹ̀ ẹ̀gbẹ́ ni mo ti ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tí ó jọra a wọn tí wọ́n ń sọ.IIO 111.1

    Nínú ìpọ́njú ń lá ni Mo ti tají. Mo sì tún padà láti sùn, ó sì dàbí i pé Mo wà ní àwùjọ ń lá. Ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ ń bá àwujọ kan sọ̀rọ̀ níwájú ẹni tí a tẹ àwòrán ayé sí. Ó ní àwòrán ayé tí ó fi ọgbà àjàrà Ọlọ́run hàn, èyí tí a ní láti ro oko o rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run ti ń tàn sórí ẹnìkẹni, tí ó ní láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn mìíràn. Àwọn iná náà ní láti rú sókè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi àti ní ara àwọn ìmọ́lẹ̀ yìí ni a yóò ti rú àwọn ìmọ́lẹ̀ mìíràn sókè.IIO 112.1

    Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ń sọ léra léra: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé: Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín la yóò fi mú u dùn? Kò ní láárí mọ́, bíkòse pé kí a dàá nù kí ó sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn ènìyàn. Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè farasin. Bẹ́ẹ̀ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì fi sábẹ́ òsùwọ̀n, bíkòse lórí ọ̀pá a fìtílà; á sì fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ẹ yín mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọn lè má a rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn kí ó lè yin Bàbá a yín tí ń bẹ lí ọ̀run lógo”. Matt.5 : 13-16.IIO 112.2

    Mo rí àwọn ìṣàn tí má a ńtàn láti àwọn ìlú àti ìletò, àti láti àwọn ibi gíga àti àwọn ìsàlẹ̀ ti ilè ayé. Wọ́n gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fún ìdí èyí wọ́n ṣe ohun ìrántí fún-Un ní gbogbo ìlú àti ìletò. Wọ́n polongo òtítọ́ ọ RẸ̀ jákè jádò ayé.- Testimonies, vol.9, pp.28,29. IIO 112.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents