Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Abala Ìkẹhìn Nínú Eré Orí Ìtàgé Náà.

    Pàṣipàrọ èyi tí àwọn ènìyàn ti ṣe nipasẹ àse eniyan lásán, éyí ti wọn ti fi ofin eniyan dipo ofin Ọlọrun nipa fifi ọjọ kin-in-ni ọsẹ rọpo Ọjọ Isinmi tootọ ti inu Bibeli ni abala ikẹhin ninu eré orí ìtàgé. Olúwa yóò dìde nínú ọlá ńlá Rẹ láti mi ayé tìtì. Yóò jáde kúro ní ibùgbé Rẹ lati fi ìyà jẹ awọn olùgbé ayé nítorì ẹṣẹ ẹ wọn.-Testimonies, Vol. 7, p. 141.IIO 160.2

    Nígbà ti orilẹ èdè wa yóò kẹhìn si àgbékàlẹ ìjọba yóò ṣe òfin èyí ti yóò sọ ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ di mímọ, àwọn alátakò ẹwẹ yóò fọwọsowọpọ pẹlú ìkọni àti àgbékalẹ Ijọ Aguda, yóò si wá dàbi ìgbà tí a gbé agbára ìjọba ni kíkún wọ ẹnìkan èyí tí ó ti ń wọnà fún irú ànfààní bẹẹ láti wà ní irú ipò bẹẹ.-Testimonies, Vol. 5, p. 712.IIO 160.3

    Nípasẹ ṣiṣe òfin láti fipá mú àgbékalẹ Ijọ Aguda láti lè fẹsẹ múlẹ, èyí tí ó tako àgbékalẹ àti ìlànà Ọlọrun, nígbà náà ni orílẹ èdè wa yóò wá já ara rẹ gbà kúrò pátàpátà nínú òdodo Ọlọrun. Nígbà tí àwọn alátakò yìí (Protestantism) báa na owó wọn làti fọwọsowọpọ pẹlú ẹmí òkùnkùn tíí ṣe abókùúsọrọ lẹhìn ti wọn bá ti wà lábẹ àkóso àwọn agbara ìṣọkan mẹta nígbà náà ni orílẹ èdè wa yóò wá kẹhin sí àwọn àgbékálẹ tí ó wà nínúú òfin wọn gẹgẹbí ìjọba àti gẹgẹbí àwọn alátakò wọn yóò wá sì fàyè gba ìtànkálẹ ẹkọ òdì ti Ijọ Agùda nígbà yíí ni kí á mọ wípé àkókò ti tó fún Sátánì láti ṣe iṣẹẹ rẹ àti wipe òpin àkókò ti súnmọ tòsí.-Testimonies, Vol. 5, p. 451.IIO 161.1

    Àkókò ti súnmọ tòsi nígbà ti àwa náà gẹgẹbì àwọn ọmọ ẹhìn Kristi àkọkọ yóò sá àsálà fún ẹmí wa nípa fífi ara pamọ sí ibi tí àwọn ènìyàn kìí gbé. Gẹgẹbí ìkọlù àwọn Roomu sí Jerusalemu ṣe jẹ àmìn sísà lọ sí Jùdíà bẹẹ gẹgẹ ni yóò rí nígbàtí orílẹ èdè wa bá bẹrẹ sí ní fi ipá mú ni láti gba òfin ọjọ ìsinmi ti ọjọ kìn-ín-nì ọsẹ tíí ṣe ti Ijọ Àgùdà. Nígbà náà ni àkókò tó fún wa láti bẹrẹ sí ní fi ìlú ńlá-ńlá sílẹ ní ìmurasilẹ láti bẹrẹ si níí gbé ni àwọn ìletò kéréje-kéréje àti láàrín-in àwọn àpáta gbogbo.-Testimonies, Vol. 5, pp. 464-465.IIO 161.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents