Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Fi Ìyọrísí Sí Ọwọ́ Ọlọ́run

    A lè má se àkíyèsí èso rere fún òpòlopò ìgbà, ó lè wá nínú okàn tí ó tutù, ìmo-ara-eni-nìkan, àti okàn tí ó kún fún ohun ayé yìí, sùgbón nígbèhìn Èmí Olórun mí, èémí ìyè sínú okàn náà bí ó ti lè ti wà nínú ayé, èso tí ó pamó yóò dìde, yóò sì so èso fún ìgbélèké orúko Olórun. Nínú ayé e wa, a kò mọ èyí tí yò yorí sí rere - èyí tàbí tòhún. Èyí kìí se ìbèrè fún wa láti yanju. A ní láti se isé ẹ wa, kí a sì fi ìyorísí sówó Olórun. “Ní òwúrò kí a gbin irúgbìn, kí a má dáwó dúró níròlé”. Májèmú Olórun ni wípé, nígbà tí ayé bá wà, ìgbà irúgbìn àti ìkórè kí yóò dáwó dúró. Nínú ìgbékèlé ìlérí yìí, baálé ilé ró ilé, ó sì ń gbìn. Ìgbékèlé wa kò kéré sí èyí bí a ti ń gbìn nínú èmí, tí a ń gba ìlérí I Rè gbó. “Béè ni òrò mi tí ó ti enu mi jáde yóò rí, kò ní padà lófifo sùgbón èyí tí èmi fé ni yóò wá sí ìmúse, yóò si se níbi tí mo bá rán an lo”. “Àwon tí ó ń fi omijé fúrúgbìn yóò fi ayò káa.-“Christ’s Object Lesson, p. 68.IIO 265.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents