Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ KẸRÌNDÍNLÓGÚN GBÍGBÒÒRÒ ÌJỌ

    Eto atorunwa

    Kìí ṣe èrò Ọlọrun ní wípé kí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ó dárogún sí ojúkan ní àwọn ìlú ńlá-ńlá. Àwon omoléhìn Kristi ní asojú Rè lórí ilè ayé, èrò Rè sì ní kí won ó túká káàkiri orílè-èdè ayé gbogbo, ní àwon ìlú ńlá-ńlá, ìlú kéréje-kéréje àti ní àwon abúle tàbí ìletò gégébí ìmólè láàrín òkùnkùn ayé.-Testimonies, Vol. 8, p. 244.IIO 178.1

    Èrò dídúró sójúkan tàbí lílọ sí àgbègbè orísirísi níbi tí ìjo kò tí fesè múlé tàbí ní ìpa lóri àwon ènìyàn tí a sì wá mú àǹfaàni tí ó ye fún òpòlopò agbègbè wá sí agbègbè wá sí agbègbè kan dàbí enití à ń pa ìmólè ní àwon ìbi tí Olórun tí ń fé kí ó tàn.-Testimonies, Vol. 2, p. 633.IIO 178.2

    Tí ìjo Olórun bá ń mú ìfé Rè se nígbà náà ní ìmólè yóò tàn sórí àwon tó jókò nínú òkùnkùn àti ní agbègbè òjìji ikú. Kàkà kí á kàn pò bí éesú lójú kan náa kí á wá máa yera fún ojúse wa kí á sì máa yípo lójú kàn-náà, kí àwon omo ìjo ó kúkú túká sí orílè-èdè gbogbo, kí wón sí jé kí ìmólé Kristi ó tàn láti ara won, kí wón sì sisé fún ìgbàlà okàn àní bí Òun pàápàá tí se fún ìgbàlà àwon okàn, nígbà náà ní “ìhìnrere ìjoba orun” yóò tàn kíákíá ní gbogbo ayé.-Thoughts from the Mount of Blessing, pp. 42, 43.IIO 178.3

    Ára lókùnrin lóbìnrin, èése tí á fi ń fò kiri àwon ìjo? Ẹ kó òwe àgùtàn tí ó sonù, kí a sì jáde lo bí olùsó àgùtàn tòótó, èyí tí ó ń wá òkan tí ó sonù tí ó sì wà nínú aginjù ẹ̀sẹ̀. E gba àwon tó ń sègbé là.-Review and Herald, Dec. 12, 1893.IIO 178.4

    Àwon omo ìjo tí kìí se àlúfà pàápàá le gbé ìgbésè láti kí mú kí isé tí won ò tíì bẹ̀rẹ̀ ó yorí sí rere sùgbón sí àwon ibi tí won ò tí ní àǹfàaní láti máa se isé òòjo wọn. Ẹ jé kí àwon ìdílé tí ó tí fesè múlè nínú òtíto bèrè sí ní wọ àwon agbègbè kòòkan lọ ní eyo kòòkan tàbí méjì-méjì. Wón gbódò ní ìfé àwon okàn, kí wón sì sa ipa won láti mú won wá sínú òtító. Wọ́n le máa pín àwon ìwé ìléwó wa, tàbí máa bá wọn se ìpàdé ní ìlé won kí wọ́n sì tipasè béè mo àwon aládùgbó won kí wón ó sì pè wón wá síbi ìpàdé yìí. Nípasè béè, wón leè jé kí ìmólè won tàn nínú isé rere.- Testimonies, Vol. 8, p. 245.IIO 178.5

    Àwon ará tí ó bá fé kúrò láti ìlú kan sí òmíràn, àwon tí wón ń wo ògo Olórun ní òkèèrè tí wón sí ń wípé ojúse àwon ní láti se rere sí àwon elòmíràn nípa jíjèrè okàn won fún Kristi, ẹni tí Ó fi èmí Rè lélè fún ènìyàn gbogbo ní láti lọ sí ìlú kéréje-kéréje àti àwon ìgbèríko níbi tí ìmólè kékeré wà tàbí tí kò tilè sí ìmólè rárá àti níbi tí wọ́n tilè wúlò láti bùkún àwon elòmíràn pèlú isé àti ìrírí wọn. A fe kí àwon ajíhìnrere ó lọ sí àwon ìlú kéréje-kéréje àti àwon ìletò láti gbé òtító sókè, kí àwon elérì fún Olórun baà lè wà káàkirí ilè àgbáyé, kí ìmólè òtító baà lè tán dé àwon ìbi tí kò tíì dé tọ́lọ̀ rí kí òtító baà lè di gbìgbéga ní ibi tí won kò tíì mọ̀ télè.-Testimonies, Vol. 2, p. 115.IIO 179.1

    Kò sí ohunkóhun tí ó leè ta okàn jí tàbí tí ó fún ìwà ní okun ju kí á sisé fún àwon elòmíràn. Nínú ìwà ìbásepò pèlú ìjo ní á tí rí ọ̀pọ̀ tí wón jéwó ará won gégébí Onígbàgbó sùgbón tí wón jé onímò tí ara eni nìkan. Wón máa ń fé gbádùn ìdàpò pèlú ìjo àti ìtójú láti òdò àlúfà. Wón máa ńdarapò mó ìjo tí ó tí fesè múlè sùgbón tí won kìí fẹ́ bìkítà nípa àwon elòmíràn. Ní síse báyì ní wón ń pàdánù àwon ìbùkún tí ó níye lórí. Ọ̀pọ́ ní á ó sí bùkún fún lópòlópò nígbàtí wón bá fi ibi ìgbádùn won sílẹ̀. Wón ńilò láti lọ sí ibi tí won ó tí lo agbára nínú isé Kristeni àti níbi tí won ó tí lọ láti kọ́ bí a ti ń se ojúse.-The Ministry of Healing, p. 151.IIO 179.2

    Òpòlopò ní àwon ibi tí á lè lọ tó jẹ́ wípé a kó tíì gbé òtító sókè níbi tí á kò tilè tíì gbó òtítò ní ilé Amerika. Bẹ́ẹ̀ si ní òpólopò tí ó yẹ kí ó lo kéde ìhìnrere sùgbon tí ọwọ́ wọ́n dilè nínú èsìn nítorí ìdí eléyì, ìrìn àjò wón sí òrun kò ń yá Kánkán nítorí iyeméjì okàn won tí ó ń bèèrè bóyá Onígbàgbó ní wón tàbí béè kó. Ohun ti wón nílò jùlo ní ìdàpò tó dán mórán pèlú Jesu Kristi. Nígbànà ní á ó so nípa ti won, “E jé alábàsisé papò pèlú Olórun”. Mo fẹ́ so fún ọ̀pọ̀ wípé, È wá enití yóò gbé yín lo sí ibí àjàrà kí ó sí mú yín sisé tàbí kí ó gbé àjàrà tọ̀ yín wá kí ẹ má baà rí ìniran lénu isé. Lásán ní è ń dúró. Tí ẹ bá gbé ojú yín sókè, ẹ ó ríì wípé okó tí pón tí ó sì ń dúró de ìkórè. Ní ònàkonà tí e le gbà wòó, ẹ ó ríi wípé isé wà fún síse yála ní tòsí tàbí ní ònà tó jìn. “Sùgbón eni mélò ní Kristi yóò so fún ní ojó ìdájó wípé “Omo òdò rere àti ótìtó?” Mò ń wòye bí yóò tí rí lára àwon áńgélì àni bí òpin se ńsùn mó àti bí àwon tí ó so wípé àwon ní òyè Olórun àti Jesu Kristi Enití Olórun rán wá jókò tetere sí ojú kan-náà tí wón sì ń lọ sí ilé ìjosìn, tí okàn won kò balè nítorí tí wọn kò rí ìwàásù gidi gbó tí ó le se àǹfaaní fún okàn won tàbí ìjo, nígbàtí ó sì jé wípé wọ́n kàn jókò lásán láì se ohunkóhun. Tí àfojúsùn ètò orò ajé won èyí tí ó wà fún ìgbà díè kò bá se dáadáa tí ó sì wá lọ sí àwọn agbègbè míràn níbi tí a kò tí kéde òtító tàbí tí ìmólè kékeré wà, ǹjé won kò ní máa se irú isé tí Jesu tí se láti gbà wọ́n là?.-General Conference Bulletin, 1893, p. 131.IIO 179.3

    A rí ìdí pàtàkì fún isé ìhìnrere láti gbé òtító lọ sí òdò àwon tó súnmọ́ wá tí kìí se ilè òkèèrè nìkan. A ní àwon ìlú ńlá àti àwon ìlú kéréje ní tòsí wa tí kò tíì sí akitiyan láti gba èmí lá níbè. È é ṣe tí àwon ìdílé tí ó mo òtító ìsisìnyí kò se lọ gbé nínú àwon ìlú wònyí láti leè gbé gbèdéke Jesu sókò, kí wọ́n sì fi ìrèlè sisé ní ònà Olórun láti léè mú ìmólè náà wá sí òdò àwon tí kò mọ̀ nípa rè télẹ̀? IIO 180.1

    Nígbà tí ìjo bá ní ẹ̀mí isé ìránsé yìí, won ó sa gbogbo ipa àti agbára won láti gba àwon okàn tí Kristi kú fún là. Won ó wọ agbègbè tuntun. Àwon tí kìí se àlúfà tí a tí gbọ́wọ́ lé lórí yóò jẹ́ alábàásisé papò pèlú Olórun ní bíbe àwon ìjo wò tí won yóò sì fún àwon ohun tí ó kù tí kò lágbára ní okun. À ó ní àwon òsìsé tí won kìí se àwon àlúfà tí won yóò máa wọ àwon ìlú kéréje àti àwon ìlú ńlá pèlú àwon abúlé gbogbo láti leè jẹ́ kí ìmólè tí Olórun fún won tàn sí òdò àwon elòmíràn?IIO 180.2

    Ní àwon ibi tí won kò tí mo òtító yìí, àwon ará tí wón tí fi ara won jìn lè gba gbògán kí wón kó àwon ènìyàn jo láti fi òtító náà kọ́ won láti inú Bíbélì wá. Tó bá jé wípé àwon ènìyàn díè ló wá, won le kà láti inú “Báyì ni Olúwa wí” láìsí àròyé, ẹ kà fún won láti inú Bíbélì kí e sì sàlàyé òtító ìhìnrere fún won kí ẹ korin kí e sì gbàdúrà pèlú wọn.-Review and Herald, Sept. 29, 1891.IIO 181.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents